Pay to use Twitter: Elon Musk kéde pé àwọn ìjọba yóò má a san owó láti lo Twitter

Oríṣun àwòrán, Reuters
Àwọn oniṣowo ati ileesẹ ijọba yoo maa san owo bayii, ki wọn to le lo ori ayelujara Twitter.
Elon Musk, ọga ileesẹ Tesla, lo sọ bẹ. Ikede naa waye lẹyin ti igbimọ Olusakoso Twitter, gbà lati ta a fun Musk, ni biliọnu mẹrinlelogoji Dọla.Sugbọn Musk sọ pe ọ̀fẹ́ ni awọn eeyan yooku yoo ma lo Twitter.
Lati asiko to ti gbà lati ra Twitter ni Ọgbẹni Musk ti sọ pe oun yoo ṣe awọn atunse ti yoo mu ki oju opo naa bojumu si i. Lara awọn ayipada to kede ni pe eeyan le pa nkan to kọ rẹ, fi ọ̀rọ̀ (tweet) pamọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Bákan naa lo sọ pe oun yoo yọ awọn ayederu eeyan kuro. Ọgbẹni Musk ti kede pe o seese ki oun da ileeṣẹ Twitter pada si ọjà ipin idokowo, lẹyin ọdun diẹ.

Oríṣun àwòrán, @elonmusk
Iroyin iwe iroyin Wall Street Journal sọ pe Musk pinnu lati pada ta ipin idokowo Twitter lẹyin bi ọdún mẹta lẹyin to ra a. Labẹ ilana to fi ra ileeṣẹ naa, oun nikan ni yoo ni gbogbo ipin idokowo bayii. Ọgbẹni Musk lo ni owo julọ lagbaye, pẹlu owo to to ọtalerugba din mẹ́wàá Biliọnu Dọla. Lara ileeṣẹ rẹ to n ṣe ọkọ ayọkẹlẹ to n lo ina lo ti ri pupọ ninu owo naa. Bákan naa lo tun ni ìpín to pọ ni ileeṣẹ to n to baalu (rocket) to n wọ inu ofurufu, SpaceX. Odinwọn ileeṣẹ naa to ọgọrun biliọnu Dọla.








