Bí ìyàwó mi ṣe gbẹ̀rímijẹ́, àti ẹ̀ru ogun ìfàyàkàya ni kìí jẹ́ ki n yan àlè - Ijebu, òṣèré tíátà

Àkọlé fídíò, Bí ìyàwó mi ṣe gbẹ̀rímijẹ́, àti ẹ̀ru ogun ìfàyàkàya ni kìí jẹ́ ki n yan àlè 0- Ijebu, òṣèré tíátà
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja oṣere tiata, Tayo Amokade, ti ọpọ eeyan mọ si Ijebu sọrọ lori iṣẹ tiata ati idile rẹ lapapọ ninu ifọrọwanilẹnuwo ti o ṣe pẹlu BBC Yoruba.

Ijebu ni ''kafinta ni baba mi, obi ni iya mi n ta lọja Awolowo niluu Eko.

Inu yara kan lawa eeyan bii mẹjọ n gbe.

Mo jẹ ọmọ to ya ipata gan an ni kekere, ile sinima ni wọn ti maa wa n mu mi.

Ṣugbọn baba pe mi jokoo wi pe ki n lọ si ile ẹkọ na, lẹyin naa mo le ṣe nnkan to ba wu mi.''

Ijebu ni Yoruba lawọn obi oun maa n ba oun sọ lati kekere, bo tilẹ jẹ pe oun gbọ ede Ijebu ṣugbọn o nira foun lati sọ.

Amokade ni awọn ọmọ ilu oun le maa sọ pe ''ṣe Ijebu lo n sọ yẹn ni, amọ, ti Ọlọrun ba ni Oun de n kọ?''

Ijebu ni oun ni ẹni akọkọ to kọkọ gba Jesu sinu aye rẹ ninu ẹbi, koda o ni afadura jagun loun

Ọgbẹni Amokade ni iyawo oun gba ẹri oun jẹ gan an, ati pe ko sẹni to le sọ pe oun da ẹnu ifẹ kọ oun ninu awọn akẹgbẹ oun kankan to jẹ oṣerebinrin ri lagbo tiata.

Ifayaluya maa n bami lẹru gan an - Ijebu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

''Ifayaluya maa n bami lẹru gan an, iyẹn lo maa n jẹ ki n pinnu lati lọ ba iyawo mi ni ile lati ṣe ibalopọ ju obinrin mii ti mi o mọ lọ.''

Ijebu tun ṣalaye idi ti oun ko fi saba jade ninu ere tiata mọ, ''kii ṣe pe mi o ṣere tiata mọ, ipe ni mo gbọ.''

Nigba ti mo n bọ lati Amẹrika ni mo gbọ ohun kan to sọ fun mi pe ki n bẹrẹ ileeṣẹ to n ta ilẹ ati ile.

Bayii ni mo bẹrẹ pẹlu ẹgbẹrun mẹjọ dọla ti mo ni lọwọ nigba naa.

Mama mi nifẹ mi gan an, nigba kugba ti mo ba ti de ni wọn maa n di mọ mi.

Iyẹn lo jẹ ki ọpọ eeyan maa n sọ fun mi pe mo fẹran iyan mi pupọ.

Koda, emi ati iya mi maa n ṣe ẹfẹ papọ lori TikTok lasiko kan.

Amọ, nigba to ya ni iya mi loun o ṣe TikTok mọ wi pe gbogbo eeyan lo n ri awọn nibẹ.

Lẹyin naa ni mo ṣalaye fun wọn pe ọjọ kan n bọ ti n ko ni le ṣe fidio TikTok pẹlu wọn mọ.

Bayii ni mama mi wọle ti wọn si lọ wọ aṣọ ti a fi jọ ṣe fidio TikTok mii, eyi ti ọpọ eeyan pin kaakiri ori ayelujara.

Iku o dọjọ, arun ko doṣu, ko pẹ si asiko yii ni mama mi jẹ Ọlọrun ni pe,'' Ijebu lo sọ bẹẹ.