Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń nà mí nítorí pé ń kò fẹ́ràn lílọ sí oko ilé ẹ̀kọ́- Buhari

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Aarẹ Muhammadu Buhari ti salaye iriri rẹ nigba to wa nile iwe ẹkọ alakọbẹrẹ ninu fọran kan tí wọn pe akole rẹ ni 'Essential Muhammadu Buhari'.

Ninu fọran ọhun to jade laipe, Aarẹ ni ọpọ igba ni awọn olukọ oun a na oun nítorí oun kuna lati lọ si oko ile ẹkọ.

Aarẹ ni awọn olukọ tí wọn kọ awọn nigba naa mu isẹ lọkunkundun nitori wọn fẹran isẹ naa.

Buhari tun sọ pe:

"Awọn olukọ lasiko ti wa mu isẹ lokunkundun.

Wọn maa ṣe wa bi ọmọ wọn ní.

To ba ṣe daadaa, wọn yoo gboriyin fun rẹ niwaju kilaasi, to ba ku diẹ ka to, wọn yoo bo ẹgba fun wa ni di.

Awon Oluko wo ni Buhari ko le gabgbe:

"N ko le gba gbe Mallam Abdul. Eeyan líle ni, o maa na wa gan, a ma pe ẹgba naa ni 'bulala'.

"Nigba naa, a ko nifẹ si igba ọjọ nitori pe a ni lati lọ si oko ile ẹkọ.

Tí a ba pẹ de ile ẹkọ, lati ago mẹfa ìdajì titi di ago meji ni wọn yoo fi na wa. A o bọ sokoto wa silẹ lati jẹ ki igba naa wọle.

"Ninu awọn olukọ wa, n ko le gbagbe oluko Arabic wa.

Ko si ibi oorun naa ṣe pọ to, yoo gbe nkan sórí.

"Ọpọ igba ni mo maa jẹ ẹgba nitori n ko ki n fẹ lọ dako nile ile ẹkọ wa. To o ko ba si ile ẹkọ."

Ọkọ ayẹta tí Kwankwaso fun mi lo komiyọ lọwọ ado oloro lọdun 2014

Bakan naa ni Aarẹ Muhammadu Buhari salaye ọkọ bọgini tí gomina ana nipinlẹ Kano, Musa Kwankwaso fi ta oun lọrẹ lo ko oun yọ ninu ijamba ado oloro lọdun 2014.

"Eeyan gidi ni Kwankwaso, o bun mi ọkọ ayẹta Land Rover nigba ti mo n dupo aarẹ.

"O ni mo nilo rẹ nitori idije eto ìdibo nigba naa, o sese kí awọn eeyan kan fẹ pami.

"Mo n lọ sí Kano lati ipinlẹ Kaduna ninu ọkọ naa ni ọkọ kan gba iwaju wa, to si ju ado oloro silẹ.

"Nigba ti ma wo ìta, oku tí sun sugbọn gbogbo awa tí awa ninu ọkọ ni nnkan ko ṣe rara