Nítorí àti dènà àìsàn ibà, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń fẹ́ máa lo ògùn ibà fún ẹ̀fọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, James Gallagher and Philippa Roxby
- Role, Health and science correspondent
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
O yẹ ki awọn ẹfọn naa maa lo oogun iba lati pa oro kokoro iba lara wọn, ki wọn ma baa maa jẹ ki aisan iba tan kalẹ mọ. Awọn oluwadii lati ilẹ America ni wọn sọ eyi.
Abo ẹfọn lo maa n fa aisan iba nigba ti wọn ba mu ẹjẹ eeyan, o si kere tan, eeyan ẹgbẹrun mẹfa (600,000) ni wọn n pa ninu ọdun kan, paapaa julọ awọn ọmọde.
Igbiyanju tawọn eeyan maa n ṣe lati pa ẹfọn ko ju ki wọn maa fi oogun apẹfọn fin wọn lọ, dipo ki wọn wa ọna ti oro iba to wa lara ẹfọn funra rẹ yoo fi kuro.
Ṣugbọn ikọ oluwadii kan lati Yunifasiti Harvard, ti ṣawari oogun meji kan to le mu oro iba kuro lara ẹfọn patapata. Wọn ni eyi ṣee ṣe bi wọn ba gba ibi ẹsẹ wọn ti oogun naa bọ ẹfọn lara.
Sisun si abẹ apo apẹfọn jẹ ọna kan lara awọn ọna ọlọdun pipẹ ti awọn eeyan maa n lo lati fi ṣẹgun ẹfọn, paapaa bo ṣe jẹ pe alẹ ni ẹfọn maa n ja ju.
Awọn abẹrẹ ajẹsara to n dena arun iba fun awọn ọmọde tun jẹ ilana mi-in lati gbogun ti ẹfọn, paapaa julọ, lawọn agbegbe ti ẹfọn pọ si.
Ni ti apo apẹfọn, bo ṣe jẹ ohun ti a le foju ri naa lo tun jẹ pe wọn ti fi oogun apakokoro si i lara.
Ṣugbọn awọn ẹfọn ti yari ni ọpọ orilẹede bayii, ti oogun apẹfọn ki i pa wọn mọ bo ṣe maa n pa wọn tẹlẹ.
"A ko ti i gbiyanju lati pa oro to wa lara ẹfọn bayii ri, nitori awọn ẹfọn funra wọn la kan n pa." Dokita Alexandra Probst, lati Yunifasiti Harvard lo sọ bẹẹ.
O ni ṣugbọn ilana pipa ẹfọn naa ko ṣiṣẹ mọ.
Ọnà àbáyọ ti wa
Ninu iṣẹ awọn oluwadii naa, wọn ṣe atupalẹ ohun to n jẹ ẹfọn gangan (DNA), wọn si wa awọn ọna ti agbara rẹ fi le dinku lasiko to ba n pọ oro.
Wọn wa ọpọ oogun ti yoo koju kokoro iba, wọn si pada ge e ku si mejilelogun (22). Awọn wọnyi ni wọn danwo lara awọn abo ẹfọn, nigba ti wọn fun wọn ni majele iba jẹ.
Ninu iwe wọn, awọn onimọ sayẹnsi yii ṣe apejuwe oogun meji kan to le pa oro iba ni ida ọgọrun-un.
Wọn dan awọn oogun naa wo lara awọn ohun to da bii apo apẹfọn.
"Koda bi ẹfọn yẹn ba yè nigba to ba wọnu apo apẹfọn, awọn oro to wa ninu rẹ yoo ti ku, ko si ni i le pọ aisan iba si eeyan lara." Dokita Probst lo ṣalaye bẹẹ.
"Mo ro pe ilana yii moriya gan-an, nitori ọna tuntun lati dojukọ awọn ẹfọn funra wọn ni."
O ni yoo ṣoro ki oogun yii to ma pa ẹfọn mọ, nitori o to biliọnu rẹ to wa lara awọn eeyan ti wọn ba fọwọ ba, ṣugbọn ko to marun-un lara ẹfọn to ba jẹni.
Iṣẹ oogun yii yoo wa lara apo fun ọdun kan, eyi yoo si jẹ ko rọrun lati ra, yoo si tun ni alopẹ ju awọn oogun apẹfọn atijọ lọ. Awọn oluwadii naa lo sọ bẹẹ.
Wọn fi kun un pe ayẹwo ti fi ilana tuntun yii mulẹ. Wọn ni ipele keji yoo waye ni Ethiopia lati mọ boya apo apẹfọn to n gbogun ti iba yii yoo wulo kari aye.
Bi wọn ṣe wi, yoo to ọdun mẹfa, o kere ju lati pari gbogbo iwadii yii, ti wọn yoo si fi mọ boya yoo ṣiṣẹ kari aye.
Ṣugbọn afojusun wọn ni lati ni apo apẹfọn ti wọn ti fi oogun si, to si tun ni aporo iba ninu, to bẹẹ to jẹ ti ọkan ko ba ṣiṣẹ, ilana keji yoo jẹ bi idan ni.














