Ọ̀pọ̀ olólùfẹ́ Peller já kúrò lójú òpó TikTok rẹ̀, àwọn kan tún ń dúnkokò láti yìnbọn mọ́ torí ọ̀rọ̀ tó sọ

Oríṣun àwòrán, @peller089/Instagram
Gbajúmọ̀ ọ̀dọ́mọkùnrin tó máa ń ṣe fídíò lórí ìkànnì ayélujára TikTok, Habeeb Hamzat tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Peller ní àwọn èèyàn kan ń dúnkokò mọ́ ẹ̀mí òun nítorí ọ̀rọ̀ tí òun sọ nípa #30DaysRantChallenge.
Peller lórí TikTok tó ṣe sọ pé, èèyàn kan dúnkokò mọ́ òun pé wọ́n máa yìnbọn mọ́ òun, tí òun bá fi lè kọjá ní agbègbè Lekki Phase 1.
"Èèyàn kan sọ fún mi pé àwọn máa yìn mí ní ìbọn bí wọ́n ṣe yin Salo níbọn, tí mo bá kọjá ní agbègbè Lekki Phase 1.
"Mo máa ń ti fóònù mi pà tí mo bá ń kọjá ní àdúgbò náà báyìí ni"
Kí ló ṣẹlẹ̀ tí Peller fi ní wọ́n ń dúnkokò mọ́ ẹ̀mí òun?
Lẹ́yìn tí àgùnbánirọ̀ kan gbé fídíò jáde níbi tó ti ń bu ẹnu àtẹ́ lu ààrẹ Bola Tinubu lórí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà, tó sì sọ̀rọ̀ lórí bí ọ̀wọ́ngógó ṣe bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ní orílẹ̀ èdè yìí, ni àwọn ọ̀dọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ẹ̀hónú wọn hàn lórí TikTok.
Ìfẹ́hónúhàn náà tí wọ́n pè ní #30DaysRantChallenge ló ń wáyé lorí ìkànnì TikTok, níbi tí àwọn ọ̀dọ́ tí ń sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí wọ́n ń kojú lórí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.
Àmọ́ ìgbésẹ̀ yìí kò dùn mọ́ Peller nínú bí ó ṣe sọ lásìkò láìfù kan tó ṣe pé káwọn èèyàn yé ṣe ìfẹ̀hónúhàn lórí TikTok mọ́.
Ó ní dípò tí wọ́n fi ń ṣe lórí TikTok, kí wọ́n lọ máa ṣe lórí ìkànnì Instagram tàbí káwọn èèyàn gba ọjà lọ.
Ó sọ pé bí wọ́n ṣe ń lo TikTok fún ìfẹ̀hónúhàn náà le ṣí ojú ìjọba sí ìkànnì ayélujára náà, kí wọ́n sì fòfin de àwọn èèyàn láti yé lo ojú òpó ayélujára náà mọ́.
"Tí wọ́n bá ti TikTok pa, ó máa dùn mí gan ni, ẹ jẹ́ ka ṣe sùúrù, ẹ yé ṣe ìfẹ̀hónúhàn lórí TikTok mọ́.
"Tí ẹ bá mọ̀ pé ó fẹ́ ṣe ìfẹ̀hónúhàn, ẹ lọ sí ọjà, ẹ má jẹ̀ ẹ́ kí wọ́n ti TikTok, ṣe inú yín kò dùn sí bí àwọn èèyàn ṣe ń ní ìtẹ̀síwájú lórí TikTok ni?
"Ẹ jẹ́ ka fi TikTok sílẹ̀, kí a lọ ṣe ìfẹ̀hónúhàn ní ìgboro, ẹni tó bá máa gbé ọkọ́, kọ gbé ọkọ́, ẹni tó bá máa gbé àdá kó gbé àdá, ìfẹ̀hónúhàn orí ayélujára kò ní ipa kankan."
Àwọn ọ̀rọ̀ Peller yìí kò dùn mọ́ àwọn ọ̀dọ́ kan nínú, táwọn èèyàn sì ń bú u pé nítorí owó tó ń rí lórí TikTok ló ṣe ń sọ àwọn nǹkan tó ń sọ náà.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n ní àwọn kò ní tẹ̀lé Peller mọ́ lórí ìkànnì TikTok àti pé gbogbo ẹbùn tó ń rí lórí TikTok, ni kò ṣe mọ nǹkan tó yẹ kó máa sọ.

Oríṣun àwòrán, @peller089/Instagram
"Ẹ ṣì mí gbọ́ ni, ohun tí mo sọ yàtọ̀ sí ìtumọ̀ táwọn èèyàn fún-un"
Ẹ̀wẹ̀, Peller ti wá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn èèyàn pé ìtumọ̀ ọ̀tọ̀ ni àwọn èèyàn ń fún nǹkan tí òun sọ lórí ìfẹ̀hónúhàn náà.
Ó ní òun kò ní kí àwọn èèyàn má ṣe ìfẹ̀hónúhàn àmọ́ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà láti ṣe ni òun ń sọ pé kò dára tó.
Peller ṣàlàyé pé òun tí òun ń gbìyànjú láti sọ ni pé dípò orí TikTok, káwọn èèyàn jẹ́ kí ìfẹ̀hónúhàn náà jẹ́ ojútáyé.
Bákan náà ló ní kò yẹ kí wọ́n máa fi tipátipá mú àwọn èèkàn ìlú tó bá kọ̀ láti kópa nínú ìfẹ̀hónúhàn náà nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé káwọn èèyàn yé tẹ̀lé àwọn gbajúmọ̀ tí kò bá ṣe ìfẹ̀hónúhàn náà.
"Àwọn kan ń sọ pé nítorí àtijẹ tèmi nìkan ni mo ṣe ń sọ pé káwọn èèyàn yé ṣe ìfẹ̀hónúhà lórí TikTok, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń jẹ àǹfàní lórí TikTok yàtẹ̀ sí èmi.
"Ohun tí mò ń sọ ni pé kí gbogbo wa pawọ́pọ̀ láti kojú àwọn adarí Nàìjíríà dípò kíkọjú oro sí èmi."















