Ọlọ́run ti fún APC láàyè láti ṣe àtúnṣe àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn – Wike

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Rivers, Nyesome Wike ti ni o yẹ ki ijọba ẹgbẹ oṣelu All Progressive Party maa dupẹ pe wọn ni anfani miiran lati tun iwa ọmọluabi wọn ṣe pẹlu gbogbo inira ti wọn ko ba awọn orilẹede Naijiria.

Wike, ẹni to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP sọ eleyi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Portharcourt, nibi to ti sọrọ lori ilana ti ijọba to wa lode gbe jade.

Gomina tẹlẹ ṣalaye pe bi ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe kuna lati tẹlẹ ilana naa to fi aye silẹ pe ki iṣejọba jẹ ẹkun-jẹkun lo fa a ti wọn fi ni ijakulẹ ninu eto idibo to waye ninu osu keji, eyi to fun ẹgbẹ APC laye lati bori idibo naa.

“O yẹ ki inu APC maa dun pe Ọlọrun gbe wọn soke nitori PDP kọ lati to ile wọn, O fun wọn laaye lati tun iwa ọmọluabi wọn ṣe niwaju awọn ọmọ Naijiria pẹlu gbogbo nnkan buruku ti wọn ti ṣe.”

Wike gbe oṣuba kare fun Aarẹ Bola Tinubu pẹlu bi o ṣe ṣe ijọba rẹ ni ẹkunjẹkun. O ni irọ ni iroyin to ni Aarẹ sọ orilẹede Naijiria di orilẹede Muslumi pẹlu bi o ṣe yan igbakeji lati ninu ẹsin Musulumi, o nni ero awọn oloṣelu to jẹ ọlẹ niyẹn.

Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima niu ẹnu bẹrẹ sini ma kun nitori wọn jẹ ẹlẹsin kan lati igba ti INEC ti kede wọn gẹgẹ bi ẹni to bori eto idibo.

Wike wa ransẹ ikilọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn n dunkoko mọ Aarẹ lati gba ruku ti ko le se ayeyọri nla.

“Ọlọrun ti fun yin ni oore ọfẹ bayi, wọn wa fẹ ṣe mọdaru.

“Ti Aarẹ ko ba ni ijọba to danmọran, to ba di ọjọ ọla, tani yoo jẹ iya? Ṣe ko ki n se awọn ọmọ Naijiri ni? Ẹjẹ ka gbagbọ pe ọkan ni wa, pe a si ni ipa lati ko.”