Ìwé tó fa àríyànjiyàn nínú Islam lórí ìyapa tó wà láàrin ẹ̀sìn mùsùlùmí àti òṣèlú

Oríṣun àwòrán, Dar Al Tanweer Publishing
Ṣẹ ki orilẹede wa labẹ ijọba awarawa tabi ki o wa labẹ idari ẹsin tabi ki mejeeji wa papọ?
Eyi ni ibeere to ti n fa ọpọ ariyanjiyan laarin awọn ọjọgbọn, amoye ati awọn to nifẹ si oṣelu nilẹ Araabu, pẹlu bi iṣejọba mejeeji ṣe fẹgbẹ kẹgbẹ.
Ni oṣu Kẹrin ni Sheikh Al-Azhari Ali Abd al-Razek kọ iwe kan ni Egypt, to pe orukọ rẹ ni "Ẹsin Islam ati oriṣun ijọba" eyi to da lori sise igbelarugẹ ero nipa ijọba, to si jiyan pe idasilẹ ẹṣin Islam ko ni ṣe ipẹlu idasilẹ ijọba,
Iwe yii da ọpọ ariyanjiyan silẹ laarin awọn amoye niluu Egypt ati kaakiri agbaye, to fi debi pe wọn yọ onkọwe naa kuro ni ile ẹkọ giga fasiti Al-Azhar to wa, ti ọpọ si bẹrẹ sii maa sọ pe Ali Abdel Razek gan an kọ ni ojulowo onkọwe naa.
Ta ni Ali Abdel Razek? Ki ni awọn ọrọ to yanana? Ki lo ro to fi gbe iwe naa sita?
Iwe ọhun jade ni ọdun1925, ọdun kan lẹyin ti ijọba orilẹede Turkey kọ lati tẹwọgba eto ijọba Caliphate, to so ẹsin ati oṣelu papọ.
Lasiko yii, ọpọ ilu Islam ni wọn n koju ikonilẹru lọwọ awọn orilẹede Yuroopu lẹyin ọpọ ọdun, ti wọn si di ijọba Ottoman Empire.
Ki lo wa ninu iwe naa?
Ninu iwe yii, Abdel Razak bẹrẹ pẹlu alaye pe iwadii rẹ ninu ofin Islam lo sun un debi kikọ iwe naa.
"Ohun to wa ninu iwe yii ni pe Anọbi Muhammad (PBUH) jẹ ojisẹ, to tọ wa ni ilana ẹsin, ti awọn itọsọna rẹ ko si ni ṣe pẹlu oye Oba jijẹ tabi iṣẹjọba."
Abdel Razek tun ni ko si iwe ẹṣin kankan to le fidi eyi mulẹ pe ẹsin ni ajọsepọ pẹlu iṣejọba.
O fikun ọrọ rẹ pe bi awọn orilẹede Islam ṣe pin nigba ti iṣejọba pẹlu ẹsin wo lulẹ ko mu kawọn eeyan padanu lọkan wọn.
Ẹṣun ti wọn fi kan onkọwe naa
Ẹsun ti wọn fi kan onkọwe naa ni pe ko duro ni ori iwe iroyin lasan ṣugbọn o de fasiti Al-Azhar.
Awọn alaṣẹ fasiti naa ṣe ipade ninu oṣu Keje ọdun 1925, ti wọn si fẹsun meje kan Abdel Razek.
Ali Abdel Razek farahan niwaju igbimọ ninu oṣu Kẹjọ nibẹ ni wọn ti fẹnu ko lati yọ ọ kuro ninu ẹgbẹ awọn alfa nla, Jam'iar, ti wọn si tun fi ofin de e pe ko gbọdọ gba ipo ẹṣin kankan.
Bakan naa ni wọn tun yọ ọ kuro ninu adajọ ile ẹjọ Sharia.
Lẹyin ọpọ ọdun ti Ali Abdel Razek wa ni aye ara rẹ, Al-Azhar gbe igbesẹ lati da a pada sipo rẹ lasiko saa ẹgbọn rẹ Mustafa Abdel Razek, ẹni to jẹ olori Jam'iar.
Wọn fun ni ipo minisita fun Awqaf ninu ijọba ọdun 1940.
Gbogbo igbiyanju lati da ijọba ẹsin pẹlu oṣelu papọ lo ja si pabo.
Iṣẹlẹ to waye ni ọdun 1937 lasiko igbaradi fun ifinijoye Oba Farouk, Ọmọ Oba Fouad, ni idi adajọ fun ayipada ọhun.















