Handicapped couple: Ọmọ tó fẹ́ jábọ́ nínú mọ́tò Eko ni mo ràn lọ́wọ́ tí mo fi gé lápá - Kehinde àti Ramota Ogunsanya
"Bayii kọ ni wọn ṣe bi mi". Arabinrin Ramota to jẹ iyawo Kehinde Ogunsanya kẹnu bọ ọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba lori ipenija oun ati ọmọ rẹ ti wọn jọ jẹ onipenija ara.
O ṣalaye bi oun ati ọkọ rẹ ti wọn jọ jẹ oni ipenija ara yii ṣe pade ti wọn si nifẹ ara wọn.

"Awọn mii ma wa ba mi pe ṣe a jọ wa ninu ọkọ kan naa ni ti a si jọ ni ijamba ọkọ?
"Ẹlomii a maa bere pe ṣe bi wọn ṣe bi wa niyẹn ni abi a jọ ṣeleri fun ara wa pe a fẹ fẹ ara wa?"
''Ìrìn wákàtí mẹ́fà la rìn nínú igbó kí ilẹ̀ tó sú bá wa, tí wọ́n sì di ọwọ́, dí ẹ̀sẹ̀ mí mọ́lẹ̀..''
Bayii kọ ni wọn ṣe bi mi - Ramota

Arabinrin Ramota ati ọkọ rẹ Kehinde gba alejo BBC Yoruba ni ile wọn ni agbegbe Ikorodu ni ipinlẹ Eko nibi ti wọn ti ṣalaye iha ti awọn eeyan kọ si bi ọkọ ṣe ge lọwọ ti iyawo naa ge lẹsẹ.
O ni o maa n ya ọpọlọpọ eeyuan lẹnu ti wọn ba ti ri oun ati ọkọ oun.
"Mo ba iya mi kiri ọja lọ ni, mi o si mọ pe ọkọ kan ti jade latẹyin... bo ṣe gba mi latyin niyẹn, iṣan ẹsẹ mi lo kọkọ jade".
Nigba ti wọn gbe Ramota lọ ile iwosan ti awọn dokita ni nnkan ti bajẹ kọja ki wọn da ẹsẹ rẹ si ayuafi ki wọn ge e, o jẹ ohun ibanujẹ.
"Mama mi keee, wọn ko fẹ gba ki wọn ge ẹsẹ mi, wọn fẹ pa ara wọn amọ nigba ti akoko ti n lọ, wọn pada gba."

Ọmọ tó fẹ́ jábọ́ nínú mọ́tò Eko ni mo ràn lọ́wọ́ tí mo fi gé lápá - Kehinde
Iṣẹ apero sọkọ ni Ọgbẹni Kehinde n ṣe to si ni awn n rinrinajo bọ lati Eko ni ti taya ọkọ naa si fo yọ.
"Ṣugbọn tori ọmọ to fẹ jabọ ti mo fẹ du ko pada wọnu ọkọ ni mo fi jabọ ti ọwọ mi fi ge."
Kehinde ati Ramota ṣe igbeyawo ni ọdun 2012, Ọlọrun si ti fi ọmọ mẹta ta wọn lọrẹ.

