Kò sí ikú tó duni tó ikú ọmọ - May Yul Edochie

Oríṣun àwòrán, MAY YUL-EDOCHIE
Iyawo gbajugbaja osere Nollywood, Yul Edochie ni o ti sọrọ sita fun igba akọkọ lẹyin to padanu ọmọ rẹ ọkunrin.
Nibi oṣu mẹta sẹyin ni May Edochie padanu ọmọ rẹ ọkunrin, Kambilinachukwu.
Ọmọ ọdun mẹrindinlogun ọhun lo sadede subu nibi to ti n gba bọọlu ni ile ẹkọ rẹ.
Lati igba ti Kambili ti jade laye ni May ko ti sọrọ lori isẹlẹ naa sugbọn bayi o ti fọhun sita lori opo ayelujara rẹ Instagram lọjọ Satide.
O ni ohun ko ro pe iku kan duni to iku ọmọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
O dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan to duro ti lasiko isẹlẹ paapa awọn mọlẹbi ati ọrẹ rẹ.
O ni; "Sisọ ọrọ ko to lati fi dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan to duro ti wa,
"Ti eeyan ba padanu ọkọ, wọn maaa pe eeyan ni opo.
"N ko ti ri orukọ ti wọn pe ẹni to ba padanu ọmọ rẹ. N ko ro pe iku kan wa to duni to iku ọmọ
"Ohun to ja ni laya ni bakan naa mo tun dupẹ lọwọ Ọlọrun.
"O nira fun mi lati gbagbe ọmọ mi ati pe ọmọ mi keji ninu awọn ọmọ mẹrin mi, ti n ko si le gbagbe rẹ.
Ki lo sẹlẹ saaju?
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lo fidi isẹlẹ naa mulẹ pe ọmọ oṣere titata, Yul Edochie jade laye.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, SP Benjamin Hundeyin, lo sạlaye fun BBC pe aarọ Ọjọbọ, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹta, ̣ọdun 2023 yii ni ọmọdekunrin naa, Kambilichukwu Yul-Edochie fi aye silẹ..
O fi kun pe ile ẹkọ ni ọmọ naa ku si, iwadii si ti bẹrẹ lori ohun to sọkunfa iku rẹ
Ta ni Yul Edochie?

Oríṣun àwòrán, YUL EDOCHIE
Oṣere tiata ni Yul Chibuike Daniel Edochie, o tun maa n dari ere, bẹẹ lo tun maa n kọ itan.
Ọjọ keje, oṣu Kini, ọdun 1982 ni wọn bi nipinlẹ Anambra, oun si ni ọmọ agba ọjẹ oṣere tiata, Pete Edochie.
Ọpọ ọdun sẹyin lo darapọ mọ iṣẹ tiata, o si ti kopa ninu ọpọlọpọ ere, lara wọn ni Idemili, Devil in Red, ati Show Down.
Yatọ si iṣẹ tiata, o tun jẹ oloṣelu.
Ẹni ọdun mejilelogun lo wa nigba to fẹ iyawo rẹ akọkọ, amọ lọdun to kọja, iroyin gbode pe o fun obinrin mii loyun, ti iyẹn si bi ọmọkunrin kan fun un.















