Ọmọkùnrin tó fi mílíọ̀nù kan Náírà, owó ọ̀gá rẹ̀, ta tẹ́tẹ́ dèrò ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilé ẹjọ́ Májísíréètì ìpínlẹ̀ Ogun kan tó fi ìlú Ota ṣe ibùjókòó ti ní òṣìṣẹ́ POS kan, Yusuf Olamilekan lọ máa fi aṣọ péńpé roko ọba lọ́gbà ẹ̀wọ̀n fún ọdún kan àbọ̀.
Ẹ̀sùn tó gbé Yusuf Olamilekan dé ọgbà ẹ̀wọ̀n ni pé ó fi mílíọ̀nù kan náírà, tó jẹ́ owó ọ̀gá rẹ̀ ta tẹ́tẹ́.
Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀, Adájọ́ O. O. Fadairo ju Olamilekan sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan àbọ̀ tàbí kó san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún ọgọ́ta náírà.
Adájọ́ tún pàṣẹ pé kí Olamilekan dá mílíọ̀nù kan náírà òwó ọ̀gá rẹ̀, Emeka and Jane Company, padà.
Ó ní agbẹjọ́rò olùpẹjọ́ ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún ilé ẹjọ́ pé Olamilekan jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fì kàn-án bí ó tilẹ̀ ti kọ́kọ́ jiyàn àwọn ẹ̀sùn náà.
Olùpẹjọ́ fún ìjọba, E. O. Adaraloye sọ fún ilé ẹjọ́ pé nǹkan bíi aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Kéje, oṣù Kẹrin ni Olamilekan hùwà ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án náà ní agbègbè Sango-Ota, ìpínlẹ̀ Ogun.
Adaraloye ṣàlàyé fún ilé ẹjọ́ pé Olamilekan gba mílíọ̀nù kan náírà nínú akoto owó iléeṣẹ́ Emeka and Jane Company tó jẹ́ ti ọ̀gá rẹ̀ láti fi ta tẹ́tẹ́.
Ó ní Olamilekan pàdánù owó náà sí oko tẹ́tẹ́ tó fi ta àti pé ìwà tó wù tako abala 383, òfin ìwà ọ̀daràn ìpínlẹ̀ Ogun ọdún 2006, tó sì ní ìjìyà lábẹ́ òfin.















