Èèyàn méjì farapa lásìkò tí bààlúù ẹ̀kọ́ṣẹ́ balẹ̀ lójijì n'Ilorin

Oríṣun àwòrán, Others
Eeyan meji farapa yanayana lasiko ti idanilẹkọọ nipa bi baalu ṣe n balẹ ni paapa ofurufu waye niluu Ilorin.
Iṣẹlẹ naa waye ni Ọjọbọ, ọjọ Kejilelogun oṣu Karun un ọdun 2025.
Agbẹnusọ ajọ NSIB, Arabinrin Bimbo Oladeji, lo kede eyi ninu atẹjade to fi lede fun awọn akọroyin; o ni iṣẹlẹ ọhun waye ni agogo marun un kọja iṣẹju mejidinlọgbọn ni paapakọ ofurufu niluu Ilorin.
Oladeji ni baalu naa ṣadede balẹ lojiji, to si ya kuro loju ọna, to si m'ori wọ inu koriko, nibi ti awọn eeyan meji to wa ninu baluu ọhun ti farapa
O ni : "Awọn mejeeji farapa yanayana, ti a si suure gbe wọn lọ si ile iwosan fun itọju lẹsẹkẹsẹ.
"Ikọ NSIB Go-Team ti n gbaradi bayii lati lọ lati Abuja si Ilorin lati le ṣe iwadii, ba awọn eeyan sọrọ lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa."
Ọga agba fun NSIB, Alex Badeh Jr, ti wa ba awọn mọlẹbi awọn to farapa kẹdun, to si paṣẹ pe ki itọju wọn bẹrẹ ni kiakia.
"Ohun to wa lọkan wa bayii ni ohun pato to ṣokunfa iṣẹlẹ yii. Gbogbo iwadii wa lo da lori aabo araalu lasiko irinajo."
Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ kejila oṣu yii ni Ijamba ọkọ ofurufu ṣẹlẹ ti baalu Air Peace tawọn ero wa ninu rẹ kọlu ẹranko igbẹ nla kan ni papakọ ofurufu ilu Asaba nipinlẹ Delta.
Ijamba yii waye lasiko ti baalu naa n sare lori ilẹ nigba to fẹ gbera lọ soke.
Ṣadeedee ni ẹran ẹtu naa jana mọ baalu ọhun lẹnu ti baalu naa si ṣeku pa a.
Baalu yii ko le rin mọ lẹyin to kọlu ẹranko igbẹ naa tan lopopona rẹ ni papakọ ofurufu ilu Asaba.
Iṣẹlẹ yii ni ko si jẹ ki baalu naa le rin gbogbo irinajo to yẹ ko rin mọ, to si tun ṣakoba fawọn baalu mii to fẹ gbera lopopona ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ni papakọ ofurufu Asaba.















