Girl Child Day 2022: Inú mi dùn pé ọmọ obinrin nìkan ni mo bi -Tawakalitu Olawale
Oní ni ayájọ ọjọ ọmọbinrin lágbàyé.
Lọdun 2019 ayajọ naa gẹgẹ bi a ṣe royin rẹ tí àkọle rẹ jẹ "Ijígìrì ọmọbinrin: kò ni àkọsílẹ̀ kò sì ṣeé dádúró".
Bí gbogbo aye ṣe ń se ayájọ ọjọ yìí, BBC Yoruba fi ọ̀rọ̀ wá Abileko Tawakalitu Olawale to bi kikida ọmọ obinrin nikan lẹ́nu wò láti le mọ ìrírí rẹ.
Eyí wáye nítori àsa to wọ́pọ̀ ààrin àwọn Yoruba pé ọmọ ọkunrin ṣe koko nínú ébi.
Abilekọ Olawale, nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni pé bíbí ọmọbinrin nikan jẹ́ ìdùnú òhun lójoojúmọ nítori ìwuri ni wọ́n jẹ́ àti pé kò si nkan ti ọkunrin ń ṣe ti obinrin wọ́n o lé ṣe.
Ó wá rọ àwọn obinrin lọ́mọde àti lágbà níyànju láti maa gbárùkù ti obinrin ẹgbẹ́ wọ́n ní gbogbo igba.
Nínú ọ̀rọ̀ tìrẹ, asoju ilé iṣẹ́ to n pese iranlọwọ ṣugbọn ti kìí ṣe ti ìjọba, Women Consortium of Nigeria, Morenike Omaiboje naa gboriyin fun awọn ọmọ obinrin.
Morenike sàlàyé pé Orílẹ-ede Naijiria ti kọja pe a fẹ ki obinrin di aya ààrẹ tàbi aya gomina nikan, sùgbọn kì àwọn gan an jẹ aarẹ tabi gomina funra wọn.
Bo tilẹ jẹ́ pé àwọn ọkunrin o fẹ́ gba èyi síbẹ̀ o ni o pọ́ndandan nítori àwọn orilẹ-èdè àgbáye toku ti kúrò ni ipele yìi'.
Morenike ni asiko ti to ki awọn ọmọ obinrin wa mọ pe ko si ipo ti wọn ko lee de laye wọn ati pe ko si iṣẹ ti wọn ko le ṣe.