‘Ara Gómìnà Akeredolu ti yá báyìí, ṣùgbọ́n…’

Gomina Akeredolu

Oríṣun àwòrán, twitter/Arakunrin Akeredolu

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu tun ti sun ọjọ ati wọle pada si ẹnu isẹ rẹ siwaju.

Ninu lẹta to kọ ranṣẹ si ile asofin ipinlẹ naa, gomina Akeredolu ni oun ko ni le wọle pada si ẹnu iṣẹ lọjọ kẹfa osu keje gẹgẹ bi oun se lero mọ.

O ni amọran ti dokita oun gba oun pe ki oun wa aye sinmi diẹ sii lẹyin ilera oun lo fa isunsiwaju ati pada si ẹnu iṣẹ oun.

Nigba to n ka lẹta naa si eti gbogbo awọn aṣofin ile, olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo, Họnọrebu Ọlamide Oladiji ṣalaye pe igbesẹ naa ba abala aadọwa iwe ofin Naijiria mu.

Bakan naa lo tun ṣalaye pe igbakeji gomina, Lucky Aiyedatiwa ni yoo tẹsiwaju gẹgẹ bi adele gomina titi di igba ti Akeredolu yoo pada si ẹnu iṣẹ.

Ilera Akeredolu ati oṣelu Ondo ṣaaju asiko yii

Gomina Akeredolu gunle isinmi itọju ara ẹni ni ọjọ karun oṣu kẹfa lati fi tọju ara rẹ lẹyin ti iroyin tan kalẹ nipa kudiẹkudiẹ ilera rẹ lati oṣu diẹ sẹyin.

Saaju isinmi rẹ lawọn iroyin ti n kaakiri pe ailera rẹ naa pọ to bẹẹ ti wọn ko fi ro pe o le ye e mọ.

Ko pẹ ẹ rẹ lawọn kan tun gbe iroyin ẹlẹjẹ dide pe amofin agba naa ti jade laye ki awọn amugbalẹgbẹ rẹ to pariwo sita pe ko si iku loju rẹ ati pe alaafia lo wa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Bi eyi ṣe n lọ lapakan ni iroyin miran n kaakiri pe gbungbungbun n waye laarin igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa at’awọn amugbalẹgbẹ Akeredolu kan lori ọrọ oe igbajeji gomina naa fẹ yẹ aga mọ ọga rẹ nidi.

Amọṣa ko pẹ pupọ ti awọn amugbalẹgbẹ gomina naa atawon alẹnulọrọ lẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ naa to pa ina rẹ mọlẹ gẹgẹ bi gbọyisọyi ile ẹmu lasan