Èèmọ̀ dé! Pásítọ̀ pa aláboyún àti èèyàn méjì míì, iléẹjọ́ dájọ́ yíyẹgi fún un

Aworan ọdaran pẹlu awọn

Oríṣun àwòrán, RIVERS STATE POLICE

Pasitọ ile ijọsin kan ni Port Harcourt nipinlẹ Rivers ni ile ẹjọ ti ni ki wọn yẹgi fun bo ṣe ṣeku pa aimọye eeyan.

Pasitọ Chidiebere Okoroafor ti ijọ Altar of Solution and Healing Assembly, Oyigbo, foju bale ẹjọ lori ẹsun pe o pa olori akọrin ijọ naa Concillia Ezenwa ti wọn fura si pe o fun loyun.

Bẹẹ naa ni Pasitọ naa jẹjọ iṣekupani Uluoma Onweagba to jẹ ọrẹ Concillia ọmọ rẹ ọmọ oṣu mẹsan Christabel lọjọ Kọkanla oṣu Kejila ọdun 2017 ni ijọba ibilẹ Oyigbo.

Adajọ S.O Benson, ninu idajọ to gbe kalẹ sọ pe ẹri ati akọsilẹ ibi ti ọdaran naa ti jẹwọ fi han pe lootọ lo jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Adajọ Johnson tẹsiwaju pe awọn to pe Pasitọ naa lẹjọ fidi ọrọ mulẹ to si ni ki wọn yẹgi fun titi ti ẹmi yoo fi bọ tabi ki wọn si gun ni abẹrẹ iku tohun naa a maa yara pa ọdaran.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye

Ni ọjọ kọkanla oṣu Kejila ọdun 2017 ni Pasitọ yi pa Ezenwa sinu ile akọku kan to si pa Onweagba si inu igbo.

Onweagba to gbe oyun oṣu marun un sinu gbe ọmọ kan sẹyin.

Pasitọ ti Onweagba ṣubu ti eleyi si mu ki ọmọ to pan sẹyin naa fori gba ilẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọmọ naa gba ibẹ ku.

A gbọ pe o ṣeku pa Onweagba ki aṣiri ma ba tu wi pe o n ni ajọṣepọ pẹlu Concillia ẹni dun marundinlọgbọn to jẹ olori ijọ akọrin tori pe o ni oun ko ni ṣẹ oyun to ni fun un.

Awọn mọlẹbii oloogbe mu ẹjọ lọ si ọdọ ọlọpaa nigba ti wọn ko ri arabinrin naa ko dari pada sile lyin ti wọn ṣabẹwo si ile Pasitọ .

Concillia lọ ba pasitọ lati jiroro nipa oyun to ni fun un ni Pasitọ ba tan wọ inu igbo ti si pa si inu igbo.

Awọn araadugbo ati ọlọpaa bẹrẹ si ni wa wọn ti wọn si pada ri oku wọn iyẹn oku Onweagba ati ọmọ to pọn sẹyin ninu igbo lẹba oju ọna Afam-lgberu lọjọ Kẹtala oṣu Kejila ọdun 2017.

Ni ti oku Ezenwa, wọn ri oku rẹ lọjọ kejidinlogun oṣu Kejila 2017 ninu ile akọku kan ni Izuoma nijọba ibilẹ Oyigbo.

Wọn gbe Paistọ Chidiebere Okoroafor lọ siwaju adajọ Kariba Braide lori ẹsun onigun mẹta to da lori ipaniyan-wọn lo yin ololufẹ rẹ Concillia Ezenwa to loyun sinu lọrun pa.

Ki aṣiri ma ba tu, o pa eeyan meji mii Uluoma Onweagba ati ọmọ rẹ ikoko ọmọ oṣu mẹsan.

Lẹyin igba naa wọn fi Pasitọ ẹni ọdun mejilelọgbọn naa si ahamọ lati le koju igbẹjọ ni ile ẹjọ giga.