Níbo ni ọ̀rọ̀ ìlera gómìnà Akeredolu dé dúró, kí ni ó ń ṣẹlẹ̀ ní Ondo?

Oríṣun àwòrán, Facebook/Olabode Richard Olatunde
Lati bi ọsẹ mọkanla sẹyin ti Gomina Akeredolu ti pada si Naijiria lati ilẹ Germany to ti lọ gba itọju amọ ti ko yọju sipinlẹ Ondo.
Eyi lo ṣokunfa bi awuyewuye ṣe n tẹsiwaju lori ipo ti ilera gomina naa wa.
Ṣaaju ki o to de ni awọn kan ti n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri pe gomina naa ti gbẹmi mi, tawọn kan naa si n wi pe gomina ọun ko lee gbe apa ati ẹsẹ rẹ mọ.
Ni kete ti gomina Akeredolu dari de ni ọjọ keje oju kẹsan lo kọja silu Ibadan nibi to n gbe ko too di gomina nipinlẹ Ondo ti ko si wa sipinlẹ Ondo lati igba naa.
Nibẹ ni Akeredolu ti kọwe sile aṣofin ipinlẹ Ondo pe oun ti ṣetan lati pada wọṣẹ bii gomina.
Amọ oniruuru ariwo lo gba ipinlẹ Ondo kan lati igba naa wa lori ipo ilera Akeredolu ati boya o ṣi ni okun lati tẹsiwaju bii gomina.
Diẹ lara awọn nkan to ti ṣẹlẹ lati igba ti Akeredolu ti pada si Naijiria ni yii:
Ọjọ kẹjọ oṣu kẹsan: Eyii ni ọjo keji ti gomina Akeredolu pada si Naijiria. Ọjọ naa lo ṣe ipade pọ pẹlu gbogbo igbimo iṣejọba rẹ, awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ondo, atawọn aṣofin ipinlẹ naa nile rẹ n’badan.
Nibi ipade yii ni Akeredolu ti fi iwe ṣọwọ si abẹnugan ile aṣofin ipinlẹ ọhun pe oun ti de lati ibi ti oun ti lọ gba itọju ati pe oun ti ṣetan lati pada wọṣẹ bii gomina lẹsẹkẹsẹ.
Ọjọ kẹsan oṣu kẹsan: Akeredolu buwọ lu abadofin idasilẹ awọn ijọba ibilẹ tuntun nipinlẹ Ondo lati ilu Ibadan.
Ọjọ kejila oṣu kẹsan: Gomina Akeredolu f’ọwọ osi juwe ile fun gbogbo awọn oluranlọwọ igbakeji gomina, Lucky Aiyedatiwa, lori eto iroyin.
Eyi lawọn onwoye juwe gẹgẹ bii apẹrẹ pe nkan ko ṣẹnu re laarin gomina Akeredolu ati igbakeji rẹ, nitori iru igbesẹ yii na lo gbe nigba ti laasigbo oṣelu bẹ silẹ laari Akeredolu ati igbakeji rẹ ni saa akọkọ, Agboola Ajayi.
Ogunjọ oṣu kẹsan: Igbiyanju lati yọ Lucky Aiyedatiwa bii igbakeji gomina bẹrẹ nile aṣofin ipinlẹ Ondo.
Ọjo kọkanlelogun oṣu kẹsan: Aiyedatiwa gba ile-ẹjọ giga ijọba apapọ lọ nilu Abuja pe ki adajọ fofin de ile aṣofin Ondo ati gbogbo awọn ti ọrọ kan lati ma lee yọ oun nipo.
Ọjo karundinlọgbọn oṣu kẹsan: Ile aṣofin fi ẹsun to fẹẹ fa iyọnipo rẹ ranṣẹ si igbakeji gomina, Lucky Aiyedatiwa.
Ọjo kẹrindinlọgbọn oṣu kẹsan: Onidajọ Emeka Nwite ti ile-ẹjọ giga ijọ apapọ nilu Abuja fofin de ile aṣofin ipinlẹ Ondo ati gbogbo awọn tọrọ kan pe wọn ko gbọdọ gbe igbesẹ kankan lori iyọnipo Aiyedatiwa.
Ọjo kejidinlọgbọn oṣu kẹsan: Alaga apapọ ẹgbẹ APC, Abdullahi Ganduje, gbe igbimọ kalẹ lati pẹtu si aawọ laarin Gomina Akeredolu, Aiyedatiwa ati ile aṣofin Ondo.
Ọjọ kẹfa oṣu kẹwa: Ganduje to jẹ alaga apapọ APC ṣe ifilọlẹ igbimọ to gbe kalẹ lati pari aawọ to n waye lẹka ẹgbẹ naa nipinlẹ Ondo.
Ọjo kẹrindinlogun oṣu kẹwa: Awọn ọdọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ondo kede pe awọn fun Akeredolu ni gbemdeke wakati mẹrinlelogun lati ba gbogbo ọmọ ipinlẹ naa sọrọ ati ọjọ mẹta lati pada sipinlẹ naa abi ko kọwe fipo silẹ.
Ọjo kẹtadinlogun oṣu kẹwa: Igbimo ti APC gbe kalẹ labẹ idari gomina ipinlẹ Katsina tẹlẹ ri, Aminu Bello Masari, ṣepade pọ pẹlu awọn ọmọ ile aṣofin Ondo ati awọn adari ẹgbẹ APC nipinlẹ naa niwaju alaga apapọ ẹgbẹ ọhun, Abdullahi Ganduje.
Ọjo kẹtalelogun oṣu kẹwa: Abẹnugan ile aṣofin Ondo kọwe ranṣẹ si adajọ agba ipinlẹ naa lati gbe iggbimọ dide ti yoo ṣewadi ẹsun ti wọn fi kan Aiyedatiwa.
Ọjo kẹrindinlọgbọn oṣu kẹwa: Lucky Aiyedatiwa pe ipade awọn akọroyin si ọfiisi rẹ nibi to ti tọrọ aforiji lọwọ Gomina Akeredolu lori awọn iroyin kobakungbe to n jade lati ipinlẹ naa, to si ni oun ko lọwọ ninu rẹ.
Ọjọ yi kan naa ni awọn ọmọ ile aṣofin mọkanla yọ ara wọn kuro ninu iwe ti abẹnugan ile fi ranṣẹ si adajọ agba ipinlẹ naa lati gbe igbimọ dide ti yoo ṣewadii ẹsun ti wọn fi kan Aiyedatiwa. Awọn mọkanla yii wi pe ko yẹ kile aṣofin naa tun gbe igbesẹ kankan lẹyin tawọn adari ẹgbẹ naa l’Abuja ti pari ija fun wọn.
Ọjo kejilelogun oṣu kọkanla: Adari ẹgbẹ Afẹnifẹre, alagba Reuben Fasoranti, kọwe ranṣẹ si Aarẹ Tinubu lati waa da si ọrọ naa ko too di yanpọnyanrin.
Ọjo karundinlọgbọn oṣu kẹwa: Aarẹ Bola Tinubu ṣepade pọ pẹlu gbogbo awọn tọrọ naa kan nilu Abuja, amọ Gomina Akeredolu ko si nibẹ.
Nibo ni ọrọ de duro?
Lẹyin ipade pẹlu aarẹ nigbagbọ wa pe alaafia yoo pada jọba nipinlẹ naa amọ ekọ ko tii ṣoju mimu ni bi awọn igun kan ṣe n wi pe ki ile aṣofin ipinlẹ naa sọ Aiyedatiwa di adele gomina amọ tawọn igun miran tako igbesẹ yii pe ko si ni ibamu pẹlu ohun ti wọn fẹnu ko si pẹlu aarẹ.
Gẹgẹ bii atẹjade ti agbẹnusọ Aarẹ Tinubu, Ajuri Ngelale, fi lede, afẹnukosi ni bi ipade ti aarẹ ṣe pẹlu awọn tọrọ naa kan ni pe ki Akeredolu tẹsiwaju bii gomina nibi to wa.
O ni ki Aiyedatiwa di ipo igbakeji gomina ti o wa mu ki o si ma si si ogun iyọnipo kankan fun-un mọ.
Bakan naa ni aarẹ wi pe ko gbọdọ si iyipada ninu awọn adari ile aṣofin ipinlẹ naa atawọn to n dari ẹgbẹ APC nibẹ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn araalu kan n pariwo pe awọn fẹ ki ẹnikan wa nipo iṣejọba gẹgẹ bi adari ti wọn lee maa wo, boya ile aṣofin yoo gbe igbesẹ ti yoo sọ aiyedatiwa di adele gomina abi Akeredolu yoo pada sipinlẹ Ondo ni kia ni a ko le sọ.








