Kí ló ń fa gbas-gbos láàrín ìjọba Kano àtàwọn òṣèré tíátà?

Fiimu Hausa

Oríṣun àwòrán, FB/Multiple

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Kano ti n gbe igbesẹ lati fofin de fiimu kan ti wọn ṣe nipinlẹ naa latari pe o lodi si ofin.

Igbesẹ ọhun ti bi ọpọ araalu ninu, ti wọn si n bu ẹnu atẹ lu ijọba ipinlẹ ọhun.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti fakinfa yoo waye laarin ajọ to n bojuto fiimu ni Kano ati ẹgbẹ oṣere ti wọn n pe ni Kannywood.

Yatọ si pe o n gbẹsẹle fiimu, ajọ ọhun tun ti fi sikun ofin mu awọn oṣere atawọn olorin kan ri bii Aminu Ala, Naziru Ahmed, Sanusi Oscar 442, Sadiq Zazzab, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Igba marun un ọtọtọ ree ti fakinfa ti waye laarin ijọba Kano atawọn oṣere tiata.

Gbigbe ẹsẹ le sinima 'Bakar Ashana'

Bo tilẹ jẹ pe wọn ti gbe ajọ to n bojuto fiimu kalẹ ṣaaju sinima naa amọ irawọ ajọ naa tunbọ tan si lẹyin ti wọn gbẹsẹle fiimu ọhun.

Ọdun 2004 ni ileesẹ Bright Star Entertainment gbe fiimu na jade nipa bi awọn obinrin ti ko ni ọkọ ṣe n ṣowo.

Iroyin ni ẹni to kọ fiimu naa lọ fi han ajọ Nigerian Film Censorship Board, NFVCB, fun ontẹ amọ ko fi to ajọ to n ṣakoso fiimu ni Kano leti lo jẹ ki wọn gbẹsẹle.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, wọn fi ọlọpaa mu ọkunrin to kọ fiimu naa, wọn gba owo itanran lọwọ rẹ, wọn si ko awo fiimu naa kuro lori igba.

Fiimu Hausa

Oríṣun àwòrán, carmenmccain.com

Ijọba Mallam Shekarau

Iṣẹlẹ mii to tun milẹ ni Kano ni bi wọn ṣe fi fidio ihoho oṣerebinrin Maryam Hiyana ati ọkunrin kan, Usman Bobo lede.

Ọpọ gbagbọ pe iṣẹlẹ naa lo mu ki gomina Malam Ibrahim Shekarau kede olori ọlọpaa Hisbah, Abubakar Rabo gẹgẹ bii alaga ajọ to n bojuto fiimu.

Lara awọn ofin tuntun ti Rabo gbe kalẹ ni pe ajọ naa gbọdọ ri itan fiimu naa ki wọn si buwọlu u ki wọn to ya fiimu naa.

Shekarau

Oríṣun àwòrán, FB/Ibrahim Shekarau

Awọn oṣere ati olorin to ṣẹwọn

Lara awọn ti wọn fi ṣikun ofin gbe lasiko Rabo ni Hamisu Iyantama, dam A. Zango ati Rabilu Musa Ibro to ti di oloogbe lọdun 2007.

Ibro kọ orin kan lẹyin naa to pe ni 'Shankarau' eyii to fi sọko ọrọ si ijọba.

Bẹẹ naa ni Zango kọ orin tirẹ lati bu ijọba lẹyin to ti ẹwọn de.

Gbigbe ẹsẹ le awọn fiimu ori YouTube

Lọdun 2022, lasiko ijọba Ismaila Na'Abba Afakallah, o fofin de gbigbe fiimu ti ajọ to n bojuto fiimu ko tii wo sori YouTube.

Igbesẹ naa waye lasiko ti awọn to n ṣe fiimu Hausan bẹrẹ si n fi sinima wọn sori YouTube.

Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC, Afakallah ni oun gbe igbesẹ naa latari pe awọn fiimu kan ti wọn n gbe jade tako aṣa ati ẹsin ilẹ Hausa.

Lara awọn fiimu ti wọn gbẹsẹle ni awọn ti wọn ya nibomii amọ ti wọn yoo ta ni Kano.

Gbigbe ẹsẹ le fiimu mejilelogun

Agbẹnusọ ajọ to n bojuto fiimu Abdullahi Sani Sulaiman, sọ ninu atẹjade kan lọjọ Aiku pe awọn gbeṣele fiimu mejilelogun latari pe awọn to ṣe fiimu ọhun ko kọkọ gba ontẹ ajọ ọhun.

Amọ ṣa, wọn ti fun awọn to ni awọn fiimu naa ni ọsẹ kan pere lati tete fi orukọ wọn silẹ lọjọ ajọ naa.