"Ilé tó lé ní igba ni wọ́n jó ní Erin-Osun, ìgbà kejì tí wọn yóò jó ilé mi rèé, n kò ní aṣọ kankan lọ́rùn mọ́"
Laipẹ yii ni akọtun ija miran tun bẹ laarin ilu Ifon Osun ati Ilobu eyi ti ọwọja rẹ tan de ilu Erin Ile.
Amọ fun iyalẹnu ọpọ eeyan, ilu Erin Osun yii lo faragba julọ ninu laasigbo naa nitori ẹmi ati dukia olowo iyebiye to jona raurau sinu isẹlẹ naa.
BBC Yoruba de ilu naa lati fi oju se mẹrin isẹlẹ naa, ti awọn eeyan to ba wa sọrọ si salaye bi laasigbo naa se waye.
Bakan naa, a ri pe ọpọ ile, mọto atawọn dukia olowo iyebiye miran lo jona patapata ninu isẹlẹ naa, ti ọpọ eeyan si di alainile lori mọ.

"Ọja Ìdírè la wa yii, ọja ọkẹ aimọye owo Naira lo jona mọ ibẹ, kikida asọ to wa lọrun onikaluku wa naa la ni, ko si nkankan miran fun wa mọ"
Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, awọn eeyan to ba BBC sọrọ ni ile to le ni igba ni awọn eeyan ilu Ifon Osun wa jo nilu Erin Osun.
Nureni Adebisi ni loru ọjọ Alamisi si ọjọ Ẹti ni awọn eeyan Ifon n wọ ilu naa wa, ti wọn n yin ibọn laibikita amọ ti awọn eeyan Ilobu tako wọn.
"Ere la tiẹ́ pe, a ro pe bi a se maa n sare le ara wa ni amọ nigba to ya ni wọn n dana sun ile, sọọbu ati ọpọ dukia miran.
Koda, ẹmi awọn eeyan gan bọ sinu isẹlẹ yii, ọja Ìdírè ni a wa yii, ko si nnkan mọ ninu ọja naa, ọja to jẹ ọkẹ aimọye owo Naira lo jona mọ ibẹ.
Kikida asọ to wa lọrun onikaluku wa naa la ni, ko si nkankan miran fun wa mọ."

"Awa eeyan ilu Erin Osun ko ba wọn ja, wọn kan sadede ka wa mọle ni, wọn run ẹmi nilu Erin, wọn si tun ba ọpọ dukia olowo iyebiye jẹ"
Laasigbo yii ko mọ nilu Ilobu nikan, se ni ọwọja rẹ tun tan de ilu Erin Osun to mule ti wọn.
Arabinrin Kosamat Kehinde, to fi omije ba BBC Yoruba sọrọ ni gbogbo awọn nilu naa, asọ kankan soso to ku lọrun awọn, nikan ni dukia ti awọn ni laye.
"Mo n rọ gomina Adeleke ati ijọba ki wọn saanu wa, ki wọn dide iranlọwọ fun wa.
Ilu Ilobu ati Ifon ni wọn n ba ara wọn ja, awa ko ba wọn ja rara, ti a ba mọ pe wọn maa na ọwọ ija sọdọ wa ni, a ko ba ti mura wọn silẹ.
Wọn kan sadede ka wa mọle ni, wọn run ẹmi nilu Erin, wọn si tun ba ọpọ dukia olowo iyebiye jẹ.
Ile ti wọn sun to igba nilu Erin Ile, ibi ti a ti fẹ́ bẹrẹ, ko ye wa bayii."

"Wọn ti sun ile mi ri, wọn tun pada wa sun, ti n ko si le mu ohunkohun jade nibẹ, ẹwu kansoso to wa lọrun mi yii, eeyan kan lo bọ fun mi lati wọ"
Bakan naa, Baba Buhari Alade to jẹ agbalagba naa fi tẹkuntẹkun salaye bo se fori sọta ajalau naa.
"Wọn ti sun ile mi ri, ti n ko si le mu ohunkohun jade nibẹ, ẹwu kansoso to wa lọrun mi yii, eeyan kan lo bọ fun mi lati wọ.
Wọn tun wa pada sun ile mi ni igba keji, awọn eeyan to ran mi lọwọ lati ba mi tun ile mi kọ nigba ti wọn jo nina lakọkọ, ni awọn ko ni da si mi mọ.
Haa, o ti su mi, awọn eeyan Ilobu to ro pe awọn yoo le da Ifon Osun mu, amọ ti wọn ko le da Ifon mu, lo pada wa ba wa.
Awa pẹlu wọn ko ja rara, wọn fi abọ le wa lori ni."

"Gbogbo kanga tawọn ijọba se fun wa, ni wọn ti wo, a ko ribi mu omi mọ, ẹdakun, ẹ saanu wa."
Mama Sulematu Raji naa salaye fun BBC pe wọn ti sọ oun di alainilelori mọ lasiko ija naa.
"Awọn asọ kọọkan ti a mu jade naa lo ku, ko si ọna abayọ mọ, ẹdakun ẹ saanu wa.
Gbogbo kanga tawọn ijọba se fun wa, ni wn ti wo, a ko ribi mu omi mọ o, ẹdakun, ẹ saanu wa."



