Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ arákùnrin tí ọlọ́pàá la igi mọ́ lórí, gba ọ̀kadà rẹ̀ l’Eko, wọ́n ní ìjìyà tó tọ́ ti bẹ̀rẹ̀ fún wọn

Aworan fidio to gba ori ayelujara naa pẹlu aworan ọga ọlọpaa Eko to lọ bẹ arakunrin naa wo.

Oríṣun àwòrán, other/lagospolice

Ọga ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, CP Idowu Owohunwa ti ṣe abẹwo si ọdọkunrin kan ti awọn ọlọpaa hu iwa aṣemaṣe si atawọn ọmọ ẹya Hausa lagbegbe Ọja Abbattoir to wa ni Agege nilu Eko lati rawọ ẹbẹ si wọn lori ihuwasi awọn ọlọpaa naa.

Ṣe awọn agba ni ọjọ ti ọmọde ba pa arọgidigba, awọn obi rẹ nii gbe e tọ lọ, Ọga ọlọpaa ni ipinlẹ Eko naa rọ arakunrin ọhun atawọn ẹya Hausa lagbegbe naa lati dakundabọ fiye denu lori iṣẹlẹ naa.

Bawo ni ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ?

Ọga ọlọpaa Eko atawọn ikọ rẹ bẹ arakunrin tawọn ọlọpaa ṣe aṣemaṣe si ni Agege

Oríṣun àwòrán, lagospolice

Ni Ọjọ Ẹti ọjọ kejila oṣu karun un ni fidio kan gbode lori ayelujara to ṣafihan bi awọn ọlọpaa mẹta kan ṣe dawọ lilu jọ fun nitori wọn fẹ gba ọkada to fi n ṣiṣẹ lọwọ rẹ.

Fun igba diẹ bayii, ijọba ipinlẹ Eko ti gbẹsẹ le gigun alupupu ọkada ati Maruwa lawọn agbegbe kan ni ipinlẹ naa eyi ti awọn agbofinro si maa n gbiyanju fidi ofin naa mulẹ.

Oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni ijọba ikede kede pe ko gbọdọ si igbokegbodo ọkada lawọn ijọba ibilẹ mẹwaa ati ijọba agbegbe LCDA marundinlogun.

Ninu fidio naa, ọkan lara awọn ọlọpaa ọhun gun ọkada arakunrin naa nigba ti awọn mejeeji yoku si n gbiyanju ati di arakunrin to ni ọkada naa lọwọ ko maa baa lọ ọkada rẹ mọ ọlọpaa to wa lori rẹ. Ọkan lara awọn ọlọpaa meji yii lo gbe kumọ kan dani to la mọ ọdọkunrin naa eyi fi di pe o ṣeṣe ti ẹjẹ si n da niwaju ori rẹ. Lẹyin eyi lawọn mejeeji ko si inu kẹkẹ maruwa kan ti wọn si lọ. Arakunrin naa gbiyanju ati le wọn sugbọn ẹpa o boro mọ.

Ọga ọlọpaa Eko ṣe abẹwo si ọmọ ọkunrin naa

Lẹyin ti fidio naa gbode ti ọpọ ọmọ Naijiria si bu ẹnu atẹ lu ihuwasi awọn ọlọpaa naa ni alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria fesi sii ohun ti araalu n sọ lori ayelujara, to si ni ọga agba yanyan nileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti da si ọrọ naa lẹyin ti fidio naa de arọwọto rẹ o si ti paṣẹ ki wọn mu awọn ọlọpaa mẹtẹta ti ọrọ naa kan si aham fun iwadi ati ijiya to tọ.

Ni Ọjọbọ ni ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko ko ikọ rẹ lẹyin lati lọ bẹ arakunrin naa wo, to si tun ṣepade pẹlawọn ọmọ ẹya Hausa to wa lagbegbe Agege lori igbesẹ ti wọn ti gbe lori ọrọ naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko SP Benjamin Hundeyin fi si oju opo Twitter, O ni Kọmiṣọna ọlọpaa, Idowu Owohunwa fi da wọn loju pe igbesẹ lati fi ijiya to tọ jẹ awọn ọlọpaa naa ti bẹrẹ, gbogbo bi nnkan ba ṣe lọ ni yoo si fihan araalu ni gbangba.

O fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni tẹti lati rii daju pe wọn n bọwọ fun ofin lẹnu iṣẹ wọn.