Kí ló kàn fún Simon Ekpa lẹ́yìn tí ìjọba Finland fẹ̀sùn ìdìtẹ̀mọ́jọba kàn án?

Simon Ekpa

Oríṣun àwòrán, Simon Ekpa/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba orilẹede Finland ti fẹsun miiran kan olori ẹgbẹ adijagbara fun ominira Biafra, Simon Ekpa lori ẹsun iditẹmọjọba lori ayelujara.

Eyi lo jẹyọ ninu atẹjade ti ijọba Finland fi lede lati kede pe awọn ti fẹsun miiran kan fun Ekpa.

Awọn ẹsun miiran ti wọn tun fi kan afurasi naa ni iwa ọdaran ati kikuna lati san owo ori, to si n lo ọna eburu lati ma san owo ori naa..

Olupẹjọ naa ko ka orukọ afurasi naa sita ṣugbọn akọroyin ileeṣẹ iroyin YLE, lorilẹede Finland ni Simon Ekpa ni ọrọ naa n ba wi.

"Fun ẹsun kan naa, ijọba Finland ni awọn ti pinnu lati ma wọ awọn eeyan yooku lọ si ile ẹjọ nitori iwadii fihan pe wọn ko jẹbi ẹsun naa," atẹjade naa ṣalaye.

O ti pẹ diẹ ti Ekpa ti wa ni ahamọ, to si ni oun ko jẹbi ẹsun ti ijọba fi kan oun.

Simon Ekpa paarọ agbẹjọro rẹ

Ni oṣu kejila ọdun 2024, BBC fi atẹjisẹ ransẹ si agbẹjọro Ekpa to n ba ṣe ẹjọ naa, Ilkka Kopra, lati bere pe ki lo n lọ ni igbẹjọ naa ati pe fun igba melo ni Ekpa ma fi wa ni ahamọ.

Kopra fesi pe "Ile ẹjọ Finland lo fi Ekpa si ahamọ".

O fikun pe gbogbo agbara ni wọn n sa lati gba ominira Ekpa ṣugbọn wọn ko le sọ igba pato ti Ekpa yoo fi wa ni ahamọ.

Iwadii BBC miiran tun fihan pe ijọba Finland ti gbesẹ le gbogbo dukia Ekpa lorilẹede naa.

Asiko yii ni iroyin tẹ wa lọwọ pe Ekpa ti parọ agbẹjọro rẹ nitori eyi to n ṣoju rẹ tẹlẹ ti fẹyinti. O si fa ẹjọ naa le ẹlomiiran lọwọ.

Ki lo kan fun Simon Ekpa bayii?

Ni bayii ti awọn alaṣẹ ti fi ẹsun iditẹmọjọba kan Simon Ekpa, yoo Farahan ni ile ẹjọ pẹlu agbẹjọro tuntun lati wẹ ara rẹ mọ.

Ti ilẹ ẹjọ ba fidi rẹ mulẹ pe o jẹbi, Simon Ekpa ni o ṣeeṣe ko si ẹwọn o kere ju oṣu mẹrin si ọdun mejila gẹgẹ ofin orilẹede naa ṣe gbe kalẹ.

Ki lo sẹlẹ saaju pẹlu Simon Ekpa?

Ni ọdun to kọja ni ọlọpaa orilẹede Finland fi ṣikun ofin mu Simon Ekpa, ẹni to pe ara rẹ ni olori ẹgbẹ agbesunmọmi IPOB.

Iroyin lati orilẹede naa sọ pe ile ẹjọ kan lagbegbe Päijät-Häme ti paṣẹ pe ki wọn lọ fi afurasi naa si ọgba ẹwọn fun akoko diẹ nibi ti yo yi maa gba atẹgun.

Ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin ọhun ni pe o n ru awọn eeyan soke lati wu iwa ọdaran pẹlu erongba igbesunmọmi.

Ile ọjọ naa sọ pe Simon Ekpa n pin ọrọ igbesunmọmi ati iyapa lori ayelujara.

Igba keji ree ti ọwọ agbofinro yoo tẹ Ekpa ni Finland.

Igba akọkọ ti wọn mu ni inu oṣu keji ọdun 2023 amọ wọn fi silẹ lẹyin wakati diẹ.

Ni bayii ti ọwọ ofin tun tẹ ẹ, a ko tii le sọ ibi ti ọrọ naa yoo yọri si.

Ekpa lo n ṣe iwuri fun awọn ọmọ ẹgbẹ IPOD lati maa da ilu ru, bẹẹ naa lo tun n ki wọn laya lati maa kọju ija si awọn agbofinro ni Naijiria.