Hope Uzodimma jáwé olúborí ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Imo fún sáà kejì

Aworan Hope Uzodimma

Oríṣun àwòrán, Hope Uzodimma/Facebook

Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC ti kéde gómìnà Hope Uzodimma gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Imo.

Nígbà tó ń kéde èsì ìbò náà, gíwà àgbà ilé ẹ̀kọ́ Federal University, Oye Ekiti Ọ̀jọ̀gbọ́n Abayomi Fashina ní Hope Uzodimma ti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ní ìbò 540,308 tí olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party sì rí ìbò 71,503 gbé ipò kejì.

Olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party ló gbé ipò kẹta pẹ̀lú ìbò 64,081.

Uzodimma ló gbégbá orókè ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tó wà ní ìjọba ìpínlẹ̀ náà níbi ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kọkànlá oṣù Kọkànlá ọdún 2023.

Káàdì èsì ìbò

Sáà kejì ni Uzodimma ń wọlé ìbò fún.

Nǹkan bí aago méjì àbọ̀ òru ni kíkéde èsì ìbò náà bẹ̀rẹ̀ ní Owerri tó sì parí ní nǹkan bí aago mẹ́jọ ààbọ̀ òwúrọ̀ yìí.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ òṣèlú méjìdínlógún ló fa àwọn olùdíje kalẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́rin; APC, PDP, LP àti AA ni wọn ń léwájú nínú ìbò náà.

Kò sí olùdíje tó gbégbá orókè ní ìjọba ìbílẹ̀ kankan yàt.ọ̀ sí Hope Uzodimma.

Ní oṣù kìíní ọdún 2020 ni ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà kọ́kọ́ kéde Uzodimma bí ẹni tó jáwé olúborí ìbò tí wọ́n sì yẹ àga mọ́ Emeka Ihedioha tó wà nípò náà nídìí.