Akẹ́kọ̀ọ́jáde méjì di èèrò ẹ̀wọ̀n nítorí ìjínigbé nípìnlẹ̀ Ekiti

Ọwọ́ èèyàn tí ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wà níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Láti bíi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni ìwà ìjínigbé ti di ohun tó gbilẹ̀ ní Nàìjíríà
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ilé-ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Ekiti tó wà ní Ado-Ekiti ti sọ akẹ́kọ̀ọ́jáde méjì sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀dógún fún ẹ̀sùn jíjí akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga fásitì Federal University Oye Ekiti, FUOYE, gbé.

Ojo Babajide, ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n àti Olajide Nathaniel, ẹni ọdún márùndínlógójì ni ilé-ẹjọ́ ní wọ́n jẹ̀bi ẹ̀sùn ìjínigbé.

Ní ọdún 2022, lásìkò tí àwọn méjéèjì ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ilé-ẹ̀kọ́ gíga ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Ilé-ẹjọ́ jù ẹni kọ̀ọ̀kan wọ́n sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá fẹún ẹ̀sùn ìjínigbé àti ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún fẹún ẹ̀sùn lílẹ̀dí àpòpọ̀ láti hu ìwà ọ̀daràn.

Ẹ̀sùn tí wọ́n kà sí wọn lọ́rùn sọ pé ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù Kẹta, ọdún 2022 ni àwọn méjéèjì gbìmọ̀ pọ̀ láti jí ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atana Emmanuel gbé.

Wọ́n ní ẹ̀sùn náà tako abala 279 àti 280 ìwé òfin ìwà ọ̀daràn ìpínlẹ̀ Ekiti ti ọdún 2021.

Báwo lọ́rọ̀ ṣe jẹ́?

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó kọ lọ́dọ̀ ọlọ́pàá, Atana Emmanuel, ẹni tó akẹ́kọ̀ọ́ FUOYE tẹ́lẹ̀, tó sì ń ṣiṣẹ́ gẹrungẹrun sọ pé nǹkan bíi aago méje ìrọ̀lẹ́ ni àwọn olùjẹ́jọ́ náà wá bá òun ní ṣọ́ọ̀bù òun.

Ó ní wọ́n sọ pé kí òun wọ inú ọkọ̀ kan tí wọ́n gbéwá, "mo kọ́kọ́ ṣe agídí àmọ́ wọ́n fipá mú mi láti ṣe ohun tí wọ́n ń fẹ́.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Wọ́n kọ́kọ́ gbé mi lọ sí ibìkan tí mi ò mọ́ ní Oye-Ekiti ṣùgbọ́n mo padà bá ara mi ní ilé ìtura kan tó wà lọ́nà Ikere-Ekiti.

"Wọ́n fipá mú mi láti san owó yàrá tí wọ́n gbà ní ilé ìtura náà."

"Lẹ́yìn náà ni wọ́n pe àwọn èèyàn mi láti bèèrè fún mílíọ̀nù kan náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìtúsílẹ̀ àmọ́ N101,000 ni a rí kó jọ.

Ó ní nígbà tí wọ́n ri pé òun kò ní owó láti fún wọn, wọ́n bọ́ gbogbo aṣọ òun , tí wọ́n sì na òun bíi ejò àìjẹ pẹ̀lú kòbókò.

"Mo ṣèṣe gidi ní gbogbo ara kó tó di pé wọ́n tú mi sílẹ̀."

Olùpẹjọ́ fún ìjọba, Kunle-Shina Adeyemo pe ẹlẹ́rìí kan sílé ẹjọ́, tó sì kó àwọn ẹ̀rí kalẹ̀.

Bákan náà ni agbẹjọ́rò àwọn olùjẹ́jọ́, Akinola Abon rọ ilé-ẹjọ́ láti ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú àánú nítorí àwọn oníbàárà òun ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ilé-ẹ̀kọ́ nígbà náà ni, tí wọ́n sì ń gbáradì láti lọ sin ilẹ̀ baba wọn.

Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ kalẹ̀, Adájọ́ Adeniyi Familoni sọ pé àwọn olùjẹ́jọ́ náà jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Adájọ́ ní ìwà ìjínigbé ti fẹ́ di tọ́rọ̀ fọ́nká sílé ní àwùjọ pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú láti fòpin si, tó sì pọn dandan láti fi àwọn olùjẹ́jọ́ náà jófin láti kọ́ àwọn mìíràn lọ́gbọ́n.

Ó ní kí wọ́n lọ máa fi aṣọ péńpé roko ọba fún ọdún mẹ́ẹ̀dógún láì sí àǹfàní fún sísan owó ìtanràn.

Ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Karùn-ún, ọdún 2025 ni ẹ̀wọ̀n náà bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ ṣe sọ.

Ọ̀dọ́bìnrin kan parọ́ pé wọ́n jí òun gbé lásìkò tó wà pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ l'Ekiti

Obinrin kan ti wọn de ni ọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Laipẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti mu ọmọbinrin kan to parọ pe wọn ji oun gbe

Laipẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti fi ṣikun ofin mu ọdọbinrin kan, Helen Kayode, ẹni ọdun mẹrinlelogun.

Ẹsun ti ọlọpaa fi kan Helen ni pe o pa irọ pe awọn agbebọn kan ji oun gbe, ti wọn si gbe oun lọ sinu ile kan loju ọna Iworoko/Ado-Ekiti, niluu Ado Ekiti.

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

O ni ọmọbinrin naa pada jẹwọ pe oun gbe igbesẹ naa ki oun le duro siluu Ado-Ekiti lati sajọyọ ayẹyẹ ọjọ ibi oun pẹlu ọrẹkunrin rẹ.

O ni ọrẹkunrin oun naa ti ṣeleri lati fun oun ni ẹbun nla, eyi to tako ifẹ inu awọn obi rẹ to n fẹ ko de siluu Eko lọjọ karun un, oṣu Karun un.