Ta ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe àtìpó nílẹ̀ òkèrè àti pé ta ló lágbára láti pinnu ẹni tó lè ṣe àtìpó?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọsẹ to kọja ni awọn ọmọ orilẹeede South Africa mọkandinlọgọta ti wọn jẹ alawọ funfun balẹ si papakọ ofurufu Dullies lẹba Washogton DC lẹyin ti wọn agba anfani lati ṣatipo nilẹ naa.
Aarẹ Donald Trump sọ pe awọn alawọ funfun ti iran wọn jẹ ẹya Europe n kọju iṣoro ẹlẹyamẹya ati iṣekupani ni South Africa.
Aarẹ South Africa, Cyril Ramaphosa ni ko si ootọ kankan ninu iroyin naa ati pe ko si ẹri kankan lati gbe iroyin naa nidii.
Awọn eeyan naa ti ọkunrin, obinrin atawọn ọmọde wa ninu wọn mu asia orilẹede Amẹrika lọwọ ti awọn alaṣẹ ilẹ Amẹrika si ki wọn kaabọ.
Ọpọ araalu lo n sọ pe iggbesẹ naa tako bi Aarẹ Trump ṣe n le awọn ajoji kuro nilẹ rẹ.
Ninu oṣu Kinni ọdun yii, Aarẹ Trump buwọlu aṣẹ kan lati dẹwọ gbigba awon aṣatipo wọle lati ilẹ okere silẹ naa.
Lẹyin asẹ yii, nnkan bii aṣatipo ti iye wọn to ẹgbẹrun lọna ọgọrun un ni ko mọ eyii to kan fun wọn mọ.
Igbesẹ Trump lati fun awọn eeyan yii ni atipo l'Amẹrika bi awọn eeyan ninu ni South Africa.
Ni South Africa, awọn alawọ funfun to jẹ ida 7% awọn ọmọ orilẹede naa lo ni idaji oko to wa nibẹ.
Aarẹ Ramaphosa juwe bi awọn eeyan naa ṣe lọ si Amẹrika gẹgẹ bii iwa ojo.
O ni "Ti ẹ ba wo awọn eeyan orilẹede wa, awọn alawọ dudu, awọn alawọ funfun, wọ ti duro silẹ yii nitori pe orilẹede wa niyii, a ko gbọdọ salọ silẹ mii, a gbọdọ duro sibi ki a le tun ile wa ṣe."
Nigba ti BBC bere lọwọ igbakeji akọwe ijọba Amẹrika, John Landau, idi ti wọn fi gba awọn alawọ funfun South Africa wọle dipo awọn ọmọ ilẹ Afghanistan ti ogun n le, o ni lara awọn amuyẹ ti awọn n wo ni bi awọn eeyan to fẹ ṣatipo yoo ṣe tete le gba aṣa ilẹ awọn.
Eyii ti n mu ki ọpọ eeyan sọ pe oṣelu wa ninu bi wọn ṣe n gba awọn aṣatipo wọle.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ta ni aṣatipo?
Nibi ipade awọn aṣatipo to waye lọdun 1951 ni wọn ti juwe aṣatipo gẹgẹ bii ẹni to sa kuro nilẹ rẹ latari inunibini nitori ẹya, ẹsin, ibi to ti wa, ẹgbẹ to darapọ mọ tabi igbabọ rẹ nipa oṣelu.
Apejuwe yii lo kọkọ wa fun awọn aṣatipo lati Europe lẹyin agbaye keji amọ wọn ṣatunṣe itumọ naa lọdun 1967 lati faye gba gbogbo eeyan to ba wa ni ipo naa lagbaye.
Yatọ si itumọ ẹni to le ṣatipo yii, wọn tun kede awọn ẹtọ awọn aṣatipo labẹ ofin ninu ipade naa.
Iye awọn aṣatipo
Ninu oṣu Kẹfa ọdun 2024, 43.7 miliọnu aṣatipo lo wa kaakiri agbaye gẹgẹ bi atẹjade ajọ UNHCR.
Ida 65% awọn aṣatipo labẹ ajọ naa lo wa lati Syria, Venezuela, Ukraine ati Afghanistan.
Ida 71% awọn aṣatipo lo n gbe lorilẹede ti ko fi bẹẹ ri jajẹ. Orilẹede Iran, Turkey, Colombia, Germany ati Uganda ni orilẹede marun un akọkọ to n gba awọn atipo julọ.
Iye awọn aṣatipo
Labẹ Aarẹ Biden, 125,000 aṣatipo lo n wọ Amẹrika lọdun. Lọdun to kẹyin ijọba rẹ, o le ni aṣatipo 100,000 to wọle, eyii to jẹ iye to ga julọ laarin ọgbọn ọdun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki ni iyatọ laarin aṣatipo, ẹni to sa asala lọ ilu miran ati arinriajo lati ilẹ okeere?
Aṣatipo ni ẹni to sa kuro lorilẹede rẹ nitori ogun, rogbodiyan tabi inunibini.
Irufẹ ẹni bẹẹ lẹtọọ si abo labẹ ofin ti wọn ba ti fontẹ lu atipo rẹ.
Ẹni to n fẹ abo ilẹ mii ni ẹni to fi ilẹ rẹ silẹ nitori ogun, rogbodiyan tabi inunibinu amọ ti wọn ko tii buwọlu ẹni naa gẹgẹ bi aṣatipo.
Ajọ IOM sọ pe ko si itumọ kan gboogi fun atipo amọ wọn le juwe rẹ gẹgẹ bi ẹni to kuro lorilẹede rẹ lọ omiran fun igba diẹ tabi titi lai.
Ki lawọn ohun to le mu ki wọn gba eeyan gẹgẹ bii aṣatipo?
Ofin agbaye nikan lo le sọ nipa irufẹ ẹni ti wọn le pe ni aṣatipo amọ awọn orilẹede funra wọn le juwe ẹni ti wọn n gba wọle bii aṣatipo.
Tendai Achiume to jẹ onimọ nipa ofin sọ pe awọn orilẹede maa n ṣe ojuṣaju nipa ọrọ awọn atipo.
O ni awọn orilẹede kan yan lati lati maa gba awọn ọmọ orilẹede ti wọn ni ibaṣepọ pẹlu, eyii lo jẹ ki awọn alawọ funfun kan maa ni anfani si atipọ nigba ti wọn ko ni gba awọn alawọ dudu wọle.
O ni "Ukraine jẹ apẹrẹ ti a ba n sọrọ nipa eyii.
"A n ri aworan nipa awọn eeyan to n sakuro nilẹ naa ati aworan awọn to n sa kuro nibẹ amọ ti wọn kii ṣe alawọ funfun."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O fi kun pe awọn orilẹede ni idi ti wọn fi n gba awọn aṣatipo.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, "Awọn orillẹede mii maa n gba awọn eeyan lati orilẹede ti awọn funra da ti wahala silẹ nibẹ.
"Ṣugbọn ofin agbaye koro oju si idẹyẹsi nipa ẹya, ẹsin, orilẹede tabi ibi ti eeyan ti wa" ki wọn to le gba a ni aṣatipo.












