Èrò àwọn lọ́balọ́ba ní ìpínlẹ̀ Ogun ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí òfin tó dé sínsin òkú àwọn Ọ́ba tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde

Àkọlé fídíò, Èrò àwọn lọ́balọ́ba ní ìpínlẹ̀ Ogun ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Lọdun to kọja ni Gomina Dapo Abiodun ti ipinlẹ Ogun lati buwọlu abadofin ti ile ignimọ asofin ipinlẹ Ogun gbe kalẹ, eyi to wa lori ifinijoye ati isinku awọn Ọba nipinlẹ naa.

Lara nnkan ti ofin naa ọhun da le lori ni aawọ to maa n waye laarin awọn afọbajẹ, awọn ẹlẹsin miran atawọn mọlẹbi ọba,

Pẹlu bi gomina se buwọlu abadofin ọhun, gbogbo awọn lọbalọba ni ipinlẹ Ogun ni anfani lati ma kopa ninu etutu ti wọn maa n se fun awọn lọbalọba, ti wọn ba fẹ fi wọn jẹ oye.

Bakan naa ofin naa fi aye gba awọn lọbalọba lati sọ bi wọn se fẹ ki wọn sin wọn lẹyin ti wọn ba waja

Ọrọ eyi lo mu wa lọ ba awọn ladelade awọn alọrọlẹnu lati mọ kulẹkulẹ ọrọ ọhun

Ki ni awọn Ọba nipinlẹ Ogun sọ lori ọrọ yii?

Ileeṣẹ BBC News Yoruba tẹ ọkọ leti lọ si ipinlẹ Ogun lati gbọ ọrọ ẹnu awọn lọbalọba, awọn onisẹẹse ati ile igbimọ asofin ipinlẹ Ogun to gbe ofin naa jade.

Ọba Olufemi Omolade, Olubara ti ilu Ibara ni orisirisi nnkan ni awọn onisẹẹse n se ti ko se sọ sita nipa sinsin oku wọnyi.

O ni igba ti Ọba ba waja, to wọn si bẹrẹ etutu lati sin Ọba ọhun ti wọn wa dana si labẹ, ti wọn n pe ni Ọba n yẹna, "Iru ina wo ni Ọba n ya?"

Oba Adeyemi Obalange, Olu ti ilu Ota ni awọn kan wa ti wọn gbagbọ pe ti Ọba ba waja, wọn ni lati ge apa Ọba, wọn maa ge ori rẹ ni ko tọna sofin rara.

O ni aye ti laju ati pe ko yẹ ki iru nnkan bayẹn ma waye nitori ko bojumu ati pe ko si oosaa kankan nibi kankan to ni oun fẹ gba ori, ọwọ, ko bojumu rara.

Oba Saka Adelola ni ki wọn to se ofin naa , ijọba pe apero to pọ lori ọrọ na, ti wọn si ba awọn eeyan sọrọ, paapa awọn ti ọrọ naa,

Oba Adelola ni oun gẹgẹ bi ẹnikan faramọ igbesẹ ijọba ipinlẹ Ogun nitori o bojumu pupọ.

Bakan naa, Oba Olufemi Omolade, ni ti ijọba ba sọ wipe ẹsin ti awọn ọba n se yii, ohun naa ni ki wọn fi sin awọn ọba o bojumu pupọ.

O ni pupọ awọn Ọba ni wọn ti lodi si bi wọn se jẹ Ọba tẹlẹ tẹlẹ.

Apa ibo ni awọn onisẹẹse kọju si?

Olori awọn Onisẹẹse, to tun jẹ Oluawo Ake nipinlẹ Ogun, Samuel Tanimowo ni isẹse ti wa ki awọn oyinbo to gbe oṣelu ati ẹsin wa ati pe paapa isẹse se pataki pupọ

Tanimowo ni awọn Baba nla wọn ni igbagbọ nini isẹse, ti wọn si kalẹ fun awọn ọmọ lati tẹle

"A o ni lodi si ijọba, nitori ijọba soro fi ọwọ pa ida rẹ loju,

"Bi awọn olori wa ba ti gba pe ki awọn se iyapada yii, o ku sọwọ wọn, nnkan ti emi ri nibẹ niyẹn sugbọn sibẹsibẹ isẹse gbọdọ si wa."

Ki se gbogbo awọn to wa sibi apero lo gba ofin naa- Adari ile asofin ipinlẹ Ogun

Olakunle Oluomo, adari ile asofin ipinlẹ Ogun ni lootọ ni pe kii se gbogbo ẹni to wa lo gba sugbọn ọpọ lo gba pe igbesẹ naa dara.

"Ohun ti ofin n sọ, ti Ọba ba waja, to ba tiẹ ba tiẹ ni etutu ksn ti ẹ fẹ se, ofin fi idi ẹ mulẹ pe awọn ti wọn n se, awọn ti o tọ lati se etutu yẹn, ki n se ki awọn kọọkan lati ibi kan o

"Awọn Ologboni, oloṣugbo, ati awọn mii awọn naa nani wọn gbọdọ se sugbọn phun ti n sọ ni pe, ki wọn se ọna to ba igbalode mu."