Ohun tó yẹ kí ẹ mọ nípa gbajúgbajà òńkọ̀wé, Ama Ata Aidoo tó kú ní ẹni ọdún 81

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajigbagbara fun ẹtọ obinrin to tun jẹ onkọwe lati orilẹede Ghana, Ama Ata Aidoo ti jade ni aye ni ẹni ọdun mọkanlelọgọrin.

Ama Ata Aidoo ti kọ awọn iwe to sọrọ nipa obinrin ninu awọn iwe rẹ bii The Dilemma of a Ghost, Our Sister Killjoy ati Changes.

Bakan naa lo tabuku bii awọn ilẹ okeere ṣe ri awọn obinrin alawọ dudu bi ẹni atẹmẹrẹ.

Onkọwe naa ṣiṣẹ gẹgẹ bi minisita fun eto ẹkọ ni ọdun 1980 amọ to fi ipo silẹ nitori ko lee sọ eto ẹkọ di ọfẹ ni orilẹede naa.

Awọn akẹkọọ ma n ka iwe rẹ bii Anowa ni ileẹkọ pẹlu awọn iwe onkọwe bii Wole Soyinka ati Chinua Achebe.

Ohun to yẹ ki ẹ mọ nipa Ama Ata aidoo?

Ọdun 1942 ni wọn bi Ama Ata aidoo ni ilu kekere, ni orilẹede Ghana.

Baba rẹ lo kọkọ ṣi ileẹkọ ni ilu naa ti wọn si jẹ ilumọọka.

Nigba to pe ọdun marundinlogun ni o pinnu lati da onkọwe, to si di onkọwe naa laarin ọdun mẹrin.

O di ilumọọka lẹyin to kọ iwe ranpẹ kan, ti iwe naa si wa ninu iwe iroyin awọn to gbe idije naa kalẹ

O ni igba naa jẹ akọkọ to pọn dandan si oun nitori awọn ohun ti oun ni lọkan wa si imuṣẹ.

Lẹyin naa lo lọ si fasiti orilẹede Ghana lati lọ ṣiṣẹ olukọ, to si fi iwe rẹ akọkọ lede ni ọdun 1964.

Lẹyin osu mejidinlogun to kọpa ninu oṣelu, lo kọ iwe fi ipo silẹ to si lọ si orilẹede Zibabwe lati lọ ṣe atipo.

Lẹyin naa lo pada wa di ilumọọka onkowe lai ṣe iṣẹ miran.