Mọ̀ nípa ààrun tó le mú kí o máa ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ tí o bá n rìn láì mu ọtí yó

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹsẹ̀ mi ní ẹ̀mí arà tirẹ̀, tí mo bá fẹ́ lọ sí ibìkan, òhun á máa lọ si ibi tó wù ú.
Arábìnrin kan, Tallulah Clark tó jẹ́ akọ̀ròyìn sọ ìrírí rẹ̀ lórí àwọn nǹkan tó ń kojú lórí àìsàn ataxia tó ń ba jà.
Mo rò wí pé ara mi kò balẹ̀ ni àfi ìgbà tí mo ṣe àkíyèsí pé ọwọ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ̀n
Clark ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni òun máa ń ní ìpènijà láti lè sọ ọ̀rọ̀ tàbí láti kọ ohunkóhun kalẹ̀.
Ó ní òun kìí lè rìn bí ó ṣe yẹ nígbà mìíràn nítorí òun máa ń rìn bí ẹni tí ọtí ń pa ni, bí ìgbà tí ènìyàn bá ká ẹsẹ̀ kan sókè tó fẹ́ máa fi ìkejì rìn lásán.
Ó ṣàlàyé pé òun máa ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ bí ẹni tó ti mu ọtí yó ni tí òun bá ń rìn, tó sì jẹ́ wí pé igi tàbí kẹ̀kẹ́ arọ ni òun máa ń lò nígbà mìíràn láti fi rìn.
Nígbà tó ń ṣàlàyé bí àisàn náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lára, ó ní láti ìgbà tí òun ti wà ní kékeré ni òun ṣe àkíyèsí pé òun kìí rí kẹ̀kẹ́ gùn, tí òun kìí rí àwọn eré tí ọmọdé máa ń ṣe ṣe.
Clark sọ pé nígbà tí òun ń dàgbà, òun ṣe àkíyèsí pé ìrìn òun kò dán mọ́rán tò sí yàtọ̀ sí ti àwọn enìyàn yòókù.
“Ìrìn náà burú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí àwọn ènìyàn máa ń bèèrè lọ́wọ́ mi pé ṣe mo mu ọtí yó ni.”
“Mo ti ẹ̀ rò wí pé ara mi kò balẹ̀ ni àfi ìgbà tí mo ṣe àkíyèsí pé ọwọ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ̀n.”
Lẹ́yìn ọdún mẹ́jọ ni wọ́n tó mọ nǹkan tó ń ṣe mi
Clark ní, ó gba àwọn onímọ̀ ní ọdún mẹ́jọ kí wọ́n tó le fi ìdí àìsàn tó ń bá òun jà múlẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn Ataxia burú díẹ̀, kìí ṣe wí pé gbogbo nǹkan burú fún òun láti ṣe.
“Mò ń gbé ìgbé ayé mi, mo fẹ́ràn láti máa dáná àti láti máa rìnrìn àjò.”
“Mo ma ń jáde pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣùgbọ́n ó máa ń gbà mí ní akitiyan tó pọ̀ díẹ̀.”
Ó fi kun pé gbígbé pẹ̀lú àìsàn tí kò wọ́pọ̀ báyìí jẹ́ ohun tó nira díẹ̀ àmọ́ Ataxia kìí ṣe ààrùn tó burú púpọ̀ jù.
“Àìsàn yìí ti ṣí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilẹ̀kùn tí mi ò mọ̀ pé ó le ṣe é ṣí fún mi.”
Kí ni Ataxia?
Ataxia jẹ́ ààrùn tó máa ń ṣe àkóbá fún àwọn ẹran ara.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde àjọ ètò ìlera ní UK, NHS, ṣe sọ, ààrùn yìí kìí jẹ́ kí ènìyàn le ṣe àmúlò ẹran ara rẹ̀ tó bá ṣe wù ú, tó sì máa ń ṣe àkóbá fún ọ̀rọ̀ sísọ.
Wọ́n ní kò sí ẹ̀yà ara tí ààrùn yìí kò lè ṣe àkóbá fún, àmọ́ èyí tó wọ́pọ̀ ni kí ènìyàn má lè rìn dáadáa, sọ̀rọ̀, jẹun, kọ̀wéè tàbí ríran.
NHS ní irú ataxia tí ènìyàn bá ní, ni yóò sọ bí àwọn ipa tí ààrùn yìí máa ṣe fún àwọn ẹ̀yà ara yìí ṣe ma burú tó.
Irú àwọn ataxia tó wà
Mẹ́ta ni ataxia tó gbajúmọ̀ jùlọ tó wà.
Àjọ Medicalnewstoday ní àwọn ataxia mẹ́ta tó gbajúmọ̀ jùlọ ni Cerebellar ataxia èyí tó máa ń wáyé nígbà tí “cerebellum” ẹ̀yà ọpọlọ kan kò bá ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.
Èkejì ni èyí tó bá jẹ́ àjogúnbá; ènìyàn lè jogún ààrùn yìí lára àwọn òbí ènìyàn tó bá jẹ́ wí pé òbí ènìyàn ti ni rí.
Irú ataxia kẹta tó gbajúmọ̀ ni èyí àìsàn kan tàbí òmíràn bíi “stroke” le fà sí ènìyàn lára.
Kí ló máa ń fa ataxia?
Gẹ́gẹ́ bí NHS, UK ṣe sọ, tí nǹkankan bá ń ṣe ọpọlọ ènìyàn máa ń fa kí ènìyàn ní ataxia.
Ọtí mímu àmujù náà máa ń fa ataxia.
Tí ènìyàn bá fi orí ṣeṣe tàbí kí èémí má lọ sí ọpọlọ bó ṣe yẹ le fa ataxia.
Lílo oògùn oorun ní àlòjù àti àwọn oògùn mìírà tó lágbára náà lè jẹ́ okùnfà ataxia.
Ìwádìí tún ní kí ènìyàn máa ṣe wàhálà púpọ̀ le fa ààrùn yìí.
Kí ni àwọn àmì àpẹẹrẹ ataxia?
- Kí ènìyàn má lè rìn dáadáa bó ti yẹ.
- Ẹni tó bá ní ààrùn yìí máa ń ní ìṣòro láti gbé oúnjẹ tàbí àwọn nǹkan mìíràn mì bó ṣe yẹ.
- Kí ojú máa yí bó ṣe wù ú láìsí ìdádúró.
- Kí ohùn ènìyàn máa gbọ̀n tàbí kí ohùn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní yàtọ̀ sí bó ṣe wà.
- Kí ènìyàn má lè jẹun, kọ iṣẹ́, de bọ̀tìnì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìtọ́jú ataxia
Kò ì tíì sí ìtọ́jú kan tó fìdí múlẹ̀ fún ataxia ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ kan ni àwọn onímọ̀ máa ń gbé láti fi ṣe ìtọ́jú àìsàn náà.
Lára àwọn ìgbésẹ̀ yìí ni ṣíṣe àmójútó bí ẹni tó bá ní ààrùn yìí yóò ṣe máa sọ̀rọ̀ nítorí ìnira tí wọ́n máa ń kojú láti lè sọ̀rọ̀.
Wọ́n máa ń fún àwọn tó bá ní ààrùn yìí ní oògùn tí yóò máa ṣe àmójútó ojú àti ọkàn wọn.
Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn àmì tí ààrùn yìí maá n fihàn ni àwọn dókítà máa ń mójútó jùlọ kí ó má ba à peléke si ju bí ó ti yẹ lọ.















