Òṣèré tíátà Yoruba míì, Adewale Adeyemo jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Kemi Filani
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Adewale Adeyemo ti jade laye.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, aarọ ọjọ Aje, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun un, ọdun ti a wa yii ni oloogbe naa jade laye.
Akẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ tiata, Ronke Oshodi Oke, lo kede iku rẹ loju opo Instagram rẹ.
Ronke ni “Hmmm oga bayii ooo... a fẹran rẹ amọ Ọlọrun fẹran rẹ ju wa lọ.”
“Sun re o Adewale Adeyemo.”
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin nnkan bii ọsẹ kan ti gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Murphy Afolabi jade laye.
Awọn oṣere tiata ṣi n ṣedaro Murphy Afolabi lọwọ ti iroyin iku Adewale Adeyemo yii tun gbode kan.
Aisan kidirin at ẹdọforo yọ Adewale lẹnu ṣaju iku rẹ
Ti ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni Adewale ti kọkọ n ṣaisan, to si bere iranlọwọ owo lọwọ lawọn eeyan lọdun naa lọhun.
Iroyin ni aisan ọgbẹ inu lo ro pe o n da oun laamu tẹlẹ amọ ayẹwo fi han lọdun 2020 pe aisan kidirin ati ẹdọforo lo n damu rẹ.
Lẹyin naa ni awọn ẹlẹyinju anu da owo jọ fun lati ṣiṣẹ abẹ.












