Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ afurasí tó ń fi ''wheelchair'' bojú ṣe kátà-kárà egbòogi olóró

Oríṣun àwòrán, NDLEA
Ajọ to n gbogun ti tita ati lilo egbogi oloro lorilẹ-ede Naijiria, NDLEA, ti fi panpẹ ọba mu ọkunrin kan to ni ipenija ara, Godwin Emuneyin, ẹni ọdun marundinlaadọta to n fi kẹkẹ alailera ta egbogi oloro.
Awọn oṣiṣẹ ajọ naa ni ipinlẹ Edo ni wọn mu Godwin nilu Afuze, nijọba ibilẹ ila-oorun Owan, lọjọ Iṣẹgun to kọja lẹyin ọpọlọpọ ifimufinlẹ.
Lakoko ti ọwọ tẹ ẹ, Godwin ni wọn gbamu pẹlu apoti kan ti egbogi oloro “methamphetamine” iwọn mejidinlogun ati igbo ti wọn ti ṣe sinu ọra pelebe mọkanlelaadọrin.
Atẹjade kan lati ọwọ Femi Babafemi to jẹ adari ẹka iroyin ajọ NDLEA wi pe Godwin lo n lo ipenija ẹsẹ rẹ ati kẹkẹ alailera to n lo lati fi tan awọn eeyan jẹ to si n ṣe iṣẹ labẹlẹ.
Ninu igbiyanju ajọ naa lati tubọ gbogun ti itankalẹ egbogi oloro nipinlẹ Edo, wọn ṣe ipalẹmọ baagi igbo mejilelogoji ti iwọn rẹ jẹ ọgọrinlenirinwo kilo ni aba kan ni Aviosi, nijọba ibilẹ iwọ-oorun Owan.
Bakan naa ni wọn ri igbo ti iwọn rẹ to ọkanlelọgbọnlenigba kilo ni Utese, nijọba ibilẹ ila-oorun-ariwa Ovia, lẹyin ti wọn dana sun oko igbo to le ni saare ilẹ mọkanla.










