Irọ́ ni pé iná ló gbé akẹkọ̀ọ́ Chrisland, Whitney - Ẹlẹ́rìí

Whitney Adeniran

Oríṣun àwòrán, DR. ADENIRAN

Oniṣowo kan ti jẹrii niwaju ile ẹjọ pe Whitney Adeniran, kii ṣe ina mọnamọna lo gbe akẹkọọ Chrisland, Whitney Adeniran to ku loṣu diẹ sẹyin.

Ẹlẹri naa, Ọgbẹni Smart, duro niwaju ile ẹjọ majisireti to wa ni agbegbe Ogba nipinlẹ Eko, sọ lọjọ Aje pe oun wa ni papa iṣere Agege, lọjọ kẹsan-an, oṣu Keji, ti ọmọdebinrin naa deede ṣubu lulẹ lasiko ti ile ẹkọ rẹ n ṣe idije ere idaraya.

O ni oun ma n wa si papa iṣere Agege lati ṣe ere idaraya.

“Lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, mo n jade bọ lati ile igbọnsẹ kan ni mo ri i lati ọọkan pe ọmọdebinrin kan ṣubu lulẹ. Mo si ri ti awọn agbalagba sara si ọdọ rẹ lati ran-an lọwọ.”

O ni to ba jẹ lootọ ni ina gbé ọmọde naa ni ìsọ̀ ẹni to n ta nnkan mimu ‘ice cream’, ko nii si ẹni to le fi ọwọ kan.

Nigba to n dahun ibeere lati ẹnu agbẹjọro ijọba ipinlẹ Eko, ẹlẹrii naa ṣalaye pe oun ti ri ẹni to gan mọ ina ri, ti ko si si ẹnikẹni to le sunmọ ẹni naa, nitori pe yoo ti gan, ati pe igi ni awọn fi kan ẹni naa.

Ṣaaju ni agbẹjọro naa beere lọwọ rẹ pe bawo lo ṣe mọ pe ina kọ lo gbe ọmọdebinrin Whitney Adeniran.

Agbẹjọro A.A. George tun beeere lọwọ rẹ boya o ni imọ nipa ina mọnamọna, ṣugbọn o ni oun ko mọ nipa iṣẹ naa.

“Iriri ti mo ri ri lo jẹ ki n mọ pe ina kọ lo gbe ọmọ naa.”

O fi kun ọrọ rẹ pe ọpọ eyan lo fi ọwọ kan akẹkọọ chrisland naa lasiko ti wọ̀n n gbiyanju lati ran-an lọwọ, ti ina ko si gbé ẹnikẹni ninu wọn.

Amọ o, Ọgbẹni Smart ni lootọ ni oun n jẹri gbé oniṣowo ice cream naa, ṣugbọn oun ko mọ ọ ri ṣaaju iṣẹlẹ iku Whitney.

O ni papa iṣere naa ni oun ti pade oniṣowo naa ni papa iṣere ọhun lẹyin ọsẹ diẹ ti iṣẹlẹ naa waye, lasiko ti oun lọ ọ ṣe ere idaraya.

Ọjọ si ni awọn gba nọmba ara wọn , lẹyin eyi ti oun pinnu lati

Awọn nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ kọkanla, oṣu Keji, ni iroyin iku whitney Adeniran jade si eti gbogbo araalu, nigba ti iya rẹ ke gbajare lori ayelujara pe ọmọ oun kú lasiko idije ere idaraya.

O fi ẹsun kan ile ẹkọ Chrisland pe wọn kọ̀ lati sọ ohunkohun nipa iku ọmọ naa.

Baba ọmọdebinrin naa, Dokita Michael Adeniran ṣalaye fun awọn akọroyin pe ọmọ oun kú lẹyin ti waya ina to wa lara ẹ̀rọ to n ṣe nnkan ipanu ice cream, gbe e lasiko to fi ọwọ kan.

“Lọgan ti ọmọ naa fi ara kan ẹrọ naa, ni ina gbe.”

Ṣugbọn, awọn alaṣẹ ile ẹkọ Chrisland sọ pe irọ ni ẹsun naa, nitori pe oju gbogbo eeyan ni ọmọ naa ti ṣubu lulẹ lasiko idije.

Wọn ni koda, ko kopa ninu idije kankan nitori pe ilera rẹ ku diẹ kaato.

Amọ awọn obi ọmọ naa sọ pe, ko si ohunkohun to ṣe ọmọ awọn.

Eyi lo mu ki ijọba ipinlẹ Eko gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣe iwadii bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.

Ile ẹkọ Chrisland, awọn oṣiṣẹ kan nile ẹkọ naa, ati oniṣowo kan, ni ijọba fi ẹsun aimọọmọ paniyan ati ailakasi kàn.

Adajọ ile ẹjọ majisireti naa ti sun igbẹjọ si ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹfa, lati gba awọn ẹlẹri mii laaye.