Oladuni Giwa-Osagie: Òrùka mẹ́fà ní ọkọ́ mi fi bèèrè láti fẹ́ mi lẹ́ni ọdún 47

Àkọlé fídíò, Oladuni Giwa-Osagie: Òrùka mẹ́fà ní ọkọ́ mi fi bèèrè láti fẹ́ mi lẹ́ni ọdún 47

Aropin ni ti eniyan amọ ilẹ aanu Oluwa kii su.

Bi ọrọ arabinrin Oladuni Giwa-Osagie se ri ree, ẹni to pe ẹni ọdun mẹtadinlaadọta ko to ni ade ori, to si bi akọbi rẹ nigba to ku diẹ ko pe ẹni aadọta ọdun.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn ipo itiju, ẹgan, ibanujẹ ọkan ati ijakulẹ to ba a lasiko to fi n wa ọkọ, Oladunni ni ẹkun ni oun maa fi n se ounjẹ lojoojumọ.

O salaye pe wọn maa n fi ọkọ bu oun nibi isẹ, ti wọn si maa n lero pe oun ti se iranu ati isekuse ni oun ko se bimọ.

Bakan naa lo salaye pe sna ti wọn fi maa n ba oun sọrọ laarin ẹbi gan ko bu ọwọ fun oun gẹgẹ bii ti awọn to ni ọkọ, eyi to maa n pa oun lẹkun.

Oladuni ni oun ti lọ si ọpọ ile aladura, ti oju ohun si ti ri orisirisi, koda, wọn gba oun nimọran lati ls fẹ ẹni to ti ni iyawo nile amọ oun ko fẹ da ile onile ru.

O ni akoko kan tiẹ wa ti oun gbiyanju lati ra atọ ọkunrin ki oun le da amọ bi amọ oun pada tun ero oun pa ni.

Nigba to n salaye ayọ ọkan to ni nigba to ni ọkọ, Oladuni ni oruka mẹfa ni ọkọ oun fi beere lati fẹ oun, ti oun si n paarọ wọn lojoojumọ.

Nigba toun naa n sọrọ, ọkọ rẹ, Oladapo Giwa-Osagie salaye pe iru obinrin ti oun ti n wa lati ọjọ pipẹ ni Oladuni, inu oun ko si bajẹ ri lati ọjọ ti oun ti fẹ.

Awọn mejeeji wa gba awọn to n wa ọkọ ati aya nimọran lati duro ti Ọlọrun, ki wsn ma si ba ara wọn jẹ tabi lọ da ile onile ru tori pe wọn fẹ bimọ.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: