Àwọn nǹkan mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Subomi Balogun tó dolóògbé nìyí

Subomi Balogun

Oríṣun àwòrán, Others

Ní ọ̀sán ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Karùn-ún ọdún 2023 ni ìròyìn gbòde pé olóyè Subomi Balogun tó jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ First City Monument Bank (FCMB) jáde láyé.

Ìròyìn sọ pé ní ìlú London, United Kingdom ni bàbá náà dákẹ́ sí lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́.

Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọmọ ilẹ̀ Ijebu tó dolóògbé náà rèé.

  • Ní ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹta ọdún 1943 ni wọ́n bí olóògbé Subomi Balogun sáyé tó sì pé ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọ́rùn-ún kó tó dágbẹre fáyé.
  • Ọmọ ìdílé Oba Tunwase ti Ijebu-Ode ni Subomi Balogun.
  • Òun ni Otunba Tunwase gbogbo Ijebu, tó sì tún jẹ́ Olori gbogbo ọmọọba Ijebu àti Asiwaju àwọn onígbàgbọ́ ni Ijebu.
  • Ìdílẹ̀ mùsùlùmí ni wọ́n bi sí kó tó yípadà sí onígbàgbọ́ nígbà tó wà ní ilé ẹkọ girama.
  • Ilé ẹ̀kọ́ Igbobi College ló ti kẹ́kọ̀ọ́ girama, kó tó tẹ̀síwájú lọ sí London School of Economics níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin.
  • Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ kó tó lọ sí ìlú òyìnbó láti lọ kàwé, tó sì tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìdájọ́ nígbà tó padà sí Nàìjíríà lẹ́yìn ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀.
  • Ní ọdún 1979 ni ó gba ìwé àṣẹ láti dá ilé ìfowópamọ́ First City Merchant Bank sílẹ̀ tí báǹkì náà sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1983.
  • Subomi Balogun dá ilé ìwòsàn fún àwọn ọmọdé kalẹ̀ ní Ijebu Ode èyí tó fún ile ìwòsàn ńlá UCH tí Ibadan.
  • Aṣọ funfun ni ó sábà máa ń wọ̀ ní gbogbo ìgbà.
  • Ọ̀pọ̀ ọmọ àti ọmọọmọ ló gbẹ̀yìn Subomi Balogun.

Erin wó! Olùdásílẹ̀ báńkì FCMB Subomi Balogun jáde láyé

Subomi Balogun

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iroyin to n tẹ wa lọwọlọwọ ni pe oludasilẹ ati oludari ile ifowopamọ First City Monument Bank (FCMB), Subomi Balogun ti dagbere faye loni ọjọ Kọkandinlogun Oṣu Karun.

Awọn iroyin kan sọ pe ni ilu London, United Kingdom ni o ti dakẹ.

Nigba ti ikọ iroyin BBC Yoruba kan si ile rẹ to wa ni agbegbe Milverton Road, Ikoyi nipinlẹ Eko, awọn to wa ninu gba ile naa sọ pe “nnkan bii oṣu kan sẹhin ni Baba ko ti sin nile ti wọn rinrinajo”.

Ẹwẹ, eekan ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party to tun jẹ oniroyin ori ayelujara, Dele Momodu sọ fun BBC yoruba lorii foonu pe lootọ ni oloogbe naa ti dagbere faye.

Subomi Balogun ni Olori awọn ọmọ Ọba ilu Ijebu Ode.

Ni ọjọ kẹsan, oṣu kẹta ni ogbontagi oniṣowo naa ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ikọkandinlaadọrun to pe loke eepẹ.