'A ṣì ń wá àwọn èèyàn lábẹ́ àwókù ilé tó gbẹ̀mí èèyàn kan, tí àwọn míràn sì farapa'

Aworan Ijamba ile to dawo

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile kan ti wọn n kọ lọwọ ti dawo nipinlẹ Eko, o si ti gba ẹmi eeyan kan, ti eeyan mẹta miiran si farapa yanayana.

Iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Idi Araba ni Mushin ni dede ago mẹta abọ ni Ọjọ Aiku ọjọ kọkandinlogun oṣu karun un ọdun 2025.

Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ to siṣẹ nibi ile naa to padanu ẹmi rẹ lasiko iṣẹlẹ naa.

Ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, NEMA, ẹka ti ipinlẹ Eko lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lati ẹnu agbẹnusọ rẹ, Ibrahim Farinloye.

"Lọwọ ti a n bayin sọrọ, eeyan kan tiku, ti a si ri ẹmi eeyan mẹta mii dola.

"A si n wa awọn eeyan ni abẹ ile ọhun lọwọ," o fikun.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ panapana nipinlẹ Eko, Shakiru Amodu naa fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Margaret Adeseye, ninu atẹjade kan to fi lede, ṣalaye pe ile ọhun ni wọn kọ lọwọ lasiko to dawo.

Adeyeye ni agbalagba mẹta ti wọn jẹ ọkunrin ni wọn yọ labẹ ile to dawo ọhun, ti wọn si ti w ani ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju.

Atẹjade naa ṣalaye, "Ile kan ti wọn n kọ lọwọ ṣadede dawo ni ọna Ishaga, to kọjusi mọsalasi Idi Araba ni agbegbe Mushin nipinlẹ Eko. Ipe pajawiri naa waye ni dede ago mẹta abọ ọsan.

"Gende ọkunrin mẹta ni yọ labẹ ile naa ti wọn farapa yanayana. Wọn ti w ani ile iwosan bayii fun itọju to peye."