Baruwa Gas Explosion: Àwọn tó forí sọta ìjàmbá iná ń bẹ ìjọba láti dìde ìrànwọ́

Àkọlé fídíò, Baruwa Gas Explosion: Àwọn tó forí sọta ìjàmbá iná ń bẹ ìjọba láti dìde ìrànwọ́

Ọjọ nla ni Ọjọbọ ọjọ Kẹjọ osu Kẹwa ọdun 2020 ti isẹlẹ ibugbamu to fa ina alagbara waye ni adugbo Baruwa nilu Eko.

Awọn eeyan to fi ori sọta isẹlẹ ọpa gaasi to bẹ, eyi to di ijamba ina naa, ti wa n naka aleebu si ijọba ipinlẹ Eko, ti wọn si n fi ẹsun kan wọn pe o pa awọn ti lai da si awọn mọ.

Awọn eeyan naa ni ẹmi mẹjọ lo sofo sinu isẹlẹ ijamba ina ọhun, ti ile to to aadọta niye si jona kanlẹ lasiko isẹlẹ naa to ba tọmọde-tagba.

Ọkan lara awọn naa to ba BBC Yoruba sọrọ, ẹni to padanu ẹgbọn rẹ obinrin ati ọmọ meji sinu ofo ina ọhun tiẹ mẹnuba awọn ohun ti oju wọn n ri lẹyin ijamba naa.

Bakan naa ni awọn miran tun sọrọ nipa ọpọ eeyan miran to fori sọta ijamba lati ipasẹ ọpa gaasi to bẹ ọhun pẹlu isoro lọkan o jọkan ti wọn n la kọja.

Ko tan sibẹ, wọn tun mẹnuba awọn eeyan miran to fori sọta isẹlẹ naa ati iru ipo ti wọn wa nile iwosan lai jẹ pe ijọba wẹyin wọn wo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn wa n rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Eko lati dide sọrọ naa, ko si se iranlọwọ to tọ fun awọn.