Ọlọ́run ló pè mí pé kí n jáde dupò Gómìnà Edo - Shaibu

Aworan Philip Shaibu

Oríṣun àwòrán, Facebook/PhilipShaibuEDSG

Igbakeji Gomina Ipinlẹ Edo, Philip Shaibu ti ni erongba oun lati di Gomina ninu eto idibo Gomina lo wa lati ọdọ Ọlọrun.

Shaibu ni oun ti ba Ọlọrun ni gbolohun, to si ti fun oun laṣẹ lati dupo naa.

O sọrọ yii lasiko to n sọrọ lori Channels TV.

"Ohun tí mo n sọ ni pe ko si ẹnikẹni to le da wa duro, araalu Edo ni wa, ti a yoo si ja fun eto wa.

"Fun idi eyi nigba ti mo ni ko si ẹnikẹni to le da mi duro nitori mo ní igbagbọ ninu Ọlọrun, to si jẹ pe oun nikan lo ni agbara pe ki nnkan ma waye.

"Awọn eeyan ko le ni pe ki nnkan ma waye nitori tí Ọlọrun lo fun wa ni igbara, o fun wa nitori idi kan ni

"Ọlọrun kaana to fun eeyan ni agbara naa ni mo lọ ba, to si ni pe ki tẹsiwaju.

"N ko se nnkan pẹlu agbara mi nìkan nigba ti mo mọ pe Ọlọrun wa pẹlu mi."

Shaibu ni oun ati Ọga rẹ Gomina Godwin Obaseke ni ede ayede saaju ko to kede pe oun fẹ jade dupo Gomina.

Saaju ni àwọn ẹṣọ ile ìjọba nipinlẹ Edo tí igbakeji Gomina Philips Shuaibu sita nitori ede aiyede to n waye laarin rẹ ati Gomina Obaseki.