Ìyàwó ilé dèrò àhámọ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó rọ ọmọ orogún rẹ̀ ní "acid" pa, ìwádìí bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Stringer
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ti fi ọwọ ṣinkun ofin mu obinrin kan labule Malari ni ijọba ibilẹ Soba lori ẹsun pe o fun ọmọ orogun rẹ ni ''acid'' mu ti ọmọ naa si ku.
Iṣẹlẹ ọhun waye lọsẹ to kọja nigba ti iya ọmọ oṣu mẹta naa lọ wẹ ti o si fi ọmọ rẹ silẹ lati maa ṣere nita.
Amọ, lọwọ orogun rẹ ni o ti ba ọmọ naa nigba ti o de lati ile iwẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, DSP Mansir Hassan, ṣalaye fun BBC wi pe ''Maryam Ibrahim to jẹ iya ọmọ oṣu mẹta yii n gbe pọ pẹlu orogun rẹ ninu ile kan naa.
Nigba to de lati ile iwẹ lo ba ọmọ rẹ lọwọ orogun rẹ, Zaliha.
Lẹyin to gba ọmọ rẹ lọwọ Zaliha ni o ri pe ọmọ naa ti n da ida itọ lẹnu ti ayipada si ba ara rẹ lojiji.
Bayii ni wọn gbe ọmọ naa digba digba lọ ile iwosan, ṣugbọn ọmọ oṣu mẹta ọhun ti ku ki wọn to de ile iwosan.''
Ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe lọgan lawọn agbofinro lọ mu Zaliha lẹyin ti wọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa.
Lẹyin naa ni ileeṣẹ ọlọpaa kede lẹyin iwadii wọn pe 'acid' ni obinrin ọhun fun ọmo orogun rẹ mu lati ṣeku pa a tori owu.
''Aburo ọkọ Zaliha lo ra ''acid'' to rọ ọmọ oṣu mẹta orogun rẹ naa pa'' - Ọlọpaa
DSP Hassan ni iwadii ọlọpaa fi han pe aburo ọkọ wọn, Lawal Muhammad, lo ba Zaliha ra ''acid'' lẹyin to sọ fun un wi pe oun ko fẹ maa ri ọmọde naa mọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ti bẹrẹ lori Muhammad to ra ''acid'' fun Zaliha naa.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo fọwọ ṣinkun ofin mu ọkunrin naa kiakia lati wa sọ tẹnu rẹ bakan naa.
DSP Hassan fikun ọrọ rẹ pe ede-ai-yede ti wa laarin Zaliha ati orogun rẹ ṣaaju iṣẹlẹ naa, ṣugbọn wọn ti yanju ọrọ naa tẹlẹ.
''Ọrọ naa ti lọọlẹ tan, amọ, nnkan ti a ko mọ ni bo ya Zaliha ṣa fẹ sẹku pa ọmọ orogun rẹ ni.
Zaliha ti n ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lori iwadii ti a n ṣe, obinrin naa yoo foju ba ile ẹjọ ti a ba ti pari iwadii lori iṣẹlẹ naa.
Zaliha yoo lọ sọ tẹnu rẹ nile ẹjọ, ileẹjọ yoo si ṣe idajọ to yẹ fun un.
Bakan naa, a o ṣawari aburo ọkọ Zaliha to ra ''acid'' to fi pa ọmọ ikoko naa fun un.
Awọn agbofinro ti fọn sita, wọn si ti bẹrẹ si ni wa ọkunrin naa pẹlu,'' agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye.















