Òkú sùn rẹpẹtẹ lásìkò tí àwọn agbébọn kọlu abúle bíi 17 ní Plateau

Ọkan lara awọn abule ti wọn dana sun

Ọpọlọpọ eeyan lo ku, ti wọn si tun dana sun ọpọlọpọ ile nigba ti awọn agbebọn kọlu awọn abule kan nipinlẹ Plateau lọsẹ to kọja.

Ikọlu naa ni iroyin sọ pe ko yọ awọn ile ijọsin silẹ ni awọn abule mejilelogun to wa ni ijọba ibilẹ Mangu ati Riyom.

Alaga ẹgbẹ awọn ijọ ọmọlẹyin Kristi nipinlẹ Plateau, to tun jẹ aarẹ ijọ ECWA, Rev. Baba Panya, sọ ninu atẹjade kan pe ọpọlọpọ eeyan ṣi ni wọn ko tii ri lati igba ti ikọlu naa ti waye.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un, ni wọn sin oku awọn eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ, paapaa ni abule Mwaghavul.

Awọn eeyan to n gbe ni abule naa sọ fun BBC pe ọjọ Iṣẹgun ni awọn agbebọn yabo abule naa, ti wọn si kọkọ yinbọn bo ṣe wu wọn, ki wọn to o dana sun awọn ile.

Agba ilu kan sọ fun BBC pe “ko din ni eeyan marundinlaadọrun ti wọn pa ni awọn abule bii mẹtadinlogun ti wọn kọlu, eeyan bi marundinlaadọrun si ni wọn pa.”

Arabinrin Deborah Samuel ti ori ko yọ ninu ikọlu naa sọ pe baba ọkọ oun ati awọn aburo ọkọ rẹ mẹrin lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Botilẹ jẹ pe ko tii si ẹni to mọ nnkan to fa ikọlu naa, awọn olugbe agbegbe naa kan gbagbọ pe ija ẹsan ikọlu si abule Fulani kan ni oṣu diẹ sẹyin ni.