Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ ibi tí ìwádìí dé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọmọ tí àṣìta ìbọn pa n'Ibadan, ìdí tí wọ́n fi ń wá bàbá rẹ̀

Aworan ọmọ ti aṣita ibọn pa n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, Odunaye Alade

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ ọmọdekunrin ti aṣita ibọn pa laarin ọsẹ yii ni agbegbe Gbagi-Alakia ni ijoba ibile Egbeda niluu Ibadan.

Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Oyo, CP Johnson Adenola, fidi ọrọ yii mulẹ lasiko ipade ti ileeṣẹ ọlọpaa ṣe pẹlu awọn aṣoju ijọba ipinlẹ naa niluu Ibadan.

Awon aṣoju ijọba naa ti kọmisọna fun eto iroyin nipinlẹ Oyo, Omoba Dotun Oyelade ko sodi lotun, alaga ẹka to ri si igokegodo ọkọ nipinlẹ Oyo (ORTMA), Ogagun feyinti Adekoya Adesagba ati komisona Ọlọpa Ipinlẹ Oyo ni wọn bawọn akọroyin sọrọ nibi ipade ọhun to waye ninu gbangan olu ileeṣe ọlọpaa to wa ni agbegbe Eleyele n''Ibadan.

Kọmiṣọna ọlọpaa ninu ọrọ rẹ ṣalaye wi pe awọn ko tii le ti fi iroyin to peye lede lori iku to pa Kehinde Alade nitori baba ọmọ naa Odunayo Alade ko tii wa sọ tẹnu rẹ lori iṣẹlẹ naa.

Adenola tesiwaju si wi pe oṣiṣẹ ile iṣe ọlọpa to sekupa Kehinde Alade ti wa ni ahamo ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ CID to wa ni agbegbe Iyaganku niluu Ibadan.

O ni ni kete ti ajo ọlọpaa ba ti gba ọrọ lẹnu baba ọmọ tan lawọn yoo kaadi iwadii lori iṣẹlẹ naa nilẹ, tawọn yoo si fidi otitọ mulẹ lori ọrọ naa.

Ẹwẹ, Ọga agba ajọ ọlọpaa ni Naijiria ti paṣẹ fun komisona Ọlọpaa ipinlẹ Oyo lati ṣe o iwaadi kikun lori iṣẹlẹ naa.

Bo tile jẹ wi pe ẹniti o kowo rin pẹlu baba oloogbe naa ati ọlọpaa to yinbo ti sọ tẹnu wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Oyo sọ pe lai si eri lati ẹnu Ọgbẹni Alade, iwaadi naa ko tii le pari.

Komisona fun eto iroyin nipinlẹ Oyo, Ọmọba Oyelade ṣalaye ni tire wi pe, ijọba Ipinlẹ Oyo yoo ri wi pe gbogbo awọn to jẹbi ninu iṣẹlẹ naa ni yoo foju wina ofin.

O ni ijọba Ipinlẹ Oyo n ro awọn ọga ile iṣe ọlọpaa lati maa kọ awọn oṣiṣẹ wọn lekọọ ilana iṣẹ ọlọpaa loorekoore ki opin leba irufẹ iṣẹlẹ yii.

Bakan naa, alaga OYRTMA, Ọgagun feyinti Adesagba bu ẹnu atẹ lu bi awọn awako ṣe n tapa si ofin ati ilana ọkọ wiwa loju popo ati awọn ikọlu sawọn oṣiṣẹ ajọ ORTMA ni gbogbo igba.

O tesiwaju wi pe igba mejo ọtọtọ ni wọn ti ṣe ikọlu si awọn oṣiṣẹ ajọ ORTMA ninu ọdun yii ti awọn miran si farapa yanayana ninu awọn ikolu yii.

Alaga OYRTMA ni lose to koja ni baba oloogbe yii rufin oju popo, ti o si san faini.

O ni bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ yii ko dun mo ajọ ORTMA ninu, o rọ awọn olugbe Ipinlẹ Oyo papaa julọ awọn awakọ lati maa tẹle ilana ojupopo ki opin lee deba irufẹ iṣẹlẹ yii.

Oṣù Kọkànla ni Kehinde kò bá pe ọmọ ọdun mẹrinla, o sọ fun mi lọsẹ to kọja pe iṣẹ agbẹjọro loun yoo ṣe boun ba dagba

Ninu alaye baba to padanu ọkan ninu awọn ibeji rẹ yii, o ni oṣu Kọkanla ọdun yii ni Kehinde to ku ko ba pe ọmọ ọdun mẹrinla.

Ọgbẹni Alade tẹsiwaju pe ọsẹ to kọja yii ni ọmọ naa n sọ foun pe iṣẹ agbẹjọro loun yoo ṣe boun ba dagba.

O ni o bani lọkan jẹ gidi pe ọṣe to tẹle e ni iku da ẹmi rẹ legbodo latọwọ awọn agbofinro to n da ọkọ oun duro.

O fi kun un pe awọn agbofinro naa yoo fi tiwọn da oun duro boun ba da wọn lohun, ọmọ to si fẹẹ lọọ ṣedanwo laaarọ ọjọ naa yoo pẹ loun ko ṣe duro.

Ṣugbọn nigbẹyin naa, oun padanu Kehinde, ẹgbọn rẹ ko si tun ri idanwo ṣe.

''Ọdun keje ree ti mo ti n da awọn ọmọ yẹn tọ, iya wọn ti da wọn silẹ fun mi''

Aworan Odunayo Alade

Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Baba Kehinde ṣalaye fun BBC pe iya to bi awọn ọmọ naa fun oun ti da wọn silẹ lati ọdun keje sẹyin.

Odunayo sọ pe latigba ti awọn ọmọ naa ṣi kere bẹẹ ni iya wọn ti lọ.

Lilọ rẹ ko ni koun fẹ iyawo miran gẹgẹ bo ṣe wi.

''Ohun ti mo maa n sọ ni pe ko si ọmọ ti obinrin kankan fẹẹ bi fun mi mọ ti yoo to awọn ti mo ti bi yii.

''Mo ni mi o le fẹyawo mi-in bayii, mo fẹẹ maa tọju awọn ọmọ mi ki obinrin mi-in ma baa fiya jẹ wọn.

''Ti mo ba fẹ ọja ọla rere fun wọn, iyawo kọ lo kan lọrọ mi.

''Lati ọdun keje ti iya wọn ti lọ, emi ni mo n tọju wọn funra mi. Mi o fẹyawo mi-in.''

Ki ni yoo waa ṣẹlẹ bayii ti ọkan ti ku lara awọn ọmọ naa, ati pe ki lohun to n fẹ lori iṣẹlẹ iku Kehinde.

Odunayo fesi pe iwadii ti yoo tanna si bawọn agbofinro ṣe yinbọn to si pa Kehinde loun fẹ.

O ni bi wọn ba ridii ọrọ naa, yoo gbegidina iru rẹ fun ẹlomi-in.

''Temi lo de ti a ri yii, a o mọ ti ẹni to n bọ lọla.

''Ti mo ba sọ pe mo fẹẹ gba ohunkohun, ko da ọmọ to ku pada. Ṣugbọn ki wọn ṣe iwadii to le dena iru eyi lọla, fun idajọ ododo''

Bẹẹ ni baba ọmọ to di oloogbe naa wi.

Tẹ o ba gbagbe, owurọ ọjọ Iṣẹgun, ogunjọ oṣu Karun-un ọdun 2025 yii ni iṣẹlẹ to gba ẹmi Kehinde Alade, waye niluu Ibadan.

Lasiko ti baba rẹ kọ lati duro fun awọn oṣiṣẹ OYRTMA to n ri si igbokegbodo ọkọ ni ọrọ bẹyin yọ.

Ọlọpaa kan yinbọn si taya ọkọ naa, eyi to gba ẹyin wọnu ọkọ to si pa Kehinde Alade lojuu Taye rẹ, ẹgbọn wọn agba ati baba wọn to n wa ọkọ ayọkẹlẹ to n gbe wọn lọ sileewe naa.