Wo bí àjọ òkèèrè yí ṣe gbọ̀nà ẹ̀bùrú jí àwọn ọmọdé gbé ní ìlú yìí

Aworan
Àkọlé fídíò, Ghana

Awọn ọmọde lorilẹede Ghana ni wọn ti mu kuro ni ilẹ wọn nipasẹ ọkan lara awọn ileeṣẹ owoyebiye kan lagbaye to n gbogun ti oko ẹru, gẹgẹ bi iwadi BBC se fihan.

Ileeṣẹ Internation Justice Mission lo ni erongba lati dola awọn ọmọde lọwọ oko ẹru, ti wọn yoo da wọn pada sọdọ mọlẹbi wọn,

Sugbọn ọpọlọpọ awuyewuye lo ti jẹyọ

BBC rin irinajo lo si ilu Mogyigna ni apa ariwa orilẹede Ghana.

Apapọ awọn eeyan to wa niluu naa ko ju mẹrinlelogun lọnigba ti a de ibẹ .

Ọkan lara ọmọde ti isẹlẹ naa soju rẹ, Musah Mustafa salaye fun BBC pe ni ọganjọ oru lọjọ kẹfa oṣu kẹjọ ọdun 2022 ni oun jade lati inu ile lati lọ tọ, to oun si ri bi ọkọ ayọkẹlẹ mẹrin se ya wọ abule ọun.

Musah ni oun sapọ ti oun si ri awọn agbebọn to jade lati inu ọkọ naa, ti wọn si wọ si sumọ ile meji kan.

O ni oun gbiyanju lati pariwo sita, pe ki oun ji awọn yooku.

Sugbọn ko si nnkan ti ẹnikẹni le se si.

Awọn agbebọn naa ya wọle, wọn si gbe ọmọ mẹrin lọ.

Abọ BBC ree ninu fọnran yii.