Prince Philip: Ó lo ọdún 93, lọ sí orílẹ̀-èdè 143, ó ní gbajúgbajà ìyàwò kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Duke ilu Edinburgh, ọkọ to gbajumọ julọ ni agbaye, ti ku ni ẹni ọdun mọkandinlọgọrun
Aadọrin ọdun lo fi gbe igbeaye rẹ ni abẹ idari iyawo rẹ, Ọbabinrin Elisabẹti II - ṣugbọn iru eeyan to jẹ fihan pe ko kan ni i jẹ ọkọ lasan.
Nitori naa, ta ani ọkunrin to duro ti Ọbabinrin naa, ati pe bawo lo ṣe ri Ọbabinrin fẹ ni iyawo?
Ọkọ ni, amọ ko jẹ ọba
Nkan akọkọ: Duke, ti a tun mọ si Arẹmọ Philip, ko si lara awọn ti ipo ọba tọ si - ọmọ rẹ ọkunrin lo wa ni ipo yii - nitori naa ni ko ṣe ni orukọ oye 'ọba'.
Idi ni pe ni ilẹ UK, obinrin to ba fẹ ọkọ ninu ile ọba, le lo orukọ oye 'Ọbabinrin', ṣugbọn awọn ọkunrin to ba fẹ Ọbabinrin ko le pe ara awọn ni ọba. Awọn ọmọkunrin ile ọba nikan lo le ṣe bẹ ẹ.
Ọmọ mẹrin ni Ọbabinrin ati Arẹmọ Philip bi: Arẹmọ Charles(72), Ọmọọbabinrin Anne (70), Arẹmọ Andrew (61), ati Arẹmọ Edward (57).
Gẹgẹ bi awọn ọmọ wọn ṣe sọ, Philip ma n paṣẹ nigba ti wọn wa ni kekere.
Ayaworan laafin ọba, Ingrid Seward sọ pe Arẹmọ Andrew ti sọ ọ ri pe "Ọbabinrin lo ni aanu l'oju ju, amọ baba wọn 'Philip' lo ni ibawi lọwọ.
Bakan naa ni Andrew tun ṣe iranti bi baba rẹ ṣe ma n pa aalọ fun wọn ni alẹ, to si tun ma n tẹti si awọn ọmọ rẹ ti wọn ba n ka iwe Rudyard Kipling, Just So Sories.
Arẹmọ Philip dagba debi i pe ọmọ-ọmọ rẹ kẹjọ dagba l'oju rẹ, o si tun ri ọmọ-ọmọ-ọmọ rẹ kẹwaa.

Nibo lo ti bẹrẹ igbeaye rẹ?
Ọdun 1922 ni irinajo Philip bẹrẹ ni Aafin to wa ni Burkingham.
Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa, ọdun 1921 ni wọn bi ni erekusu Greek, Corfu. Oun si ni abigbẹyin ati ọkunrin kan ṣoṣo ti Arẹmọ Andrew ti Greece ati Ọmọọbabinrin Alice ti Battenberg, bi.
Idile to ti jade mu ki o di Arẹmọ Greece ati Denmark. Amọ ni ọdun to tẹle ibi rẹ, wọn le ẹnbi rẹ kuro ni Greece lẹyin iditẹ gbajọba kan.

Oríṣun àwòrán, Topham/topham picturepoint/pa
Ọkọ oju omi ijagun ti orilẹ-ede Britain lo gbe wọn de Italy ni alaafia, pẹlu Philip to jẹ ikoko, to n sun ninu apẹrẹ kan.
Bawo ni wọn sẹ tọ ọ dagba?
Oriṣiri adanu ati òfò lo ṣẹlẹ nigb ati Philip wa ni kekere.
Ni ọdun 1930, nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹjọ, iya rẹ di eero ileewosan alarun ọpọlọ.
Ẹkọọkan si ni Philip n ri awọn obi rẹ mejeeji lẹyin igba naa. Baba rẹ sọ French Riviera di ile pẹlu aale rẹ kan, awọn ẹbi iya rẹ ni UK si lo tọ ọ dagba.
Orukọ ẹbi naa, Mountbatten si lo pada n jẹ.
Ileewe Gordonstoun, ti Scotland, lo lọ. Ileewe naa lo si ti kọ ẹkọ nipa bi eeyan ṣe n da a duro.

Oríṣun àwòrán, keystone features/getty images

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọdun 1937, ọkan lara awọn ẹgbọn Philip, Cecilie, ku ninu ijamba ọkọ ofurufu pẹlu ọkọ rẹ, ọmọ orilẹ-ede Germany, iya ọkọ rẹ, ati ọmọ rẹ mejeeji.
Inu oyun paapaa lo wa ni asiko naa.
Ko pẹ ti Cecilie darapọ mọ ẹgbẹ Nazi, to n dari eyi to pọju ninu ijọba Germany, ni iṣẹlẹ yii waye.
Pẹlu ibanujẹ ni Philip, ẹni ọdun mẹrindinlogun fi n rin tẹle posi ẹgbọn rẹ ni igboro Darmstadt.
Bawo ni Philip ṣe fẹ Ọbabinrin?
Nigba ti Philip kuro ni ileewe, diẹ lo ku ki ogun ṣẹlẹ laarin Britain ati Germany. O darapọ mọ Britannia Royal Naval College ni Dartmouth (ileewe ikọṣẹ ọmọ ogun ori omi ti UK). Nibẹ si lo ti leke awsn ti wọn jọ wa ni kilaasi.
Nigba ti Ọba George VI ṣe abẹwo ẹnu iṣẹ si ileewe naa lọdun 1939, Philip lodari eto dida awọn ọmọ ọbabirnin kekeeke naa, Elizabeth ati Margaret, lara ya.

Oríṣun àwòrán, Press association
Alamojuto awọn ọmọọbabinrin naa, Marian Crawford sọ pe Philip fakọyọ pupọ. Ihuwasi rẹ si dun mọ Elizabeth to jẹ ọmọ ọdun mẹtala lori.
Ipa kekere kọ ni Philip ko lasiko ogun agbaye keji. Nigba ti yoo fi di ọdun 1942, to ti pe ẹni ọdun mọkanlelogun, Philip ti di ọkan lara awọn ọgagun ori omi to kere julọ.
Lẹta kikọ si ni ọmọọbabinrin naa ati ọgagun fi n ba ara wọn sọrọ.
Lẹyin abẹwo kan ti Philip ṣe si aafin ni asiko ọdun Keresimesi lọdun 1943, aworan rẹ ni Elizabeth gbe si ori tabili niyaara rẹ.
Botilẹ jẹ pe ero diẹ lara awọn amugbalẹgbẹ Elizabeth n sọ oriṣiriṣi nkan nipa Philip ( kii ṣe eniyan jẹẹjẹ, onigberaga, ẹni ti ko kae, ti ko si nii jẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
olootọ), ifẹ ti ọmọọbabinrin ni i si ko dinku.
Ọba George pada fọwọsi igbeyawo wọn, amọ awọn atunṣe kan gbọdọ waye.
Arẹmọ orilẹ-ede Greece ati Denmark ọhun di ọmọ ilu ni Britain, o darapọ mọ Church of England, o si pa gbogbo oye to ni nilẹ okeere ti.
Lọjọ ayẹyẹ igbeyawo rẹ ni ogunjọ oṣu Kọkanla, ọdun 1947, wọn sọ ọ di Duke ilu Edinburgh, orukọ to jẹ titi di opin ay erẹ.
Ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn ni, iyawo rẹ si jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun.
Igbeyawo wọn ko ti i ju ọdun mẹrin lọ, pẹlu ọmọ meji, nigba ti iṣẹ ìlú bẹrẹ.
Orilẹ-ede Kenya ni wọn wa, lẹnu irinajo si awọn orilẹ-ede Commonwealth, ti iroyin iku baba Elisabẹti, Ọba George VI fi ba wọn.
Ẹni ọdun mẹrindinlọgọta lo kú.
Ọgagun Michael Parker, ọrẹ Duke ti Edinburgh, to tun jẹ akọwe ikọkọ fun sọ nipa asiko ti Philip gbọ pe iywao rẹ ti di Ọbabinrin.
"O n wo bi ẹni ti wọn gbe ilaji ẹru gbogbo aye le lori. Aanu eeyan ko ṣe mi bẹẹ ri. O n mi soke-silẹ bi ẹni ti ipaya mu. O ri loju ẹsẹ pe asiko idakọnkọ oun ati Elisabẹti ti dopin.
Opin de ba afojusun Philip gẹgẹ bi ọmọ ologun ori omi, nitori pe Ọbabinrin tuntun yoo nilo ọkọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP/getty images
O di oludamọran ati alabarin fun iyawo rẹ, ojuṣe rẹ si ni lati ma a ṣe atilẹyin fun.
Wahala nla ṣẹlẹ ni nkan bi ọdun 1950, nigba ti Philip fẹ ki idile ọba o ma a jẹ orukọ ẹbi rẹ, Mountbatten.
"Emi nikan ni ọkunrin ti wọn ko faaye gba ni orilẹ-ede yii, lati fi orukọ rẹ sọ awọn ọmọ rẹ!" Bayi lo ṣe fi ibinu sọrọ nigba ti wọn rọ Ọbabinrin lati ṣi ma a jẹ Windsor. "Mi o yatọ si amoeba."
Philip tiraka lati jẹ ṣe awọn ojuṣe ti wọn la kalẹ fun. Ṣugbọn, gẹgẹ bi iru eeyan to jẹ, o pinnu lati fẹ afẹfẹ to yatọ ni aafin ni Buckingham.
Bawo ni Philip ṣe mu ayipada ba idile ọba?
Duke ko gbagbe orisin rẹ ni Greece, o si gbagbọ pe awọn ọmọ idile ọba gbọdọ ni ifarada.
O ṣe idasilẹ eto ti yoo mu ki Ọbabinrin le ba awsn eeyan pade, ;ai fi iru eeyan ti wọn jẹ ṣe.
Awọn ọmọ ọdọ ni aafin dẹkun fifi atike kun irun wọn.
Nigba to tun gbọ pe ile ìdáná mii wa ti wọn ti n dana ounjẹ idile ọba, o ti ẹyọkan pa.
Diẹ lara awọn ayipada to ṣe niṣee pẹlu bi igba ewe rẹ ṣe ri.
Philip ṣeto bi tẹliffonu ṣe wa ninu aafin, ki awọn ọmọ ọdọ o ma ba ma a damu wa jiṣẹ fun Ọbabinrin.
Fun'ra rẹ lo n gbe ẹrù rẹ.
Oun lo si ma n se ounjẹ aarọ rẹ ninu yaara rẹ titi di asiko ti Ọbabinrin yari nitori oorun.
Bawo lo ṣe lo akoko rẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi oludamọran to pẹ julọ ninu itan Britain, oun fun'ra rẹ da ṣe iṣẹ bi i 22,191.
Nigba to fẹhinti lẹnu iṣẹ aafin lọdun 2017, awọn ajọ ati ẹgbẹ to le ni 780 lo sọ ọ di baba'salẹ, ọmọ ẹgbẹ tabi aarẹ wọn.
Orilẹ-ede 143 lo lọ l'ẹnu iṣẹ, to si ma n lo ede French ati German to gbọ.
Amọ, ọkan lara awọn nkan iranti nipa rẹ ni idasilẹ ami ẹyẹ Duke ti Edinburgh, lati ọws ọga ileewe rẹ tlẹlẹ, Kurt Hahn.
Awọn olukopa fun ami ẹyẹ naa (ọmọ ọdun 14 si 25) le gba ami ẹyẹ nipa ṣiṣe iṣẹ iranlọwọ, kikọ nipa ere idaray, iṣẹ ọwọ, tabi gigun apata to ga atbi irinajo ori omi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọdun 2016, ọdọ bi i 1.3 miliọnu lo kopa ninu eto naa lati orilẹ-ede 130.
Ẹni to fẹran ere idaraya ni Philip. O si jẹ ọkan lara eeyan mẹrin to n gbegba oroke ninu ere idaraya Polo ni Uk ni nkan bi ọdun 1960.
Bakan naa lo ma n polongo fun dida ẹmi awọn ẹranko igbo si.
Ninu ọrọ to sọ lati ṣapejuwe ipa to ko ninu itan Britain, Philip sọ pe "Mo ti ṣe eyi ti mo lero pe o dara.

"Awọn eeyan kan gba pe o dara, awọn miran si gba pe ko dara to. Ṣugbọn, kinni mo le ṣe? Mi o le yi bi mo ṣe n ṣe nkan pada. O ti mọ mi lara. Amọ, wọn o gba bẹ ẹ ni."
Philip gbagbọ pe ipamọra ti Ọbabinrin ni lo mu ki ibagbepọ wọn o pẹ, amọ awọn kan ninu ile ọba sọ pe ẹẹrin lo so wọn pọ.

Oríṣun àwòrán, Reuters












