Mo ti ṣẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin, àfi kí wọ́n dárí jìn mí - Suebebe, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà bẹ̀bẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Gbajugbaja agba osere tiata Yoruba, Sule Suebebe, ti ọpọ mọ si Suebebe ti n tọrọ aforijin lọwọ gbogbo awọn obinrin to ti sẹ lagbo ere sinima tabi ni ibo miiran.
O tọrọ aforijin yii ninu fọnran kan to gbe sori ayelujara Facebook.
Suebebe, ẹni to jẹ gbajumọ lagbo ere sinima agbelewo nigbakanri lo nni ipenija ilera, ti ko si ni anfani lati le rin mọ bayii.
O ni o se koko ki oun tọrọ aforijin lọwọ gbogbo obinruin ti oun ti fẹ ri.
"Gbogbo ẹni ti mo ba sẹ, yala ẹni ti mo mọ tabi ti n ko mọ, ẹ jọwọ, ẹ darijin mi.
"Ori idọbalẹ lo yẹ ki ti ma sọ eleyii sugbọn ko si aye fun mi lati dọbalẹ.
"Ẹ jọwọ, paapa awọn obinrin ti mo ti sẹ, nitori mo mọ pe mo ti tẹ ọpọlọpọ ẹmi mọ lẹ."
Osere Tiata naa to jẹ ọmọ bibi ilu Ekiti tẹsiwaju pe oun ti gbe igbe aye ti ko dara sẹyin sugbọn oun nilo aforijin gbogbo awọn ti oun ti sẹ bayii.
"Nigba ti mo jẹ olorin, ti mo kere, mo gbadun aye, n kii wọ asọ kan lẹẹmeji nitori mo ni wọn to pọ jaburata.
"Mo kan n gbe igbe aye to wu mi ni. Mo kopa ninu nkankan ti ọwọ si n wọlẹ fun mi.
"N ko ni ẹni to le gba mi ni imọran nipa igbesi aye ti mo n gbe. Ko si mọlẹbi to le tọ mi sọna.
"Mo ri ara mi gẹgẹ bi pe ko si ẹni to ju mi lọ."
Lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹfa ni fọnran kan bọ sori ayelujara ni bi agba osere naa ti n tọrọ iranlọwọ lọwọ gbogbo ọmọ Naijira lori ilera rẹ to ni kudiẹkudiẹ












