Ó lé ní 52,000 ọmọ Naijiria tó ṣípò padà lọ sí UK ní 2024- Ìwádìí

Aworan paapa ofurufu Uk

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O le ni ẹgbẹrun mejilelaadọta ọmọ orilẹede Naijiria to japa lọ si ilu United Kingdom ni ọdun 2024, gẹgẹ bii esi iwadii ti wọn ṣẹṣẹ gbe sita ṣe ṣafihan rẹ l'Ọjọbọ, eyi to fi orilẹede Naijiria si aarin awọn orilẹede tí àwọn eeyan rẹ n lọ si ilẹ Gẹẹsi.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo wa lati wa kawe tabi wa siṣẹ . Ni apapọ, ẹgbẹrun mẹtadinlọgbọn ọmọ Naijiria wa fun iṣẹ, ẹgbẹrun mejilelogun wa fun iwe kika, ti ẹgbẹrun mẹta yooku wa fun awọn nnkan miiran.

Nigeria darapọ mọ orilẹede bii India, Pakistan, ati China gẹgẹ bi ọkan ninu awọn orilẹede ti ki ṣe Yuroopu to n wa si ilẹ UK.

"Ni ipari oṣu kejila ọdun 2024, India lo n lewaju ninu awọn orilẹede ti eeyan rẹ pọ julọ lara awọn to n ja pa lọ si ilẹ UK.

"Iṣẹ ati iwe kika ni o jẹ idi gboogi ti ọpọ eeyan fi n wa ilẹ UK lati orilẹede India, Pakistani ati orilẹede Naijiria.

Iwadii ni ida mẹtalelọgọta awọn arin irinajo wa si ilẹ UK ni wọn wa ni ọjọ ori iṣẹ (16–64 ), ti ida mejilaadọta wọn si jẹ ọkunrin, ti mejidinlaadọta wọn si jẹ obinrin.

Awọn ọmọde jẹ mẹrindinlogun awọn arin irinajo, ti ida kan si jẹ ti awọn agbagba ti wọn ti le ọgọta ọdun ni ọjọ ori.

Ọpọ awọn arin irinajo to de si ilẹ UK lasiko itankalẹ Corona tabi lẹyin itankalẹ ni wọn ti pada si orileede wọn, paapa awọn to wa kawe.

Awọn arin irinajo to wa kawe ni ida wọn jasilẹ lẹyin igbesẹ ijọba Ilẹ UK.

Ki lo ṣẹlẹ tẹlẹ?

Bẹẹ ba gbagbe, oṣẹ to kọja ni Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Keir Starmer, gbe awọn igbesẹ tuntun lati jẹ ko le koko fun awọn ọmọ ilẹ okeere lati kawe, ṣiṣẹ tabi gbe lorilẹede naa.

Lara awọn igbesẹ naa ni bi wọn ṣe sọ ọ di dandan lati ṣe idanwo ti yoo fi han pe awọn eeyan naa gbọ, wọn si le sọ ede Gẹẹsi.

Olootu ijọba naa tun ni, ijọba fẹ mu adinku ba iye awọn oṣiṣẹ olutọju alaisan, ti wọn n gba lati ilẹ okeere ati iye ọdun ti eeyan gbọdọ gbe nilẹ ọhun ko to di ọmọ oniluu.

Amọ ko mẹnuba awọn to n wọ ilẹ naa lọna ti ko ba ofin mu, bii awọn to n gba ori omi wọle.

Gẹgẹ bii atẹjade ijọba ilẹ ọhun, 728,000 ọmọ ilẹ okeere lo wọ orilẹede United Kingdom nigba ti yoo fi di inu oṣu Kẹfa ọdun 2024.