Wọ́n gún ẹ̀ṣọ́ Emir Sanusi ní ọ̀bẹ pa, òmíràn fara gbọgbẹ́ lásìkò tó ń bọ̀ níbi ìrun ọdún Ìtúnu Ààwẹ̀

Oríṣun àwòrán, Emir Sanusi Lamido Sanusi
Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kano ti mu ọkunrin kan, ẹni ogun ọdun, ni adugbo Sharifai si ahamọ lori ẹsun pe o pa ọkan lara awọn ẹsọ to w ani aafin Emir tilu Kano.
Gẹgẹ bi ileesẹ akoroyinjọ ilẹ wa, NAN se wi, Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ni Kano, Abdullahi Kiyawa, lo sisọ loju isẹlẹ naa lọjọ Aiku nilu Kano.
Kiyawa ni asiko ti ikọ to kọwọrin pẹlu Emir Sanusi Lamido Sanusi Keji lọ kirun ọdun Itunu Aawẹ lọjọ Aiku ni isẹlẹ naa waye ni deede aago kan ọsan ku ogun isẹju.
"Ọlọpaa ransẹ pe agba ijoye kan nilu Kano, Alhaji Wada Isyaku, ko wa sọ ti ẹnu rẹ lori isẹlẹ ipaniyan naa"
Kiyawa salaye pe afurasi naa pẹlu awọn eeyan miran, ti wọn tin a papa bora lo fi ọbẹ gun ẹsọ Emir naa, ti orukọ rẹ n jẹ Surajo Rabiu.
Rabiu si lo jẹ ara ẹsọ oju ni alakan fi n sọri to wa lati abule Sabon Titi Jaba, to si jade laye nitori ọgbẹ to gba lati ara ọbẹ ti wọn fi gun naa.
"Ọmọ ikọ ẹsọ oju ni alakan fi n sọri miran, Aminu Suleman ti agboole Kofar Mata, naa gba ọgbẹ lorisirisi, to si n gba itọju nile iwosan Muritala Muhammed to wa nilu Kano.
"Ileesẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadi lori isẹlẹ naa, to si ti ransẹ pe agba ijoye kan nilu Kano, Alhaji Wada Isyaku, pe ko wa sọ ti ẹnu rẹ nipa ohun to mọ lori isẹlẹ ipaniyan naa."
Ileesẹ ọlọ̀paa naa wa fidi rẹ mulẹ pe oun ti gbẹsẹle gbogbo ohun to jẹ mọ iwọde durbar lasiko ọdun itunu aawẹ, to si n laago ikilọ fun awọn arufin pe wọn yoo jo palongo labẹ ofin, ti wọn ba fi tako ikilọ naa.
Agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa wa tun sekilọ lori iwa jagidijagan atawọn iwa miran to le dunkooko mọ alaafia ilu, to si n tọ ilẹ la pe oun yoo ko gbogbo awọn eeyan to ba si ofin idaluru si ahamọ, ti wọn yoo si fi imu ko ata ofin.
Bakan naa, ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kano wa parọwa sawọn araalu lati farabalẹ, ki wọn si fọwọ sowọpọ pẹlu awọn alasẹ lati ri daju pe alaafia jọba ni awujọ wa.
















