NDLEA: gbẹ́sẹ̀lé Tramadol àtí Exol 5 tí iye rẹ̀ lé ní ₦5b

NDLEA

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ajọ to n gbogun ti tita ati lilo egboogi oloro ni Naijiria, NDLEA, ti kede pe awọn ti gbẹsẹle miliọnu mẹsan an abọ tabulẹti Tramadol ati Exol 5 ti iye rẹ le ni biliọnu marun un naira.

Agbẹnuṣo ajọ naa, Femi Babafemi lo fi ikede naa sita ninu atẹjade kan niluu Abuja.

Babafemi ni awọn gbẹsẹle awọn oogun naa ni papakọ ofurufu ilu Eko, Abuja ati Edo.

O ni awọn ṣe aṣeyọri iṣẹ naa pẹlu ifẹwọsopọ ileeṣẹ aṣobode Naijiria.

NDLEA ni ẹgbẹlẹgbẹ katọnu awọn oogun naa lawọn gbẹsẹlẹ ninu eyii ti awọn oogun naa wa.

Ọwọ NDLEA tun ba Cocaine ati Heroin

Ẹwẹ, NDLEA ni awọn tun ya bo ibi ti wọn ti n ta oogun oloro lagbegbe Wire Road, niluu Benin, ati niluu Uromi, ni ijọba ibilẹ aringbungbun Esan, nibi ti wọn ti gbẹsẹle oogun oloro Cocaine ati Heroin.

Nibẹ ni wọn ti fi ṣikun ofin mu awọn afurasi marun un.

Àkọlé fídíò, 'Láti kékeré mo ti ní ọjọ́ kan lèmi náà ọ́ kọ́ Mọ́sálásí kékeré bíi àwọn bàbá wa'

Babafemi ni wọn fi ṣikun ofin mu ọgbẹni kan, Harrison Odion, to n ta oogun.

O ni awọn ka aadọrin igo codeine lọwọ rẹ, eyii to jẹ oogun ti ijọba ti gbẹsẹle ṣaaju lẹyin iwadii ileeṣẹ iroyin BBC.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, wọn tun gbẹsẹle tabulẹti Tramadol 9,638, tabulẹti Exol 16,843, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Yatọ si eyii, wọn tun dana sun agbegbe kan ti wọn n gbin igbo si ninu aginju Okpuje.

Babafemi pari ọrọ rẹ pe ọga agba ileeṣẹ naa, Buba Marwa gboriyin fun awọn oṣiṣẹ NDLEA fun iṣẹ ribirbi ti wọn n ṣe lati fọ ilu mọ lọwọ oogun oloro.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí