Èyí làwọn iṣẹ́ àkànṣe táwọn aṣòfin àpapọ̀ gbẹ̀yìn gbé wọ inú ètò ìṣúná 2025 ní Nàìjíríà

Ààrẹ Ile ìgbimọ Aṣofin Naijiria, Godswill Akpabio atawọn aṣofin kan

Oríṣun àwòrán, Nigeria Senate/facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Latigba ti ẹgbẹ oluwadii kan to n ri si eto iṣuna Naijiria ati tawọn ilu Africa mi-in ti a mọ 'BudgIT', ti loun ri i pe awọn aṣofin kan n fi kun eto iṣuna 2025 ni awuyewuye ti n jẹyọ.

Iwadii BudgIT ṣalaye pe awọn aṣofin Naijiria kan fi agbaṣe iṣẹ ti ko ni anfaani kankan ninu sinu eto iṣuna 2025.

BudgIT tẹsiwaju pe oun ti ri agbaṣe iṣẹ11,122, ti owo rẹ yoo yoo ju N6.93 trillion ninu eto iṣuna ọdun 2025 yii.

O ni eyi wa ninu eto iṣuna ti ile igbimọ aṣofin ti buwọlu naa lai wo ipa to le ni lori ọrọ aje.

Ẹgbẹ oluwadii yii sọ pe awọn afikun naa ni wọn ki bọ iṣuna awọn ileeṣẹ ijọba ti ko tiẹ ni nnkan lati ṣe pẹlu iṣẹ ti ileeṣẹ naa n ṣe.

Eyi ni BBC fi ṣe atupalẹ mẹsan-an ninu awọn iṣẹ naa ati iye ti wọn dọgbọn fi kun un.

Kókó mẹ́sàn-án

Iná ojú pópó: Iwadii BudgIT sọ pe owo ti iye rẹ jẹ N393.29 billion ni wọn dọgbọn ki bọ owo eto iṣuna fun eyi.

Wọn ni wọn yoo fi pese ina oju popo ti iye rẹ jẹ1,477 lawọn agbegbe ile igbimọ aṣoju ati aṣofin kaakiri Naijiria.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀: Owo to to N505.79 billion ni wọn ni wọn yoo nilo lati fi pese eto ibaraẹnisọrọ fun awọn eeyan ile igbimọ aṣofin kaakiri Naijiria . 2,122 si ni oju opo ti wọn ni eyi yoo mu wa.

Atunṣe awọn gbọngan ilu: Gbọngan ilu mẹtalelogoji (43) ni wọn ni yoo gba N17.23 billion lati tunṣe lawọn agbegbe ẹkun ile igbimọ.

Kíkọ yara ikawe, pipese iwe kika ati dida awọn tiṣa lẹkọ̀ọ́: Bi iwadii BudgIT ṣe fi han, awọn aṣofin naa sọ pe 179.96 billion naira ni yoo nilo lati fi kọ yara ikawe, pese iwe kika ki wọn si tun ṣeto idanilẹkọọ fun awọn olukọ.

Ètò tí kò kan ìlera: 319 ni awọn eto ti ko kan ilera ti wọn ni wọn kọ mọ iṣuna 2025. N420.09 billion si ni yoo pari rẹ bi wọn ṣe sọ.

Mimu igbe-aye irọrun ba awọn ọba alaye: BudgIT ṣalaye pe awọn aṣofin ko gbagbe awọn oriade o.

O ni 6.74 billion naira ni wọn ni awọn yoo fi mu igbe-aye irọrun ati igbadun ba awọn ọba.

Ṣíṣe ọ̀nà tuntun àti àtúnṣe àwọn ti tẹ́lẹ̀

Oju ọna to to 380 ni wọn ni wọn yoo ṣe ni tuntun, N1.44 trillion ni eyi yoo si gba lawọn agbegbe tawọn aṣofin n ṣoju.

Ríra ọkọ̀ ààbò fún àwọn agbófinró: BudgIT jábọ̀ pe awọn aṣofin ti ya 11.7 billion naira fun rira mọto ti wọn yoo maa lo fun aabo f'awọn agbofinro.

Kanga gbigbẹ: Kanga 538 ti iye rẹ yoo wọ N114.53 billion ni wọn yoo tun pese lawọn agbegbe tawọn aṣofin n ṣoju bi iroyin ṣe ro o.

Ìmọ̀ràn BudgIT

BudgIT ninu ọrọ rẹ, sọ pe awọn aṣoju ijọba ki i bọ sọwọ ofin bi wọn ba lu owo ilu ni ponpo ni Naijiria.

O ni eyi si n fa iṣoro fun ilana iṣẹ ọba.

"Awọn ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ bii EFCC ati ICPC gbọdọ fi kun jijafafa wọn.

"Wọn gbọdọ gbogun ti ajebanu, ki wọn si fi oju awọn to ba lufin han ni kootu.

Àwíjàre Ilé ìgbìmọ̀

Alaga to n ri si ikede nile igbimọ aṣofin, Sẹnetọ Yemi Adaramodu, ti sọ pe ọrọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni ẹgbẹ oluwadii naa gbe jade.

Adaramodu, sọ fun ẹka iroyin Daily Trust, pe wọn buwọ lu eto iṣuna 2025 lẹyin ayẹwo finni-finni.

"Awọn aṣofin yẹ eto iṣuna 2025 yii wo finni-finni ki wọn too buwọ lu u. Iye to si wa ninu ohun ti ẹka agba to gbe e wa fi ṣọwọ si wa naa ni"

Adaramodu lo sọ bẹẹ.

O fi kun un pe awọn ọlọtẹ kan ninu oṣelu lo wa nidii ọrọ naa.

"Amọran wa fun awọn tawọn oloṣelu n lo lati gbe iru nnkan bayii jade ni pe ki wọn dẹkun ẹ.

" Ki wọn maa gbe ọrọ gidi yẹwo, yatọ si awọn agbelẹrọ ọrọ oṣelu bi eyi.''

Adaramodu lo sọ bẹẹ.