Prince Phillip: Ọlọ́lajùlọ Ọmọọba Philip, Duke ti Edinburgh jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Terry O'Neill/ Getty Images
Ọmọọba Philip, Ọlọla Duke ti Edinburgh, jẹ ẹniti ọpọlọpọ eeyan maa n bọwọ fun nitori iduro sinsin ati atilẹyin to rinlẹ to nse fun Ọbabirin ilẹ Gẹẹsi nigbakugba.
Isẹ to le ni fun ẹnikẹni lati se, ka to wa sọ ẹni to ti mọ lara lati maa pasẹ gẹgẹbii ọgagun oju omi, ẹni tawọn ero rẹ nipa awọn ọrọ to sọtọọtọ gbopọn pupọ.
Amọ, irufẹ abuda takuntakun to ni yi lo mu ko rọrun fun-un lati maa se ojuse rẹ lọna to pegede, to si tun nse atilẹyin fun iyawo rẹ tọkantọkan gẹgẹbii Ọbabinrin.
Gẹgẹ bii oludamọran si isejọba Ọbabirin, Ọmọọba Philip ko ni ojuse kankan ti ofin la silẹ. Sugbọn kosi ẹnikẹni to sunmọ oriade naa, tabi to se pataki si Ọbabinrin naa ju Ọmọọba Philip lọ.
Wọn bi Ọmọọba Philip torilẹede Greece lọjọ kẹwa osu karun ọdun 1921 ni erekusu Corfu. Iwe ẹri ọjọ ibi rẹ safihan ọjọ kẹjidinlọgbọn osu karun odun 1921 nitoripe orilẹede Greece ko tii se itẹwọgba iwe ọunka ọjọ tilana Gẹẹsi nigba naa.
Baba re Ọmọọba Andrew torilẹede Greece jẹ ọmọ kekere kan ninu awọn ọmọ Ọba George kinni ti Hellenes. Mama rẹ, Ọmọọbabinrin Alice ti Batternberg, jẹ Bẹẹrẹ Ọmọọba Louis ti Battenberg, to si tun jẹ arabinrin si Ọlọla Earl Mountbatten tilu Burma.
Lẹyin iwa iditẹ gbajọba to waye lọdun 1922, ile ẹjọ ajijagbara kan le baba rẹ kuro lorilẹede Greece.
Ọkọ ijagun oju omi kan ti ibatan rẹ Oba George karun, fi ranse lo gbe ẹbi rẹ lọ si orilẹede France.
Inu ibusun to wa ninu apoti alawọ olomi ọsan kan ni Phillip, to jẹ ọmọde jojolo ti lo ọpọ akoko rẹ lasiko irinajo naa.
Oun ni ọmọ to kere julọ, ọmọkunrin kansoso ninu ẹbi to kun fun ọmọbirin, o si lo igba ewe rẹ ni ayika to kun fun ifẹ.
Ọmọọba naa bẹrẹ ileewe lorilẹede France, sugbọn nigba to di ọmọ ọdun mẹje, o pada lọ gbe lọdọ awọn mọlẹbi rẹ to wa ni agbegbe Mountbatten nilu England, nibi to ti lọ si ileewe jẹleosinmi ni Surrey.
Lasiko yi, iwadi isegun fihan pe mama rẹ ni arun ọpọlọ (chizophrenia), wọn si ti gbe lọ sile iwosan awọn alarun ọpọlọ. Ọmọọba kekere naa ko lee farakinra pẹlu iya rẹ ju igba diẹ lọ.
Ni ọdun 1933 wọn ran lọ sileẹkọ Schule Schloss Salem to wa ni guusu orilẹede Germany, eyi ti Kurt Hahn tii se oludasilẹ eto ẹkọ jẹ alakoso rẹ.
Sugbọn laarin osu diẹ, Hahn to jẹ ẹya Juu lo di dandan fun lati sa asala kuro ni Germany nitori ifiyajẹni awọn Nazi.
Won darukọ rẹ ninu awọn atẹjade kan
Hahn pada si Scotland nibi to ti da ileewe Gordonstoun silẹ, ibẹ ni wọn da Ọmọọba naa pada si lẹyin to lo saa eto ẹkọ meji ni Germany.
Ilana lile ileewe Gordonstoun, to da lori didaduro funra ara ẹni, jẹ ayika to daraju fun ọmọkunrin ti ko gbe lọdọ awọn obi rẹ, lati lero pe oun lee da duro.
Ni akokọ ti ogun nsunmọle, Ọmọọba Philip pinnu lati darapọ mọ isẹ ologun. O fẹ darapọ mọ ileesẹ ologun ofurufu tilẹ Gẹẹsi (Royal Air Force).
Sugbọn asa sise isẹ awakọ oju omi wọpọ laarin awọn ẹbi iya rẹ, idi si ree to fi di ọmọ ogun labẹ ileesẹ ologun oju omi ( Britannia Royal Naval College) ni Dartmouth.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọọba di ọmọ ogun nileewe ologun oju omi Royal Naval College, ti Dartmouth.
Ni asiko to wa nibẹ, wọn yan-an pe ko maa se ẹsọ ọmọọbabirin kekere meji, Elizabeth ati Margaret, nigba ti Ọba George kẹfa ati Obabirin Elizabeth sabẹwo sileewe naa.
Gẹgẹ bawọn eeyan ti abẹwọ naa soju wọn ti wi, Ọmọọba Philip huwa se-karimi pupọ lasiko naa.
Sugbọn ipade naa ko kuro lọkan ọmọọbabirin Elizabeth to jẹ ọmọ ọdun mẹtala.
Bẹẹ si ni Philip fi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹni to ni ọjọ iwaju dara-dara, pẹlu bo ti se ipo kinni ni kilaasi rẹ losu kinni, odun 1940, o si foju ri ikọlu awọn ologun fun igba akọkọ loju agbami okun India.
Wọn gbe lọ soju ogun HMS Valiant laarin ọwọ ologun to wa ni ẹkun okun Mediterranean, wọn si darukọ re ninu awọn iatẹjade kan lori ipa to ko ninu ogun Cape Matapan lọdun 1941.
Gẹgẹ bi osisẹ ologun to wa ni ẹka to n risi sise awari ina ọkọ oju omi to ba nbọ, o ko ipa pataki ninu awọn ikọlu ologun to n waye lọwọ alẹ.
"Mo ri ọkọ oju omi miran, o si tan ina si aarin rẹ, lẹyin naa lo poora loju ẹsẹ nigba ti wọn da ọta ibọn ti iwọn ikọọkan rẹ to ọpa mẹẹdogun boo."
Ni osu kẹwa ọdun 1942, o jẹ ọkan lara awọn ọgagun oju omi to kere julọ lọjọ ori ninu awọn ọmọ ogun oju omi Royal Navy, to si sisẹ lori ọkọ ijagun oju omi HMS Wallaface.
Tọkọ-taya oju ọna
Ni gbogbo akoko to wa nileesẹ ologun oju omi yii, oun ati ọmọọbabirin Elizabeth kekere nkọwe ransẹ sira wọn, wọn si ransẹ sii lati wa gbe pẹlu awọn ẹbi ọba naa laimọye igba.
Lẹyin irufẹ ọkan lara awọn abẹwo yii, lẹyin ọdun Keresimesi 1943, ni Elizabeth fi aworan Philip to wa ninu asọ ologun sori tabili imura rẹ.
Akoko ti ogun pari, ti alaafia si bẹrẹ si ni jọba ni ifẹ wọn gbopọn sii, bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹsọ kan to jẹ Sọbaloju laafin lodi si tako ifẹ wọn yii- ọkan lara wọn si se apejuwe Ọmọọba Philip gẹgẹ bii "Oloorun ati Alailẹkọ."
Sugbọn Ọmọọbabirin kekere naa ti yofẹ ati pe, ni akoko ooru ọdun 1946, ololufẹ rẹ tọrọ rẹ lọwọ ọba lati fi se aya.

Oríṣun àwòrán, PA
Sugbọn ki wọn to kede pe awọn mejeeji ti di ọkọ ati iyawọ afẹsọna, Ọmọọba naa nilo lati di ọmọ orilẹede mii tuntun ati orukọ mọlẹbi tuntun.
O fi oye rẹ lorilẹede Greece silẹ, o di ọmọ ilẹ Gẹẹsi, bẹẹ lo si bẹrẹ si lo orukọ iya rẹ to jẹ ti Gẹẹsi, Mountbatten.
Ni ọjọ aisun ọjọ igbeyawo rẹ, Ọba George kẹfa fun Philip ni oye ọlọla julọ, nigba to si di owurọ ọjọ igbeyawo, wọn fi jẹ oye Ọlọla (Duke) ti Edinburgh ati Alasẹ (Earl) ti ẹkun Merioneth ati Baron.
Wọn se igbeyawo naa ni ile-ijọsin Westminster Abbey ni ogunjọ osu kọkanla ọdun 1947. Gẹgẹbii Wiston Churchill ti se akawe rẹ, igbeyawo naa jẹ "alarabara" nilẹ Gẹẹsi to dakẹrọrọ lẹyin ogun.
Ọlọla Duke pada si isẹ ologun-oju omi rẹ, wọn si taari rẹ lo si orilẹede Malta nibi ti tọkọ-t'aya naa ti ri aaye lati gbe igbe aye ẹbi ologun fun igba diẹ, gẹgẹbii awọn ẹbi yoku.
Wọn bi akọbi wọn, Ọmọọba Charles, ni aafin Bukingham lọdun 1948, ati ọmọbirin kan, Ọmọọbabirin Anne, lọdun 1950.
Ni ọjọ keji osu kẹsan ọdun 1950, o se aseyori nidi ohun to maa njẹ afojusun ọmọ ologun kọọkan, nigba ti wọn fun ni ẹka ileesẹ ologun oju omi tiẹ, HMS Magpie.
Sugbon isẹ ologun rẹ ti fẹrẹ dopin. Ailera Ọba Geoge kẹfa tumọ si wipe ọmọ rẹ obirin yoo tubọ gbe ẹru isẹ aafin wọ, to si nilo ọkọ rẹ lẹgbẹ rẹ.
Philip gba isinmi nileesẹ ologun oju omi losu keje ọdun 1951. Kọ si pada si isẹ ologun naa mọ.
Ọlọla Duke kii se ẹni to maa n kabamọ lori ohunkohun, sugbọn lẹyin-orẹyin o sọ wipe oun kabamọ pe oun ko tẹsiwaju ninu isẹ ologun oju-omi.
Awọn ojugba rẹ sọ wipe pẹlu awọn aseyọri rẹ, ko ba ni agbega ninu isẹ ologun oju omi titi de ipo ọga agba pata nileesẹ ologun oju omi.
Ni ọdun 1952, awọn tokọtaya to jẹ ọmọ ọba naa gunle irinajo sawọn orilẹ-ede to ni ajọsepọ pẹlu ilẹ Gẹẹsi lagbaye (Commonwealth) eyi to ti wa lakọọlẹ fun Ọba ati Ayaba lati se tẹlẹ.
Awọn ẹrọ ọtun to jẹ tigbalode
Nigba tawọn tọkotaya naa nnaju lọwọ ọgba-ẹranko kan lorilẹ-ede Kenya ninu osu keji ni iroyin de wi pe ọba ti waja.
Aisan asekupani to nmu ki ẹjẹ inu ọkan di lo n baa finra eyiti wọn npe ni coronary thrombosis.
Ojuse Ọmọọba naa si ni lati sọ iyawo rẹ wipe oun ni ọba kan.
Gẹgẹ bi ọrẹ rẹ kan ti s'apejuwe isẹlẹ naa lẹyin-ọrẹyin, o ni Ọmọọba Philip wa nwo bii ẹni ti idaji ile aye ja le lori.

Oríṣun àwòrán, AFP
Niwọn igba ti ko lee pada sidi isẹ ologun oju omi to nse mọ, o gbọdọ se agbekalẹ ojuse kan fun ara rẹ, bi Elizabeth si se gun ori itẹ tun mu ki ibeere nipa ohun to yẹ ki ojuse naa jẹ tun jẹ jade.
Bi asiko iwuye naa si se nsunmọle, asẹ ọba kan kede wipe ojuse Ọmọọba Philip yoo fidi mulẹ gẹgẹ bii ẹni to kangun si ọbabinrin sugbọn ko ni ipo kankan ninu akọọlẹ ofin.
Ọlọla Duke ni ero pupọ nipa awọn ọna to yẹ lati sọ isejọba di ti igbalode ko si mu adinku ba awọn ilana isejọba to ti di ogbo, sugbọn ero rẹ yi ko ri ita nitori awọn ẹsọ ọba kan ti wọn ti di ogbologbo si aafin to nse atako rẹ.
Ajalu to koro
O dari gbogbo okun inu rẹ si idi ajosepọ pẹlu awọn eeyan. Oun atawọn ọrẹkunrin rẹ kan maa n pade lọsọọsẹ ninu awọn yara kan to wa ni oke ile-ounjẹ kan ni adugbo Soho to wa laarin gbugbu ilu London.
O kundun lilọ si apejẹ ọsan pẹlu awọn alabarin rẹ ati ile-ijo ni alẹ, wọn si maa nya aworan rẹ pẹlu awọn alabarin ti imura wọn se gẹgẹ.
Ibi kansoso ti wọn ti fun Ọmọọba naa ni agbara lati pasẹ ni eyi to jẹmọ mọlẹbi rẹ bi o tilẹ jẹ wipe o fidi rẹmi ninu igbinyanju rẹ lati kede orukọ tawọn ọmọ rẹ yoo jẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijakulẹ nla ni ipinnu ọbabirin wi pe orukọ ẹbi naa yoo maa jẹ orukọ idile ọba ilẹ Gẹẹsi, Windsor, dipo orukọ idile Ọmọọba Philip tii se Mountbatten eyi to jẹ nkan ibanujẹ nla fun un.
Ọmọọba naa fi apa janu fawọn ọrẹ rẹ nigba kan pe "Emi nikan ni ọkunrin to wa ninu ilu yi ti ko ni anfani lati fun awọn ọmọ rẹ ni orukọ rẹ gẹgẹ bi orukọ idile wọn. Afoomọ to n jẹ lara ẹlomiran ni mi."
Gẹgẹ bii obi, Philip le e se bii ẹni ti ko ni suuru tabi ẹni ti ko bikita nigba mii.
Gẹgẹ bii ẹni to kọ itan igbesi aye Ọmọọba Charles, Jonathan Dimbleby ti wi, Ọmọọba naa bu sẹkun nigba to wa ni kekere ti baba rẹ baa wi nita gbangba, bẹẹni ibasepọ laarin baba ati akọbi rẹ ọkunrin yii ko rọgbọ rara.
Philip tẹnumọ wi pe Ọmọọba Charles gbọdọ lọ sile-iwe rẹ atijọ toun naa lọ, Gordonstoun, pẹlu igbagbọ pe ọwọ lile ti wọn maa fi n mu awọn akẹkọọ nibẹ yoo seranwọ lati fopin si bi ọmọ rẹ se maa n fa sẹyin laarin eeyan.

Oríṣun àwòrán, PA
Sugbọn Ọmọọba kekere naa korira ile-iwe yii, nibi to ti maa n se aaro ile, tawọn akẹẹgbẹ rẹ si doju lee lati fi se yẹyẹ.
Awọn iwa Duke yi se afihan abuda lile rẹ, eyi to jẹyọ lati ara bo se da wa ni kekere.
Ipọ to ba ara rẹ kan-an nipa fun-un lati da duro lati igba ewe, to si soro fun-un lati gba pe kii se gbogbo eeyan lo ni abuda to lagbara bii tirẹ.
Ọkan lara awọn nkan to jẹ Ọmọọba Philip logun julọ idẹrun awọn ọdọ.
Ni ọdun 1956 ifẹ to ni si idẹrun awọn ọdọ yi lo se atọna ifilọlẹ ami ẹyẹ Duke ti Edinburgh fawọn alasẹyọri.
Fun ọpọlọpọ ọdun, ami ẹyẹ ọhun fawọn ọdọ to jẹ abarapa atawọn to ni ipenija ara bii miliọnu mẹfa lo wa fun.
Awọn naa lo ni anfaani lati pe ara wọn nija ninu ara, ninu ọpọlọ, ati ni ero ninu awọn eto ita gbangba ti wọn se agbekalẹ rẹ lati se agbelarugẹ isẹ ajumọse, ọgbọn atinuda ati ibọwọ fun isẹda.
Ọmọọba Philip sọ fun ileesẹ BBC pe: "To ba fi lee mu kawọn ọdọ se asẹyọri ninu isẹ kan ti wọn ba dawọle, idunnu nipa sise asẹyọri nidi isẹ yii yoo ran awọn isẹ yooku."
Ni gbogbo ọjọ aye rẹ, Ọlọla Duke tubọ fi akoko silẹ sii lati tẹra mọ eto ọhun, to si nlọ si orisirisi ayẹyẹ, bẹẹ lo tun nkopa ninu awọn eto ti wọn la silẹ fun-un lojoojumọ.
‘Iwa Ọmọluabi’
O maa nsọrọ pẹlu itara nipa ẹtọ ẹranko ninu igbo ati aato ayika, bi o tilẹ jẹ wipe ipinnu rẹ lati yin ibọn mọ ẹkun kan lasiko abẹwo rẹ si orilẹede India lọdun 1961 fa ẹhonu.
Bi Ọmọọba tun se tẹ aworan kan jade ninu eyi to ti safihan ẹkun naa gẹgẹ bii ife ẹyẹ, jẹki ọrọ naa buru si.
Sibẹsibẹ, o fi okiki ati agbara rẹ satilẹyin fun agbega apo asunwọn ẹdawo fawọn ẹranko igbẹ, eyi to pada di apo asunwọn ẹdawo fun isẹda , to si jẹ ẹni to l'ẹtọ lati je aarẹ akọkọ fun ajọ naa.

Oríṣun àwòrán, PA
O sọ fun akọroyin BBC kan pe: "Mo lero wi pe nkan iyalẹnu ni wi pe a ni orisirisi nkan abẹmi nile aye yii, ti gbogbo wọn gbe ara le ara wọn."
"Mo si tun lero pe ti awa eniyan ba ni agbara iye ati iku- ka le ku tabi wa laye- o yẹ ka lo agbara naa pẹlu iwa ọmọluabi.
Kin lo de taa fi pa nkan rẹ nigba ti a ko nilo ati se bẹẹ?"
O mu inu bi awọn alailaju kan nigba to npọn lẹyin iwa yiyin ibọn pa ẹye inu igbo kan.
O sọ pe : "To ba ni ẹran igbẹ kan to fẹ ko ye nitori pe o fẹ mu diẹ ninu rẹ lọdun to nbọ- gẹgẹ bi agbẹ,
O gbiyanju lati kore rẹ ni, o ko fẹ paa rẹ."
Ede aiyede
Ọpọlọpọ eeyan maa n gboriyin fun nitori bo se tẹpa mọ aabo igbo aye ati ipolongo lati tako pipa awọn ẹja inu okun pupọju.
Bakan naa ni Ọmọọba Philip nifẹ sawọn ileesẹ nlanla, o si maa n sabẹwo sawọn ileesẹ, to si di baba isalẹ ẹgbẹ awọn onileesẹ nlanla (Indutrial Society) ti wọn pe ni Work Foundation bayii.

Oríṣun àwòrán, PA
Nigba to nba awọn onileesẹ kan sọrọ lọdun 1961, Duke fi iwa aile fi ọrọ sabẹ ahọn sọ rẹ han si wọn, nigba to sọ fun wọn pe: "Ẹyin Arakunrin, asiko tito taa fa awọn ọmọ ika wa yọ."
Iwa bi Duke se n sọ oju abẹ niko yi lawọn eeyan kan gba sodi, ti wọn si ri bii iwa alailẹkọ eyi to maa nko sinu iyọnu nigba mii.
O si di olokiki ninu awọn isẹlẹ ti wọn ti sii gbọ. paapa nigba to ba sabẹwo silẹ okeere.
Ọrọ kan to sọ tawọn eeyan ngba mọ ara wọn lọwọ, bii ẹni gba igba ọti julọ lo waye lasiko to tẹle Ọbabinrin lọ se abẹwo si orilẹ-ede China lọdun 1986.
Nibẹ lo ti sọ ọrọ kan to ro pe bonkẹlẹ ni nipa "awọn oju to jin sinu"
Awọn iwe iroyin ba fariga, bo ti lẹ jẹ wipe ọrọ naa ko gba ilẹ to bẹẹ nilẹ China.
Nigba to bẹ ilẹ Australia wọ lọdun 2002, o bi onisowo abalaye kan leere pe: "Se ẹ si n tun ju ọkọ̀ sirayin".
Nigba tawọn kan n se atako rẹ gidi fun ailẹmi ikora ẹni nijanu yii, awọn ẹlomii ri abuda rẹ yi gẹgẹ bii ẹni to nsafihan irufẹ ọkunrin to jẹ, ẹni to kọ lati maa karibọnu nitori ibawi oselu.
Nitootọ ọpọ eeyan lo ri awọn asisọ rẹ yi gẹgẹ bii ara ọna lati dẹẹrin pa ẹẹkẹ araalu, ki ara wọn si fuyẹ.
Ni gbogbo ọjọ aye rẹ, Ọmọọba Philip safihan ifẹ to ni si ere idaraya.
O maa n wa ọkọ oju omi, o gba bọọlu kirikẹti ati bọọlu atori ẹsin-gba, o se aseyori nibi wiwa ọkọ ẹlẹsin, o si jẹ aarẹ fun ẹgbẹ awọn agun-ẹsin lagbaye fun ọpọlọpọ ọdun.

Oríṣun àwòrán, PA
Aifararọ to wa laarin rẹ ati Arẹmọ rẹ tubọ foju han lẹyin ti won tẹ iwe igbesi aye Ọmọọba Charles, ti Jonathan Dimbley kọ, sita
Wọn sọ wipe Ọlọla Duke ti Edinburg lo fi tipa mu Charles lati fẹ Diana Spencer.
Sibẹsibẹ Duke lo nse alagbawi ju bi awọn alatako ti lero lọ, nigba ti igbẹyawo awọn ọmọ rẹ n fori sọpọn.
O n lewaju ninu igbiyanju lati ni oye nipa isoro yii, eyi to wa lati ipasẹ awọn iranti iriri asiko to le to ti ni sẹyin nitoripe o fẹ iyawo nidile Ọba
==========Ọjọ ogbo ko mu adinku ba akitiyan rẹ rara. o n rinrin ajo bo se fẹ, paapa fun eto ẹdawo aabo awọn ẹranko igbẹ ati pẹlu Ọbabinrin lẹnu abẹwo isẹ ilu silẹ okeere.========
Irin ajo ẹsin
Ọmọọba Philip nbanujẹ nitori bi igbeyawo ọmọ rẹ mẹta ninu mẹrin se fori sanpọn - Ọmọọbabinrin Anne, ati Ọmọọba Andrew, to fi mọ Ọmọọba Charles pẹlu.
Sugbọn o maa n kọ lati sọrọ nipa awọn nkan to ba jẹ ti ara rẹ, o sọ fun iwe iroyin kan lọdun 1994 wipe oun ko se bẹẹ ri, oun ko si ni bẹrẹ si ni se bẹẹ lasiko naa.
Ọjọ ori rẹ to ndi ogbo ko din lilọ-bibọ rẹ ku.
O n tẹsiwaju lati rin irinajo kikan-kikan, bo se nrin irinajo fun apo asunwọn ẹdawo fun awọn ohun isẹda, naa lo tun nba ọbabinrin lọ se awọn abẹwo to nse sawọn ilẹ okeere.

Oríṣun àwòrán, PA
O rin irinajo ẹsin lọ silu Jerusalem ni ọdun 1994 lati sẹ abewo si oju orori iya rẹ. Ifẹ ọkan iya rẹ lati jẹ ki wọn sin oun si Jerusalem wa si imusẹ.
Akoko ibanujẹ mii waye fun-un lasiko ayẹyẹ iranti aadọta ọdun ti orilẹede Japan kede lati jawọ ninu ogun agbaye keji, taa mọ si VJ Day, eyi to waye ni ọdun 1995.
Inu ọkọ ijagun oju omi ilẹ Gẹẹsi ni Ọmọọba Philip wa nigbati ariwo sọ pe orilẹede Japan ti jawọ ninu ogun naa, nigba ti o si di ọjọ ayẹyẹ iranti yii, o darapọ mọ awọn ajagunfẹyinti yoku lati yan bi ologun kọja niwaju Ọbabirin.
Ọrọ itunu
Bakan naa lo tun kaanu pẹlu awọn eeyan ti orilẹ-ede Japan mu nigbekun tẹlẹ, amọ to nira fun un, tabi ti wọn faake kọri pe lailai awọn ko ni se aforijin fun iwa ti wọn hu si wọn.
Amọ iwa kogberegbe rẹ dinku diẹ lọdun diẹ sẹyin, nitori bawọn araalu se gbe oju agan si idile Ọba lẹyin iku Diana, Ọmọọbabirin Wales.

Oríṣun àwòrán, AFP
Wọn tẹ awọn lẹta ti Duke ati Ọmọobabirin Diana kọ si ara wọn sita lọdun 2007 lati tako iroyin kan to sọ wi pe n se lo maa n le oju mọ iyawo ọmọ rẹ.
Awọn lẹta naa, ti wọn npe ni "awọn lẹta baba mi tootọ" fihan wipe o jẹ igi lẹyin ọgba nla fun Diana, eyi to foju han ninu ohun tutu ti Diana fi kọ awọn lẹta naa sii.
Mohammed Al fayed, to jẹ baba fun alabarin to gbẹyin fun Diana, Dodi, gan an daba nibi eto ayẹwo lati mọ iru iku to pa Diana, sọ pe asẹ ti Ọmọọba Charles pa lo sokunfa bi wọn se gbẹmi rẹ - ẹsun yii si ni alaga igbimọ oluwadi ọhun tako gidigidi.
Ọmọọba Philip, Ọlọla Duke ti Edinburgh, jẹ ọkunrin to ni ipinnu ọkan to le pupọ ati ọkunrin to lee da duro funra rẹ, ẹni to maa n ba ara rẹ ni aarin gbungbun awujọ ilẹ Gẹẹsi.
'O jẹ ẹniti kogberegbe'
O jẹ ẹni ti o ni abuda asaaju lati ọrun wa, amọ ti ojuse rẹ gẹgẹ bii ọkọ Ọbabinrin maa n jẹ ko gba ipo keji, ọkunrin to ni inu fufu ni eyi to maa n tako ipo ẹlẹgẹ to di mu.

Oríṣun àwòrán, AFP
O sọ fun BBC nigba kan pe: "Mo ti se nkan ti ipa mi ka.
Emi ko lee sadede yi ihuwasi mi pada.
Emi ko lee yi awọn ifẹ ọkan mi pada tabi iha ti mo maa n kọ sawọn nkan. Ilana igbe aye temi ni eleyii"
Olotu ijọba ilẹ Gẹẹsi, David Cameron, naa fidi eyi mulẹ nigba to nbu ọla fun Duke ni aisun alẹ ọjọ ibi aadọrun ọdun rẹ ninu osu kẹfa ọdun 2011.
O sọ pe: "O maa n se nkan rẹ l'ọna to lee gba fi se awokọse funra rẹ pẹlu ilana kogberegbe eyi ti mo nigbagbọ pe awọn eeyan ilẹ Gẹẹsi yọnu si.
Philip se aseyọri nidi lilo ipo rẹ lati ko ipa nla si igbe aye awọn eeyan ilẹ Gẹẹsi, to si tun ko ipa tirẹ lati se iranwọ fun idile Ọbabinrin ki wọn lee faramọ iyipada to nba awujọ lati ọdunmọdun.
Sugbon aseyori rẹ to tobi julọ laise aniani ni Bo se jẹ opomulero ati igi lẹyin ọgba fun Ọbabinrin ninu isejọba ọlọdun gbọọrọ rẹ.
O ni igbagbọ wi pe isẹ rẹ ni, gẹgẹ bi o ti sọ fun onkọtan rẹ, "lati ri daju wi pe Ọbabinrin le e dari ilu."
Ninu ọrọ apilẹkọ kan to ka nibi ayeye ajọdun aadọta ọdun ti wọn se igbeyawo wọn, Ọbabirin gboriyin fun ọkọ rẹ, tii se Olugbaninimọran to tii pẹ julọ ninu itan ilẹ Gẹẹsi.
Ọbabirin sọ pe: "O jẹ ẹnikan ti ori rẹ kii wu ti wọn ba n gbe oriyin fun-un, sugbọn o jẹ agbara mi, ẹni to duro ti mi ni gbogbo ọdun yii. Emi naa, ati gbogbo ẹbi rẹ pẹlu orilẹede yi ati awọn orilẹede miran jẹẹ ni gbese to ju nkan ti yoo le beere lọ lailai tabi eleyi ti a lee mọ."
Gbogbo awọn aworan yii lo loluwa












