Tìlù tìfọn la ma fi kí Sunday Igboho padà sí Nàìjíríà láìpẹ́- Agbẹjọ́rò

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Pelumi Olajengbesi, agbẹjọro fun Oloye Sunday Adeyemọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho ti fi idi rẹ mulẹ pe gbajugbaja ajafẹtọ iran Yoruba naa ko ni pẹ pada si orilẹede Naijiria.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, Sunday Igboho lo di ero ahamọ lorilẹede Benin lọdun 2021 lẹyin ti ajọ DSS se ikọlu si ile rẹ lori ẹsun pe o n pe fun Idasilẹ orilẹede Ilẹ Yoruba.

Olajengbesi ninu ifọrọwerọ to se pẹlu Ileeṣẹ BBC News Yoruba ni gbogbo eto lo ti bẹrẹ lati se ayẹyẹ ipadabọsile Sunday Igboho laipẹ

"A ni igbagbọ pe Sunday Igboho yoo pada si orilẹede, ti a si fi ilu ati ijo ki kaabọ.

"Igboho jẹ eeyan to ni inu re, to lewaju pe ki adajọ ododo wa ni agbegbe wa

"Ti a ba dẹ wo bi nnkan se n lọ labẹ isejọba tuntun yii, gbogbo akitiyan ni wọn sa lati se atunse si isoro Naijiria ti isọkan yoo si wa, ti gbogbo ọmọ orilẹede yii yoo si anfani si idajọ ododo.

"Sunday Igboho ko dẹsẹ ri tẹlẹ ati pe ki se ọdaran rara lorilẹede Naijiria .

"Ohun ti Igboho n pe fun tẹlẹ lo da le bi ijinigbe ati ipaniyan to wọpọ ni ilẹ Yoruba yoo se wa sopin, ti ba dẹ wo bi nnkan se ri bayi, atunse ti wa, ti a si ni igbagbọ pe alaafia yoo tu bọ tẹsiwaju ni agbegbe wa.

"Igboho ko yi ipinnu rẹ pada lori Yoruba Nation"

Pelumi Olanjengbesi tẹsiwaju pe ko ni nnkan to jọ mọ pe Sunday Igboho fẹ yi ipinni rẹ pada lori idasilẹ ilẹ Yoruba

O ni nnkan ti Sunday Igboho n se bayi ni pe o n tẹlẹ ofin ninu irinajo ipe rẹ fun idasilẹ Yoruba Nation.

"Ajafẹtọ ọmọ Yoruba ni Sunday Igboho, o fẹran ibi to ti sẹ wa.

"Ko gbe ipe rẹ lori idasilẹ Yoruba silẹ, o ni igbagbọ pupọ ninu Yoruba Nation.

"O n pada bọ si orilẹede Naijiria lati darapọ mọ awọn mọlẹbi rẹ ati lati tẹsiwaju ninu ipe rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn sọrọ ni agbegbe wa."