Adeola, ọmọ Jumoke George ní iṣẹ́ àṣẹ́wó ni wọ́n mú òun lọ ṣe ní Mali láìmọ̀, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí, kí Ọlọ́run tó kó o yọ

Aworan

Oríṣun àwòrán, Biola Adebayo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Adeola, ọmọ gbajugbaja oṣere tiata, Jumoke George , ti ṣalaye ohun to gbe lọ si orilẹede Mali ati ohun ti oju rẹ ri lọwọ ẹnikan to ṣapejuwe gẹgẹ bii ẹni to se ni aanu.

Adeola ni obinrin kan, to pe ni Blessing, ti oun ti gba sinu ile ri, ni o ta oun silẹ Mali, lati lọ maa lọ ṣe iṣẹ asẹwo.

O ni oun yari mọ obinrin ti wọn mu oun lọ ba ni Mali lọwọ, to oun si fi tipatipa mu silẹ lorilẹede Mali.

Adeola sisọ loju isẹlẹ naa ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu Biola Adebayo, Adeola ni wọn tan oun lọ si irinajo lọ si orilẹede Mali lori adehun pe oun yoo ri iṣẹ ṣe.

Ṣugbọn ohun to fọkan si kọ lo ba pade nigba to de si Mali, to si ri pe n se ni wọn ta fun obinrin kan, to ni ko ma sanwo pada pẹlu biba awọn ọkunrin lopọ.

"Mo ba awọn to obinrin to wa nibẹ, to n sisẹ asẹwo sọrọ, wọn ni o to ogun ọkunrin ti ikọọkan wọn n ba lopọ lojumọ"

Adeola ni gbogbo erongba oun ni pe oun yoo ma gbe pẹlu obinrin naa, ti oun yoo si ma ba sisẹ gẹgẹ bii Blessing to mu wa ṣe sọ.

"Otitọ jade nigba ti obinrin naa sọ fun mi pe mo jẹ oun ni owo toto 1,5m CFA francs lati san pada.

Owo naa si to milliọnu mẹta Naira, ọrọ naa ko kọkọ ye mi, ti ẹru si n ba mi.

Obinrin naa sọ pe ti oun ba mọ pe mo ti dagba ni, oun ko ni igba lati jẹ ki maa gbe mi bọ rara."

Pato iṣẹ ti Adeola lọ ṣe ni orilẹede Mali, ni pe ko ma ba awọn ọkunrin lopọ, ko si ma fi owo to ba pa san owo to jẹ pada.

O salaye pe oun ba awọn to wa nibẹ, to n sisẹ asẹwo sọrọ, ti oun si ri pe o to ogun ọkunrin ti ikọọkan obinrin n ba lopọ lojumọ.

"Obinrin ti wọn mu mi wa fun, ni oun ti san N250,000 fun Blessing lori mi, mo si gbọdọ sn milliọnu mẹta Naira pada"

Adeola ni ọrọ naa binu oun ninu pupọ, ti oun si jẹ ko di mimọ pe oun ko le ṣe isẹ asẹwo rara.

"Mo sọ fun obinrin naa pe o san ki n ku, ju pe ki n maa ba awọn ọkunrin lopọ tabi siṣẹ aṣẹwo.

Se ni ilẹ Mali n gbona gidi, to si maa n mooru, ibi ti wọn ni ki n sun gan da bi ile ọti, ti n ko si le sun mọju nibẹ.

Mo tun pada ni ọjọ keji lati lọ pẹtu si obinrin ti wọn mu mi wa fun, to si ni oun ti san N250,000 fun Blessing lori oun.

Ibi ti mo ti n ronu ni mo ti ri ọkunrin kan to gbọ Yoruba, to si ni ki n maa lọ si igberiko lati sisẹ ọmọ ọdọ olounjẹ.

O ran mi lọwọ lati sa lọ kuro lọdọ obinrin naa, mo wa lọdọ obinrin kan to n ta ounjẹ amọ owo to n fun mi kere pupọ."

"Mo setan lati ran awọn ọmọ Naijiria to n jiya ni igberiko lọwọ, ti wọn n sisẹ asẹwo, ki wọn le e pada si igboro lati sisẹ gidi."

Blessing ni oun ko le jẹun tori ounjẹ wọn ko ba oun lara mu, ti oun si sa lati abule naa wa silu Bamako, tii se olu ilu orilẹede Mali.

"Abule ti mo ti n sisẹ olounjẹ ni eeyan kan tun ti gba mi nimọran lati maa lọ si ilu nla tabi igboro.

O sọ fun mi pe ọpọ isẹ ti wọn yoo ti sanwo gidi wa nigboro, ti mo si gba ibẹ lọ.

Nilu Bamako ni mo ti ri ọpọ ọmọ Naijiria, awọn Yoruba ati Igbo si pọ nibẹ pupọ.

Wọn ni ẹgbẹ ti wọn ti n ran ara wọn lọwọ, ti wọn si n sisẹ gidi.

Mo setan lati ran awọn ọmọ Naijiria to n jiya ni igberiko lọwọ, ti wọn n sisẹ asẹwo, ki wọn le e pada si igboro lati sisẹ gidi."

Ki lo ti sẹlẹ saaju nipa Adeola, ọmọ Jumoke George?

Bẹẹ ba gbagbe, ajọ to n mojuto igbaye-gbadun awọn ọmọ Naijiria to wa nilẹ okeere, The Nigerians in Diaspora Commission (NiDCOM) lo mu Adeola, ọmọ osẹrebinrin, Jumoke George, wa sile lati orilẹede Mali.

Ọsan ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun un, ni Ọga Agba ajọ NiDCOM, Arabinrin Abike Dabiri, fi ikede sita loju opo X rẹ pe, oṣerebinrin, Biola Adebayo ati akẹgbẹ rẹ Adeniyi Johnson, ti tẹwọ gba arabinrin ọhun.

Ọsẹ meji sẹyin ni agba oṣere naa ke gbajare sita pe lati bi ọdun mẹrin ni akọbi ọmọ oun, Adeola, ẹni ọdun mọkanlelogoji, ti dawati.