Mọ̀ nípa Opeyemi Bright, ọmọbìnrin Nàìjíríà tó di olórí ìjọba ìbílẹ̀ ní UK

Ọmọbabinrin Opeyemi Bright, ọmọ Naijiria to di Alaga ibilẹ ni UK

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán, Ọmọbabinrin Opeyemi Bright
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Orilẹede United Kingdom ti yan Ọmọbabinrin Opeyemi Bright, sipo olórí ijọba ibilẹ awọn agbegbe kan niluu naa, eyi ti a mọ si Mayor.

Mayor tuntun naa ni awọn iroyin kan n sọ pe o kere julọ lọjọ ori ninu itan awọn to ti dipo naa mu ri, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29) ni Opeyemi Bright n ṣe.

Ọmọ orilẹede Naijiria ni Opeyemi, bo tilẹ jẹ pe ilẹ Gẹẹsi ni wọn bi i si, eyi to fun un ni anfaani lati tun jẹ ọmọ UK pẹlu.

Ni bayii, oun ni yoo maa dari agbegbe Barking ati Dagenham ni UK.

Ọpọ eeyan to jẹ ọmọ adulawọ ni UK ati lorilẹede yii ni wọn ti n sọ pe aṣeyọri nla ni iyansipo ọdọbinrin ọmọ Yoruba yii.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un ọdun 2025 yii ni Opeyemi di olori agbegbe tuntun ni UK.

Ta a ni Ọmọbabìnrin Opeyemi Bright?

Orilẹede United Kingdom ni wọn bi Ọmọbabinrin Opeyemi Bright si lọdun mọkandinlọgbọn sẹyin.

Baba rẹ, Pasitọ Gbolahan Bright, to gba oye MBE ni UK, jẹ ojiṣẹ Ọlọrun ninu ijọ Ridiimu.

Iya to bi olori ijọba ibilẹ tuntun ni UK yii ni Ọmọwe

Afolasade Bright, toun naa ti jẹ kansilọ ri, to si tun di ipo Mayor agbegbe Hackney mu laaarin ọdun 2006 si 2007.

Irinajo Opeyemi sinu oṣelu UK bẹrẹ nigba to wa lẹni ọdun mejilelogun, wọn yan an sipo kansilọ nigba naa.

Latigba naa lo ti mu riro awọn ọdọ lagbara ni koko, o si n jẹ ki wọn mọ pe o yẹ ki wọn nipa ninu iṣelu agbegbe wọn.

Nigba ti wọn n yan an sipo Mayor tuntun yii, Ọmọbabinrin Opeyemi sọ pe:

"Oore ọfẹ Oluwa ko ju bayii lọ. O wu mi lori lati ṣiṣẹ sin agbegbe mi, bi mo dẹ ṣe jẹ ọmọ Naijiria to ṣee mu yangan, ma a ṣoju ìpín mi pẹlu irẹlẹ ati iṣẹ takuntakun.

"Ki eyi jẹ ohun ti yoo mu awọn ẹlomi-in naa dide lati lewaju, sinlu ki wọn si le ga si i."

Àwọn ọmọ Naijiria tí wọ́n dipò òṣèlú mú lókè òkun

Yatọ si Opeyemi Bright, wọnyi ni awọn ọmọ Naijiria mi-in ti wọn tun wa nipo oṣelu loke okun.

Kemi Badenoch:

Chi Onwurah

Uzoma Asagwara

Esther Agbaje

Iyansipo Bright ti mu kawọn eeyan maa ran ijọba Naijiria leti, pe ohun to yẹ ni lati fi aaye silẹ fun awọn ọdọ ninu oṣelu.

Wọn ni bi wọn ba le maa faaye gba wọn bi eyi nilẹ okeere, ko sohun to ni kawọn ọdọ ma ṣe ju bẹẹ lọ nilẹẹ baba wọn.