Prince Philip: Wọ́n yìbọn sókè káàkiri Ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì láti ṣẹ̀yẹ Duke ti Edinburgh

Woolwich

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọogun ikọ ibudo Woolwich Barracks to yin ibọn lasiko igbeyawo Ọbabinrin Elizabeth ati Ọmọbakunrin Philip ni ọdun 1947, ati ni ọdun 1953 to jẹ ọba naa yin ibọn lati ṣe ẹyẹ ikẹyin Duke ti Edinburgh

Ayẹyẹ ṣì ń tẹ̀síwájú fún ìsìnkú ọmọọba Philip tó jẹ́ Duke ti Edinburgh nípa bí wọ́n yóò ṣe yìnbọn sókè kákìkiri ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì, ní Gibralter ati lori ọkọ̀ ìjà ojú omi.

Hillsborough
Àkọlé àwòrán, Awọn ikọ ọmọogun wọ ibomu dudu lati yin ibọn ẹyẹ ikẹyin ni Hillsborough.

Ọmọọba Philip, tó jẹ́ ọkọ ọbabinrin ilẹ̀ gẹ̀ẹ̀sí Elizabeth kejì fún ọdún mẹ́tàléláàdọ́rin kú ní ọjọ́ Eti, ọjọ́ kẹsàn, oṣù kẹrin ọdún 2021.

Cardiff

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Awọn eniyan pejọ lati wo bi wọn ṣe n yin ibọn naa.

Philip ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn ni ó ṣe ìjọba ni inú ìtàn ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ̀sí.

Cavalry
Àkọlé àwòrán, Awọn ikọ ọmọọgun to n ṣiṣẹ ninu ile ọba pejọ lati bẹri fun Duke ti Edinburgh pẹlu idake iṣẹju meji.

Àwọn ọmọogun yóò yin ìbọn mọ́kanlélógójì láàrín ìṣẹ́jú kan látimaago mejìlà ọsan ni ìlú London, Edinburgh, Cardiff, àti Belfast, gẹ́gẹ́ bi ilé iṣẹ́ ààbò ilẹ̀ gẹ̀ẹ̀sì ṣe sọ.

Canberra, Australia

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ni orilẹede Australia, wọn so 'flag' orilẹede naa walẹ lati ṣe ayẹyẹ ikẹyin fun Duke ti Edinburgh.

Awọn ọmọ ogun ojú omi fún ilé óba to fi mọ HMS Diamond ati HMS Montrose náà yóò yìnbọn ìkíni fún ayẹyẹ Duke to ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi ọmọ ogun ojú omi lásìkò ogun àgbáyé ẹlẹkejì tó sì gba ipò oye gíga "Lord High Admiral"

Prince Philip: Wọ́n yìbọn sókè káàkiri ilẹ̀ gẹ́ẹ̀sì láti ṣẹ̀yẹ Duke ti Edinburgh
Àkọlé àwòrán, Awọn to n fi òdòdó sí wáju ilé ọba ni Winsdor Castle

Ìbọn yìnyin yìí ni yóò waye loju iworan yin lórí ayélijara tí o si ṣe pàtàkì ki àwọn olùgbé ilẹ̀ gẹ̀ẹ̀sì máa wòó láti ilé.

Wọ́n yìbọn sókè káàkiri ilẹ̀ gẹ́ẹ̀sì láti ṣẹ̀yẹ Duke ti Edinburgh