Insecurity in Lagos: Ìṣọ́ òru ní obìnrin náà ti ń bọ̀, kó tó kàgbákò ìkọlù

Oríṣun àwòrán, @followlasg
Àwọn jàndùkú kan gún ìyá ọlọ́mọ mẹ́ta, Oluwakemi Odugbesan pa ni agbegbe Oduntan ladugbo Ketu nípìnlẹ̀ Eko lọ́jọ́ Satide.
Wọ́n pa arábinrin náà lásìkò tí wọ́n fẹ́ jí fóònù àti báàgì àpamọ́wọ́ rẹ̀.
Obìnrin ẹni ọdun mọ́kànlélógójì náà ni wọ́n pàdé lásìkò tó n bọ̀ láti ilé ìjọsin tó lọ fún iṣọ́ òòru ni aago mẹ́fà ìdájí ọjọ́ náà.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Alaafin kọ́lé tuntun fún ọ̀kan lára Olorì rẹ̀ ní Ibadan, ariwo sọ
- Davido, Pasuma àti Yinka Ayefele dábírà lópin ọ̀sẹ̀, aráyé múgbe bọnu
- Oríadé míì nílẹ̀ Yorùbá tún kàgbákò ìkọlù agbébọn
- Ìjà parí! Ẹgbẹ́ dókítà dáwọ́ ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ mẹ́wàá dúró
- Duke ti Edinburgh ti dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 99
- Ìlẹ̀kẹ̀ otútú ọgbọ̀n, Ìrọ́kẹ́, àwa ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ náà fẹ́ káwọn ọmọ wa máa wọ lọ sílé ìwé - Elebuibon
- Àrà kengé! Ṣọ́ọ̀ṣì Church of England fẹ́ dá ère idẹ Benin méjì padà sí Nàìjíríà
- Ẹ wo àwòrán bí wọ́n ṣe yìbọn sókè káàkiri Ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì láti ṣẹ̀yẹ Duke ti Edinburgh
Gẹ́gẹ́ bi ìròyìn ṣe sọ, agbegbe Oduntan ni arábìrín náà ń gbé ó sì tí fẹ́ẹ̀ dé ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀ nigbati isẹlẹ naa waye.
Lẹ́yìn ti wọ́n ṣe iṣẹ́ ibi náà tán, ọ̀kan nínú àwọn ọdaran ọ̀hún ló fi fóònu Oluwakemi pe ìyá rẹ̀, láti sọ ǹkan ti wọn se fun ọmọ rẹ.
Ẹni ti ọ̀rọ̀ náà ṣe ojú rẹ̀ ṣàlàyé pé, Oluwakemi tó jẹ́ àkọ́bi nínú ọmọ marun ti ìyá rẹ̀ bi, ni wọ́n gún ni ni àyà lẹ́ẹ̀mẹ̀ta .
Wọ́n sáré gbe lọ sí ilé ìwòsàn Azir ni opópónà Oduntan, sùgbọ́n ó pada gbé ẹmi mi nítorí pé ẹjẹ̀ tó ṣòfò lara rẹ ti pọ̀jù.
Àwọn ẹbi olóògbé tí mú ẹjọ́ náà lọ sí agọ́ ọlọ́pàá tó wà ni Ketu.
Ọjọ́ ìbí ọkọ Oluwakemi ni wọ́n pa á, ọ̀sẹ péréte ló kù kí tọkọtaya Odugbesan lọ tẹ̀dó si orílẹ̀-èdè Canada, kí wọ́n to dá ẹmi rẹ̀ légbodò.
Gbogbo Ketu àti agbègbè rẹ̀ ló ti wà nínú ìbẹ̀rù bojo láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ́.
Láti ńkan bi ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹyin báyìí, ó kéré tán, ènìyàn mẹ́wàá ni àwọn janduku ti kojú ni oríta agbegbe náà ni ìdáji tàbi alẹ́.














