Nnamdi Kanu tún fojú balé ẹjọ́ lónìí, ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajijagbara fun ominira ilẹ Biafra, Nnamdi Kanu tun ti foju bale ẹjọ lonii.
Lasiko igbẹjọ naa ni agbẹjọro rẹ fi fidio kan han adajọ nibi ti ajagunfẹyinti, T.Y Danjuma ati ọga agba ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, DSS ti n sọ fun awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn daabo bo ara lọwọ awọn agbesunmọmi.
Fidio ti agbẹjọro naa, Paul Erokoroa, SAN, fi han nile ẹjọ ṣafihan ipade kan to farajọ ipade awọn akẹkọọ nibi ti Danjuma ti sọ ọrọ naa.
Ki lo wa ninu awọn fidio ti agbẹjọro Nnamdi Kanu fihan?
Danjuma ni "awọn ọmọ ogun n ṣegbe lẹyin awọn kan, wọn n padi apo pọ pẹlu awọn janduku ati agbesunmọmi lati gbẹmi eeyan.
"Awọn lo n fun awọn agbesunmọmi ni iroyin, awọn naa lo n daabo bo wọn, ti ẹ ba n duro ki awọn ọmọ ogun ba yin dojukọ awọn agbesunmọmi, ikọọkan ni ẹ maa ku tan."
Fidio keji ṣafihan ibi ti ọga agba DSS, Adeola Ajayi ti ṣalaye nipa abule Azare, nipinlẹ Borno.
O ni Boko Haram kọlu abule naa amọ awọn eeyan abule ọhun kọju ija si Boko Haram ti wọn si gbẹmi gbogbo awọn ọmọ ogun Boko Haram ọhun.
Ajayi sọ ninu fidio naa pe lati ọjọ naa Boko Haram ko yọ abule ọhun lẹnu mọ.
Ọga DSS naa sọ ninu fidio ọhun pe "Ẹ ko le maa ro pe gbogbo ibi ni awọn ologun ati ọlọpaa yoo wa ni gbogbo igba lati daabo bo yin, awọn araalu ni lati dide lati daabo bo ra wọn, asiko si niyii lati ṣe bẹẹ."
Fidio ti agbẹjọro Kanu fi lede kẹyin nile ẹjọ ni ibi ti gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodima ti n sọ pe awọn oloṣelu lo wa nidi iṣekupani to n waye lagbegbe Orlu.
Lẹyin eyii, agbẹjọro Kanu tun mu abọ iwadii igbimọ to ṣewadii iṣẹkupani iloro Lekki lasiko iwọde EndSARS niluu Eko lọdun 2020 jade.
O ni abajade iwadii naa fi han pe awọn agbofinro lo ṣekupa araalu, kii ṣe awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB.
Adajọ ni ki igun mejeeji fẹnuko lori bi ẹjọ́ naa yoo ṣe tete pari
Wayi o, adajọ to n gbọ ẹjọ naa ti sọ pe oun yoo ri daju pe igbẹjọ ọhun ya kankan ṣaaju isinmi awọn adajọ ti yoo waye ninu oṣu Keje ọdun yii.
O ni ki ikọ mejeeji mu ọjọ mẹfa laarin ọṣe meji to n bọ lati ke si awọn ẹlẹri wọn ki wọn le pa oju ẹjọ wọn de.
Ikọ agbẹjọro Kanu mu ọjọ kejidinlọgbọn ati ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu yii ati ọjọ kẹfa, ọjọ kẹrindinlogun, ọjọ kejidinlogun ati ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹfa fun itẹsiwaju ẹjọ naa.












